Orukọ Ọlọrun ati Awọn Atumọ Bibeli
Orukọ Ọlọrun ati Awọn Atumọ Bibeli
NÍ KÙTÙKÙTÙ ọgọrun ọdun keji, lẹhin tí eyi tí ó kẹhin lara awọn apostle ti kú, ṣiṣako lọ kuro ninu igbagbọ Kristian tí Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ti sọtẹlẹ bẹrẹ ní pẹrẹu. Awọn imọ-ọran ati ẹkọ-isin keferi di eyi tí ó wọ inu ijọ; ẹya-isin ati iyapa laarin ijọ dide, ìmọ́gaara igbagbọ ní ipilẹṣẹ si di eyi tí a sọdibajẹ. A si dẹkun lilo orukọ Ọlọrun.
Bi isin Kristian apẹhinda si ti ntankalẹ, aini dide lati tumọ Bibeli lati inu ede Hebrew ati Greek ti ipilẹṣẹ si ede miiran. Bawo ni awọn atumọ ṣe tumọ orukọ Ọlọrun ninu itumọ wọn? Bii ti atẹhinwa, wọn lo “Oluwa” bi ibaṣedeedee. Itumọ olokiki lakoko igba yẹn ni Latin Vulgate, itumọ Bibeli tí a ṣe lati ọwọ Jerome si Latin tí a nsọ lojoojumọ. Jerome tumọ Tetragrammaton naa (YHWH) nipa fifi Dominus, “Oluwa” ṣe arọpo rẹ̀.
Lẹhin-ọ-rẹhin, awọn ede titun, bii French, Gẹẹsi ati Spanish bẹrẹsi yọju ní Europe. Bi o tiwu ki o ri, Ṣọọṣi Catholic kó irẹwẹsi bá titumọ Bibeli si awọn ede titun wọnyi. Nipa bayii, niwọn bi awọn Jew, ní lilo Bibeli lede Hebrew ti ipilẹṣẹ, ti kọ̀ lati pe orukọ Ọlọrun nigba tí wọn bá rí i, eyi tí ó pọ̀ julọ ninu “awọn Kristian” gbọ́ kika Bibeli ní itumọ Latin tí kò lo orukọ naa.
Lẹhin akoko gigun diẹ, orukọ Ọlọrun pada di lílò. Ní ọdun 1278 ó farahan lede Latin ninu iṣẹ naa Pugio fidei (Dagger of Faith [Idà Igbagbọ]), lati ọwọ Raymundus Martini, ajẹjẹ-anikandagbe ara ilẹ Spain kan. Raymundus Martini lo sípẹ́lì naa Yohoua. * Kò pẹ́ lẹhin naa, ní 1303, ni Porchetus de Salvaticis ṣe aṣepari iṣẹ kan tí akọle rẹ̀ njẹ́ Victoria Porcheti adversus impios Hebraeos (Ijagunmolu Porchetus Lodisi Awọn Ara Hebrew Alaiwa-bi-Ọlọrun). Ninu eyi, oun, pẹlu, mẹnukan orukọ Ọlọrun ní oniruuru sípẹ́lì bii Iohouah, Iohoua ati Ihouah. Nigba naa, ní 1518, Petrus Galatinus ṣe itẹjade iṣẹ kan tí akọle rẹ̀ njẹ De arcanis catholicae veritatis (Nipa Awọn Aṣiri Otitọ Agbaye) ninu eyi tí ó kọ orukọ Ọlọrun gẹgẹ bi Iehoua.
Orukọ naa farahan nigba akọkọ ninu Bibeli Gẹẹsi kan ní 1530, nigba tí William Tyndale ṣe itẹjade itumọ awọn iwe marun akọkọ inu Bibeli. Ninu eyi oun lo orukọ Ọlọrun, bii ti atẹhinwa ní kikọ sípẹ́lì rẹ̀ ní Iehouah ninu ọpọlọpọ awọn ẹsẹ Bibeli, * ati pe ninu ọrọ pataki kan ninu ẹ̀dà yii, ó kọwe pe: “Iehovah ni orukọ Ọlọrun . . . Siwaju si i ní gbogbo igba tí o bá rí OLUWA ní awọn lẹta gàdàgbà-gàdàgbà (ayafi tí aṣiṣe bá wà ninu iwe títẹ̀) eyi jẹ Iehovah ti ede Hebrew.” Lati inu eyi ni iṣe-aṣa naa ti dide nipa lilo orukọ Jehofah ninu kiki iwọnba awọn ẹsẹ kereje kan ati kikọ “OLUWA” tabi “ỌLỌRUN” ninu eyi tí ó pọ̀ julọ ninu awọn ibomiran nibi tí Tetragrammaton ti wáyé ninu awọn ọrọ Hebrew.
