Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
“OLUKULUKU ẹni tí ó bá kepe orukọ Jehofah ni a o gbala.” (Rome 10:13, NW) Pẹlu awọn ọrọ wọnyi apostle Paul tẹnumọ bi ó ti ṣe pataki tó fun wa lati mọ orukọ Ọlọrun. Gbolohun rẹ̀ mú wa pada si ibeere wa akọkọ: Eeṣe tí Jesu fi ‘ìbọ̀wọ̀-fún,’ tabi ‘ìsọdimímọ́,’ orukọ Ọlọrun si ibẹrẹ Adura Awokọṣe rẹ̀, ṣaaju ọpọ awọn ọran pataki miiran? Lati loye eyi, a nilati loye daradara diẹ si i nipa itumọ awọn ọrọ pataki meji naa.
Akọkọ, kinni ọrọ naa ‘bọ̀wọ̀-fún’ tabi ‘sọdimímọ́,’ tumọsi niti gidi? Lọna itumọ-olówuuru ó tumọsi: “Sọ di mímọ́.” Ṣugbọn orukọ Ọlọrun kò ha ti wà ní mímọ́ tẹlẹtẹlẹ bi? Dajudaju ó ti wà bẹẹ. Nigba tí a bá sọ orukọ Ọlọrun di mímọ́, a kò sọ ọ di mímọ́ ju bi ó ti wà rí lọ. Dipo eyi a mọ̀ ọ́n ní àmọ̀dunjú gẹgẹ bi eyi tí ó mọ́, a yà á sọtọ, gbé e ga ju ohun gbogbo lọ. Nigba tí a bá gbadura pe ki a sọ orukọ Ọlọrun di mímọ́, a nfojusọna si igba tí gbogbo ẹda yoo bọwọ fun un gẹgẹ bi eyi tí ó mọ́.
Ekeji, niti gidi kinni ohun tí ọrọ naa “orukọ” tumọsi? A ti rí i pe Ọlọrun ní orukọ kan, Jehofah, ati pe orukọ rẹ̀ farahan ní ẹgbẹẹgbẹrun igba ninu Bibeli. A ti jiroro, pẹlu, nipa ijẹpataki dídá orukọ yẹn pada sibi tí ó lẹtọ si ninu ọrọ-aarin-iwe Bibeli. Bi orukọ naa kò bá si nibẹ, bawo ni ọrọ onipsalm naa yoo ti ní imuṣẹ pe: “Awọn tí ó si mọ orukọ rẹ yoo gbẹkẹle ọ: nitori iwọ, [Jehofah], kò kọ awọn tí nṣafẹri rẹ silẹ.”—Psalm 9:10.
Ṣugbọn njẹ ‘mimọ orukọ Ọlọrun’ wulẹ ní ninu kiki ọgbọn-ori nikan pe orukọ Ọlọrun lede Hebrew ni YHWH, tabi ní Yoruba, Jehofah? Rara o, ó tumọsi ohun tí ó ju eyiini lọ. Nigba tí Moses wà ní Oke Sinai, “[Jehofah] si sọkalẹ ninu ikuukuu awọsanma, ó si bá a [Moses] duro nibẹ, ó si pe orukọ [Jehofah].” Kinni ohun tí kikede orukọ Jehofah yii ní ninu? Apejuwe awọn animọ rẹ̀: “[Jehofah, Jehofah], Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni tí ó pọ̀ ní iṣeun-ifẹ ati otitọ.” (Exodus 34:5, 6) Lẹẹkan si i, ṣaaju iku rẹ̀, Moses sọ fun awọn ọmọ Israel pe: “Emi yoo pokiki orukọ [Jehofah].” Kinni ohun tí ó tẹle e? Imẹnuba diẹ lara awọn iwa-ẹ̀yẹ nlánlà Rẹ̀, ati lẹhin naa atunyẹwo ohun tí Ọlọrun ti ṣe fun Israel nitori orukọ Rẹ̀. (Deuteronomy 32:3-43) Fun idi yii, mimọ orukọ Ọlọrun tumọsi kíkọ́ ohun tí orukọ yẹn duro fun ati jijọsin Ọlọrun tí ó ní in.
Niwọn bi Jehofah ti so orukọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ awọn animọ rẹ̀, ete ati iṣẹ rẹ̀, a le rí idi tí Bibeli fi sọ pe orukọ Ọlọrun jẹ mímọ́. (Leviticus 22:32) Ó ní ọlánla, ó tobi, ó ní ẹ̀rù ó si ga ju ohun gbogbo lọ. (Psalm 8:1; 99:3; 148:13) Bẹẹ ni, orukọ Ọlọrun ju akọle lasan kan lọ. Ó duro fun un gẹgẹ bi eniyan kan. Kii ṣe orukọ lasan onigba-kukuru kan tí a lè lò fun akoko kan lẹhin naa tí a o si fi orukọ-òye kan iru bii “Oluwa” gba ipo rẹ̀. Jehofah funraarẹ̀ sọ fun Moses pe: “‘Jehofah . . .’ Eyi ni orukọ mi titi lọ gbére, eyi si ni iranti mi lati iran-eniyan kan dé iran-eniyan miiran.”—Exodus 3:15, NW.
Bi o tiwu ki ó sapa tó, eniyan kò le pa orukọ Ọlọrun rẹ́ lori ilẹ-aye lae. “Nitori lati ila-oorun titi ó si fi dé ìwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yoo tobi laarin awọn keferi; nibi gbogbo ni a o si fi turari jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mímọ́: nitori orukọ mi ó tobi laarin awọn keferi, ni [Jehofah] awọn ọmọ-ogun wi.”—Malachi 1:11; Exodus 9:16; Ezekiel 36:23.
Fun idi yii, sisọ orukọ Ọlọrun di mímọ́ ṣe pataki ju ohunkohun miiran lọ. Gbogbo awọn ete Ọlọrun ni a sopọ mọ́ orukọ rẹ̀. Awọn ọran-iṣoro araye bẹrẹ lati igba tí Satan kọkọ sọ orukọ Jehofah di àìmọ́ ní pípè É, ní itumọ kan naa, òpùrọ́ ati alaitootun lati ṣakoso iran ẹda-eniyan. (Genesis 3:1-6; John 8:44) Kiki nigba tí a bá dá orukọ Ọlọrun lare lọna yiyẹ ni araye yoo tó lè gbadun itura patapata kuro lọwọ awọn ipa onijamba tí irọ́ Satan ti ní. Idi niyii tí awọn Kristian fi ngbadura kárakára fun ìsọdimímọ́ orukọ Ọlọrun. Ṣugbọn awọn ohun kan wà tí wọn le ṣe, pẹlupẹlu, lati sọ ọ di mímọ́.
Bawo Ni A Ṣe Lè Sọ Orukọ Ọlọrun Di Mímọ́?
Ọna kan ni lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Jehofah ki a si tọkasi Ijọba rẹ̀ lati ọwọ́ Kristi Jesu gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun araye. (Ifihan 12:10) Ọpọ nṣe eyi, ní imuṣẹ ode-oni fun awọn ọrọ asọtẹlẹ Isaiah wọnyi: “Ní ọjọ naa ni ẹyin yoo si wipe, Yin [Jehofah], kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣe rẹ̀ laarin awọn eniyan, mú un wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ ni a gbé leke. Kọrin si [Jehofah]: nitori ó ti ṣe ohun didara: eyi si di mímọ̀ ní gbogbo ayé.”—Isaiah 12:4, 5.
Ọna miiran ni lati pa awọn ofin Ọlọrun ati aṣẹ rẹ̀ mọ́. Jehofah sọ fun orilẹ-ede Israel pe: “Nitori naa ni ki ẹyin ki ó maa pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹyin si maa ṣe wọn: Emi ni [Jehofah]. Bẹẹ ni ẹyin kò gbọdọ ba orukọ mímọ́ mi jẹ́ [sọ di àìmọ́]; bikoṣe ki a yà mi si mímọ́ laarin awọn ọmọ Israel: Emi ni [Jehofah] tí nyà yin si mímọ́.”—Leviticus 22:31, 32.