Ní 1611 ohun tí ó di itumọ ede Gẹẹsi tí ó gbajumọ julọ, Authorized Version, ni a tẹjade. Ninu eyi, orukọ naa farahan lẹẹmẹrin ninu awọn ibi pataki. (Exodus 6:3; Psalm 83:18; Isaiah 12:2; 26:4) “Jah,” ikekuru eléwì kan fun orukọ naa, farahan ninu Psalm 68:4. Orukọ naa si farahan lẹkunrẹrẹ ninu awọn orukọ-adugbo bii “Jehovah-jireh.” (Genesis 22:14; Exodus 17:15; Awọn Onidajọ 6:24) Bi o tiwu ki o ri, ní titẹle apẹẹrẹ Tyndale, awọn olutumọ naa lọpọ igba fi “OLUWA” tabi “ỌLỌRUN” dipo orukọ Ọlọrun. Ṣugbọn bi orukọ Ọlọrun bá le farahan ninu awọn ẹsẹ mẹrin, eeṣe tí kò le farahan ninu ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹsẹ miiran tí wọn ní in ninu lede Hebrew ti ipilẹṣẹ?
Ohun kan tí ó farajọ eyi nṣẹlẹ lede Germany. Ní 1534 Martin Luther ṣe itẹjade itumọ odi-ndi Bibeli tirẹ̀, eyi tí ó gbeka ori awọn ede ti ipilẹṣẹ. Fun awọn idi kan kò fi orukọ Ọlọrun sinu rẹ̀ ṣugbọn ó lo awọn àfidípò, bii HERR (“OLUWA”). Bi o tiwu ki o ri, ó mọ orukọ atọrunwa naa, nitori pe ninu iwaasu kan tí oun ṣe lori Jeremiah 23:1-8, ní 1526, oun sọ pe: “Orukọ yii Jehofah, Oluwa, jẹ eyi tí a yasọtọ gedegbe fun Ọlọrun tootọ naa.”
Ní 1543 Luther kanjú abẹ níkòó nipa kikọwe pe: “Pe wọn [awọn Jew] lè wá kede laisi ami-ẹri nisinsinyi pe orukọ naa Jehofah nilati jẹ alaileṣeepè, wọn kò mọ ohun tí wọn nsọrọ nipa rẹ̀ . . . Bi wọn bá le fi kálàmù ati tàdáwà kọ orukọ naa silẹ, eeṣe tí wọn kò fi nilati sọ ọ jade lẹnu, eyi tí ó tilẹ sunwọn ju kikọ ọ́ silẹ pẹlu kálàmù ati tàdáwà lọ? Eeṣe tí wọn kò fi pè é ní alaileṣeekọsilẹ, alaileṣeeka, tabi alaileṣeeronu lé lori? Bi a bá gbé gbogbo awọn nkan wọnyi yẹwo, iwa òjóró kan wà nibẹ.” Ṣugbọn, Luther kò ṣe atunṣe awọn ọran naa ninu itumọ Bibeli tirẹ̀. Ní awọn ọdun diẹ lẹhin naa, bi o tiwu ki o ri, orukọ naa farahan ninu awọn Bibeli miiran lede Germany ninu Exodus 6:3.
Ní ọpọ ọgọrọọrun ọdun lẹhin naa, awọn atumọ Bibeli bẹrẹsi tọ ọ̀kan lara awọn ipa-ọna meji naa. Awọn kan yẹra fun lilo orukọ Ọlọrun patapata, nigba tí awọn miiran lò ó lọna gbigbooro ninu Iwe-mimọ Hebrew, boya gẹgẹ bi Jehofah tabi Yahweh. Ẹ jẹ ki a ṣayẹwo awọn itumọ meji tí wọn yẹra fun orukọ naa ki a si rí idi, ní ibamu pẹlu ohun tí awọn atumọ wọn sọ, tí wọn fi ṣe eyi.