Bawo ni pipa tí awọn ọmọ Israel pa Ofin Jehofah mọ́ ṣe sọ orukọ rẹ̀ di mímọ́? A fun awọn ọmọ Israel ní Ofin naa lori ipilẹ orukọ rẹ̀. (Exodus 20:2-17) Fun idi yii, nigba tí wọn bá pa Ofin naa mọ́, wọn nfi ọlá ati igbega yiyẹ hàn fun orukọ naa. Siwaju si i, orukọ Jehofah wà lori awọn ọmọ Israel gẹgẹ bi orilẹ-ede kan. (Deuteronomy 28:10; 2 Chronicles 7:14) Nigba tí wọn bá huwa lọna yiyẹ, eyi mú ìyìn wá bá a, gẹgẹ bi ọmọ kan tí ó huwa lọna yiyẹ ti nmú ọlá wá fun baba rẹ̀.
Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, nigba tí awọn ọmọ Israel kuna lati pa Ofin Ọlọrun mọ́, wọn sọ orukọ rẹ̀ di àìmọ́. Nipa bayii, ẹṣẹ iru bii rirubọ si oriṣa, ibura eke, jijẹgaba lori awọn alaini ati didẹṣẹ agbere ni a ṣapejuwe ninu Bibeli gẹgẹ bi ‘bíba orukọ Ọlọrun jẹ́.’—Leviticus 18:21; 19:12; Jeremiah 34:16; Ezekiel 43:7.
Bakan naa, awọn Kristian ni a ti fun ní awọn aṣẹ ní orukọ Ọlọrun. (John 8:28) Awọn naa, pẹlu, ni a kà mọ́ ‘awọn eniyan fun orukọ Jehofah.’ (Iṣe 15:14) Fun idi yii, Kristian kan tí ó nfi pẹlu otitọ-inu gbadura pe, “Ki a bọwọ fun orukọ rẹ” yoo sọ orukọ yẹn di mímọ́ ninu igbesi-aye oun funraarẹ̀ nipa ṣiṣegbọran si gbogbo awọn aṣẹ Ọlọrun. (1 John 5:3) Eyi yoo ní ninu pẹlu ṣiṣegbọran si awọn aṣẹ tí a fi funni lati ọwọ Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu, ẹni tí ó maa nṣe Baba rẹ̀ logo nigba gbogbo.—John 13:31, 34; Matthew 24:14; 28:19, 20.
Ní alẹ ọjọ tí ó ṣaaju iṣekupa rẹ̀, Jesu pe ọ̀gangan-afiyesi sori ijẹpataki orukọ Ọlọrun fun awọn Kristian. Lẹhin sisọ fun Baba rẹ̀ pe: “Mo ti sọ orukọ rẹ di mímọ̀ fun wọn, emi yoo si sọ ọ di mímọ̀,” ó nbá a lọ lati ṣalaye pe, “ki ifẹ tí iwọ nifẹẹ mi lè wà ninu wọn, ati emi ní irẹpọ pẹlu wọn.” (John 17:26, NW) Kíkọ́ tí awọn ọmọ-ẹhin kọ́ orukọ Ọlọrun ní ninu, wíwá lọna ti ara-ẹni lati mọ ifẹ Ọlọrun. Jesu ti mú ki ó ṣeeṣe fun wọn lati di ojulumọ pẹlu Ọlọrun gẹgẹ bi Baba wọn onifẹẹ.—John 17:3.
Bi Ó Ti Ṣe Kàn Ọ
Nibi ipade awọn Kristian apostle ati awọn agba ọkunrin ní ọgọrun ọdun kìn-ín-ní ní Jerusalem, ọmọ-ẹhin naa James sọ pe: “Symeon ti rohin lọna pípé-pérépéré bi Ọlọrun ní igba ìkínní ti yí afiyesi rẹ̀ si awọn orilẹ-ede lati mú ninu wọn awọn eniyan kan fun orukọ rẹ̀.” A ha le kà ọ mọ́ awọn wọnni tí Ọlọrun mú jade lati jẹ́ “eniyan fun orukọ rẹ̀” bi iwọ bá kuna lati lò tabi jẹ́ orukọ yẹn bi?—Iṣe 15:14.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ nlọtikọ lati lo orukọ naa Jehofah, ati pe ọpọ awọn atumọ Bibeli ti yọ ọ́ kuro ninu itumọ wọn, araadọta ọkẹ awọn eniyan yika ayé ti fi tayọtayọ tẹwọgba anfaani jíjẹ́ orukọ Ọlọrun, tí lílò ó kii ṣe ninu ijọsin nikan ṣugbọn ninu ọrọ ojoojumọ, ati kikede rẹ̀ fun awọn ẹlomiran. Bi ẹnikan bá bá ọ sọrọ nipa Ọlọrun Bibeli tí ó si lo orukọ naa Jehofah, pẹlu ẹgbẹ isin wo ni iwọ yoo kà á mọ́? Ẹgbẹ kanṣoṣo péré ni ó wà ní ayé tí nlo orukọ Ọlọrun deedee ninu ijọsin wọn, gan-an gẹgẹ bi awọn olujọsin rẹ̀ nigba atijọ ti ṣe. Awọn wọnyi ni awọn Ẹlẹrii Jehofah.
Orukọ tí a gbeka ori Bibeli naa awọn Ẹlẹrii Jehofah nfi awọn Kristian wọnyi hàn yatọ gẹgẹ bi ‘awọn eniyan fun orukọ Ọlọrun.’ Wọn yangan lati jẹ orukọ yẹn, nitori pe ó jẹ eyi tí Jehofah Ọlọrun funraarẹ̀ fun awọn olujọsin tootọ. Ninu Isaiah 43:10, a kà á pe: “‘Ẹyin ni ẹlẹrii mi,’ ni [Jehofah] wi, ‘iranṣẹ mi tí mo ti yàn.’” Tani Ọlọrun nsọrọ nipa rẹ̀ nihin yii? Ṣayẹwo diẹ lara awọn ẹsẹ iṣaaju.
Ninu ẹsẹ Isa 43 5 si 7 ori kan naa, Isaiah sọ pe: “Má bẹru, nitori emi wà pẹlu rẹ; emi yoo mú iru-ọmọ rẹ lati ila-oorun wá, emi yoo si ṣà á jọ lati iwọ-oorun wá. Emi yoo si wi fun ariwa pe, Dá a silẹ; ati fun guusu pe, Maṣe dá a duro; mú awọn ọmọ mi ọkunrin lati okeere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá, olukuluku ẹni tí a npè ní orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ògo mi, mo ti mọ ọ́n, ani, mo ti ṣe é pé.” Lọjọ tiwa, awọn ẹsẹ wọnni ntọkasi awọn eniyan Ọlọrun funraarẹ̀ tí oun ti kojọ lati inu gbogbo orilẹ-ede lati fi ìyìn fun un ati lati jẹ ẹlẹrii rẹ̀. Nipa bẹẹ kii ṣe kiki pe orukọ Ọlọrun nfi i hàn yatọ nikan ni ṣugbọn ó tún nṣeranwọ lati fi awọn iranṣẹ rẹ̀ tootọ hàn yatọ lori ilẹ-aye lonii.
Awọn Ibukun Lati Inu Mímọ Orukọ Ọlọrun
Jehofah ndaabobo awọn wọnni tí wọn nifẹẹ orukọ rẹ̀. Onipsalm naa sọ pe: “Nitori pe ó ti gbé ifẹni rẹ̀ lé ori mi, Emi pẹlu yoo pese àjàbọ́ fun un. Emi yoo daabobo ó nitori ó ti wá lati mọ orukọ mi.” (Psalm 91:14) Oun pẹlu nranti wọn: “Nigba naa ni awọn tí [wọn] bẹru [Jehofah] nbá ara wọn sọrọ nigbakugba: [Jehofah] si tẹ́tí si i, ó si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn tí [wọn] bẹru [Jehofah], tí wọn si nṣe aṣaro fun orukọ rẹ̀.”—Malachi 3:16.
Nipa bayii, awọn èrè-anfaani lati inu mímọ̀ ati ninifẹẹ orukọ Ọlọrun ni a kò fi mọ si iwalaaye yii nikan. Fun araye onigbọran ni Jehofah ti ṣeleri iwalaaye titilae ninu ayọ lori Paradise ilẹ-aye. A misi David lati kọwe pe: “Nitori tí a o ké awọn oluṣe buburu kuro: ṣugbọn awọn tí [wọn] duro de [Jehofah] ni yoo jogun ayé. Wọn yoo si maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.”—Psalm 37:9, 11.