Idi Tí Wọn Fi Yọ Ọ́ Silẹ
Nigba ti J. M. Powis Smith ati Edgar J. Goodspeed ṣe itumọ Bibeli ti ode-oni kan ní 1935, awọn onkawe rí i pe OLUWA ati ỌLỌRUN ni a ti lò ní awọn ibi tí ó pọ̀ julọ gẹgẹ bi àfidípò kan fun orukọ Olọrun. Idi naa ni a ṣalaye ninu ọrọ-akọsọ kan pe: “Ninu itumọ yii a ti tẹle ofin-atọwọdọwọ awọn Jew tí ó wọpọ a si ti fi ‘Oluwa’ dipo orukọ naa ‘Yahweh’ ati ẹ̀là-gbolohun naa ‘Oluwa Ọlọrun’ dipo si ‘Oluwa Yahweh.’ Ní gbogbo awọn ọran nibi tí ‘Oluwa’ tabi ‘Ọlọrun’ bá ti duro fun ‘Yahweh’ awọn lẹta gàdàgbà-gàdàgbà keekeeke ni a lò.”
Lẹhin naa, ní sisori ofin-atọwọdọwọ awọn Jew tí wọn nka YHWH ṣugbọn tí wọn npè é ní “Oluwa” kodò lọna aramanda kan, ọrọ-akọsọ naa wipe: “Ẹnikẹni, nitori, tí ó ní ifẹ-ọkan lati di adùn ọrọ ti ipilẹṣẹ naa mú titi nilati ka ‘Yahweh’ nibikibi tí ó bá ti rí OLUWA tabi ỌLỌRUN”!
Ní kika eyi, ibeere naa tí yoo wá si ọkàn lẹsẹkẹsẹ ni pe: “Bi kika “Yahweh” dipo “OLUWA” bá di “adùn ọrọ ipilẹṣẹ” mú titi, eeṣe tí awọn atumọ kò fi lo “Yahweh” ninu itumọ wọn? Eeṣe tí wọn, ní ibamu pẹlu ọrọ awọn tikalaraawọn, ṣe fi ọrọ naa “OLUWA” ‘ṣàfidípò’ orukọ Ọlọrun tí wọn si tipa bayii tàwọ̀n boju adùn ọrọ ipilẹṣẹ naa?
Awọn atumọ naa sọ pe awọn ntẹle ofin-atọwọdọwọ Jew tí ó wọpọ. Sibẹ eyiini ha bá ọgbọn mu fun Kristian kan bi? Ranti pe awọn Pharisee ni wọn npa ofin-atọwọdọwọ awọn Jew tí ó wọpọ mọ́, awọn ni wọn kọ Jesu silẹ, tí Jesu si sọ fun wọn pe: “Ẹyin ti sọ ofin Ọlọrun di asan nipa ofin-atọwọdọwọ yin.” (Matthew 15:6) Iru àfidípò bẹẹ nsọ Ọrọ Ọlọrun di alailera nitootọ.
Ní 1952 a tẹ Revised Standard Version ti Iwe-mimọ Hebrew jade lede Gẹẹsi, ati pe Bibeli yii, pẹlu, lo awọn àfidípò fun orukọ Ọlọrun. Eyi yẹ ní ṣiṣakiyesi nitori pe American Standard Version ti ipilẹṣẹ, tí eyi jẹ́ atunyẹwo rẹ̀, lo orukọ naa Jehofah jálẹ̀jálẹ̀ Iwe-mimọ Hebrew. Fun idi yii, yiyọ orukọ naa silẹ jẹ ìyàkúrò kan tí ó hàn ketekete. Eeṣe tí wọn fi ṣe bẹẹ?
Ninu ọrọ-akọsọ ti Revised Standard Version, a kà pe: “Fun awọn idi meji Igbimọ naa ti fàbọ̀ sori ìlò ti gbogbo wa ti mọ̀ dunju naa ti King James Version [eyiini ni, gbigbojufo orukọ Ọlọrun dá]: (1) ọrọ naa ‘Jehofah’ kò duro lọna pipeye-pérépéré fun Orukọ eyikeyi tí a tíì fi igba kan rí lò lede Hebrew; ati (2) lilo orukọ gidi eyikeyi fun Ọlọrun kanṣoṣo naa, bii ẹnipe awọn ọlọrun miiran wà tí a nilati fi iyatọ hàn laarin wọn, ni a ti dáwọ́ lílò rẹ̀ duro ninu isin Judaism ṣaaju akoko awọn Kristian ati pe eyi kò si ní ibamu rara pẹlu igbagbọ Ṣọọṣi Kristian latoke-delẹ.”
Awọn ijiyan wọnyi ha lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bi? Ó dara, ní ibamu pẹlu ohun tí a ti jiroro ní iṣaaju, orukọ naa Jesu kò duro lọna pipeye-pérépéré fun orukọ Ọmọkunrin Ọlọrun tí awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lo. Sibẹ eyi kò yí ero Igbimọ naa pada lati yẹra fun lilo orukọ yẹn, ki wọn si lo awọn orukọ-òye bii “Alarina” tabi “Kristi” dipo rẹ̀. Lootọ, awọn orukọ-òye wọnyi ni a lò, ṣugbọn ní afikun si orukọ naa Jesu ni, kii ṣe dipo rẹ̀.
Nipa ijiyan naa pe kò si awọn ọlọrun miiran lara awọn eyi tí a gbọdọ fi iyatọ hàn laarin Ọlọrun tootọ, jẹ ohun tí kò tọna. Aimọye araadọta ọkẹ awọn ọlọrun ni araye njọsin. Apostle Paul ṣakiyesi eyi: “Ọpọ ‘ọlọrun’ ni ó wà.” (1 Corinth 8:5; Philippi 3:19) Dajudaju, Ọlọrun tootọ kanṣoṣo ni ó wà, ní ibamu pẹlu ohun tí Paul tẹsiwaju lati sọ. Fun idi eyi, ọla-anfaani titobi kan ti lilo orukọ Ọlọrun tootọ ni pe ó nfi i hàn yatọ kuro lara awọn ọlọrun eke. Yatọ si eyi, bi lilo orukọ Ọlọrun bá jẹ eyi tí “kò si ní ibamu rara,” eeṣe tí ó fi farahan ní iye tí ó fẹrẹẹ tó 7,000 igba ninu Iwe-mimọ Hebrew ti ipilẹṣẹ?
Otitọ naa ni pe, ọpọ awọn atumọ kò nimọlara pe orukọ naa, pẹlu pípè rẹ̀ ti ode-oni, jẹ eyi tí kò ṣegẹ́gẹ́ pẹlu Bibeli. Wọn ti fi i si awọn ẹ̀dà tiwọn, abajade rẹ̀ nigba gbogbo si ni itumọ kan tí nbọla fun Onṣewe Bibeli naa tí ó si nfi tootọ-tootọ walẹ̀ jìn sinu awọn ọrọ ipilẹṣẹ siwaju si i. Diẹ ninu awọn ẹ̀dà tí a ti lò lọna gbigbooro tí wọn ní orukọ naa ninu ni itumọ ti Valera (lede Spanish, tí a tẹjade ní 1602), ẹ̀dà ti Almeida (lede Portuguese, tí a tẹjade ní 1681), ẹ̀dà Elberfelder ti ipilẹṣẹ (lede Germany, tí a tẹjade ní 1871), ati American Standard Version (lede Gẹẹsi, tí a tẹjade ní 1901). Awọn itumọ diẹ, ní pataki The Jerusalem Bible, lo orukọ Ọlọrun lọna iṣedeedee-ṣọkan-délẹ̀ ṣugbọn pẹlu sípẹ́lì naa Yahweh.
Nisinsinyi ka awọn alaye tí diẹ lara awọn atumọ tí wọn fi orukọ naa sinu itumọ tiwọn sọ, ki o si ṣe ifiwera ero-ori wọn pẹlu ti awọn wọnni tí wọn gbojufo orukọ naa dá.