Bawo ni eyi yoo ti ṣeeṣe? Jesu fun wa ní idahun. Ninu Adura Awokọṣe kan naa nibi ó ti kọ́ wa lati gbadura “ki a sọ orukọ rẹ di mímọ́,” ó fikun un pe: “Ki ijọba rẹ dé, ki ifẹ-inu rẹ di ṣiṣe, gẹgẹ bi ní ọrun, lori ilẹ-aye pẹlu.” (Matthew 6:9, 10, NW) Bẹẹ ni, Ijọba Ọlọrun lọwọ Jesu Kristi yoo sọ orukọ Ọlọrun di mímọ́, tí yoo si tún mú ipo didara wá si ilẹ-aye yii. Yoo pa iwa-ibi rẹ́, yoo si mú ogun, iwa-ipá, ìyàn, aisan ati iku kuro.—Psalm 46:8, 9; Isaiah 11:9; 25:6; 33:24; Ifihan 21:3, 4.
Iwọ le gbadun iwalaaye titilae labẹ Ijọba yẹn. Bawo ni? Nipa wíwá lati mọ Ọlọrun. “Iye ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o le mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni tí iwọ rán.” (John 17:3) Inu awọn Ẹlẹrii Jehofah yoo dùn lati ràn ọ lọwọ lati ní imọ tí nfunni ní ìyè yẹn.—Iṣe 8:29-31.
Ireti wa ni pe isọfunni tí ó wà ninu iwe pẹlẹbẹ yii ti fun ọ ní idaloju-igbagbọ pe Ẹlẹdaa naa ní orukọ ara-ẹni kan tí ó ṣe iyebiye gidigidi fun un. Ó nilati ṣe iyebiye fun iwọ naa pẹlu. Njẹ ki iwọ ki ó mọ̀ ní àmọ̀dunjú ijẹpataki mímọ̀ ati lilo orukọ yẹn, ní pataki ninu ijọsin.
Njẹ ki iwọ si ronupinnu lati sọ gẹgẹ bi wolii Micah ti fi tigboya-tigboya sọ ní ọpọ ọgọrun ọdun sẹhin pe: “Nitori gbogbo awọn eniyan yoo maa rìn, olukuluku ní orukọ [ọlọrun] tirẹ̀, awa yoo si maa rìn ní orukọ [Jehofah] Ọlọrun wa lae ati titi laelae.”—Micah 4:5.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
‘Mímọ orukọ Ọlọrun’ rekọja níní imọ ori lasan nipa otitọ-iṣẹlẹ naa pe orukọ rẹ̀ ni Jehofah
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
Orukọ Jehofah ní ‘ọlá, itobi, ẹ̀rù, ó si ga ju ohun gbogbo lọ.’ Gbogbo awọn ete Ọlọrun ni a sopọ mọ́ orukọ rẹ̀
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ninu akori ọrọ kan ninu Anglican Theological Review (October 1959), Dr. Walter Lowrie pe ọ̀gangan-afiyesi sori aini naa lati mọ orukọ Ọlọrun. Ó kọwe pe: “Ninu awọn ibaṣepọ ẹda-eniyan ó ṣe pataki pupọ lati mọ orukọ naa gan-an, orukọ ti ara-ẹni, ti ẹni tí a nifẹẹ rẹ̀, ẹni tí a nbá sọrọ, tabi paapaa nipa ẹni tí a nsọrọ nipa rẹ̀. Bẹẹ gan-an ni ó rí ninu ibatan eniyan si Ọlọrun. Eniyan kan tí kò mọ Ọlọrun nipa orukọ rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n gẹgẹ bi ẹnikan niti gidi, kò ní ominira ibanisọrọ pẹlu rẹ̀ (eyi tí adura tumọsi), kò si le nifẹẹ rẹ̀, bi ó bá mọ̀ ọ́n gẹgẹ bi ipá kan tí wíwà rẹ̀ kii ṣe bii ti ẹnikan.”