Idi Tí Awọn Miiran Fi Lo Orukọ Naa
Nihin ni a rí alaye naa tí awọn atumọ American Standard Version ti 1901 ṣe: “[Awọn atumọ] ni a mú wá si idaloju-igbagbọ onifimọṣọkan pe gbigba ohun asan gbọ́ awọn Jew, ti wọn ka Orukọ Atọrunwa naa si ohun tí ó mọ́ pupọpupọ kọja nkan tí a le fẹnusọ jade, kii ṣe ohun tí ó yẹ ki ó jọba lori itumọ ede Gẹẹsi tabi itumọ eyikeyi ti Majẹmu Laelae . . . Orukọ manigbagbe yii, tí a ṣalaye rẹ̀ ninu Ex. iii. 14, 15, tí a si tẹnumọ leralera ninu ọrọ ipilẹṣẹ ti Majẹmu Laelae, ndarukọ Ọlọrun gẹgẹ bi ẹ̀dá kan, gẹgẹ bi Ọlọrun majẹmu, Ọlọrun iṣipaya, Oludande, Ọ̀rẹ́ awọn eniyan rẹ̀ . . . Orukọ ara-ẹni yii, pẹlu ọpọ awọn ibakẹgbẹ mímọ́ pẹlu rẹ̀, nisinsinyi ni a ti mú padabọsipo si àyè naa ninu ọrọ mímọ́ si eyi tí kò si iyemeji nipa rẹ̀.”
Bakan naa, ninu ọrọ-akọsọ Elberfelder Bibel ti ede Germany ní ipilẹṣẹ a kà pe: “Jehova. A ti di orukọ yii fun Ọlọrun Majẹmu Israel mú titi nitori pe ó ti mọ́ onkawe lara fun ọpọ ọdun.”
Steven T. Byington, atumọ The Bible in Living English, ṣalaye idi tí oun fi lo orukọ Ọlọrun: “Sípẹ́lì naa ati pípè naa kii ṣe ohun tí ó ṣe pataki lọna giga. Ohun tí ó ṣe pataki lọna giga ni lati mọ̀ ọ́n lọna tí ó ṣe kedere pe orukọ ara-ẹni kan ni eyi jẹ. Ọpọ awọn ẹsẹ Bibeli ni wọn wà tí a kò le loye wọn daradara bi a bá tumọ orukọ yii si ọrọ-orukọ wiwọpọ kan bii ‘Oluwa,’ tabi, ní eyi tí ó buru jù, si ọrọ-apejuwe kan tí ó wà pẹtiti [fun apẹẹrẹ, Ayeraye].”
Ọran itumọ miiran, lati ọwọ J. B. Rotherham, jẹ eyi tí ó gba afiyesi. Oun lo orukọ Ọlọrun ninu itumọ rẹ̀ ṣugbọn ní fifaramọ Yahweh. Bi o tiwu ki o ri, ninu iṣẹ kan tí a ṣe lẹhin naa, Studies in the Psalms, tí a tẹjade ní 1911, oun fàbọ̀ sori lilo Jehofah. Eeṣe? Ó ṣalaye: “JEHOVAH.—Àmúlò orukọ Manigbagbe naa lede Gẹẹsi (Exo. 3:18) ninu ẹ̀dà awọn Iwe Psalm ti lọọlọọ yii kii ṣe eyi tí ó dide lati inu iyemeji eyikeyi niti pípè naa tí ó tọna, pe ó njẹ́ Yahwéh; ṣugbọn nitori eyi tí a gbeka kiki ori ẹri-ami ohun tí nṣẹlẹ nikan ni mo ṣe yàn funraami niti ifẹ-ọkan naa lati wà ní ibamu pẹlu etí-ìgbọ́ ati oju-iriran gbogbo eniyan ninu iru ọran bayii, ninu eyi tí ohun tí ó ṣe pataki julọ jẹ́ mimọ orukọ Atọrunwa naa ní àmọ̀dájú pẹlu irọrun jẹ́ ipetepero mi.”
Awọn olujọsin Jehofah ni a gbaniyanju ninu Psalm 34:3, NW pe: “Gbé Jehofah leke pẹlu mi, ẹyin eniyan, ẹ jẹ ki a gbé orukọ rẹ̀ ga lapapọ.” Bawo ni awọn onkawe awọn itumọ Bibeli tí wọn gbojufo orukọ Ọlọrun dá ṣe le dahunpada lẹkunrẹrẹ si ọrọ-iyanju yẹn? Awọn Kristian layọ pe ó keretan awọn atumọ diẹ ti ní igboya lati fi orukọ Ọlọrun kún awọn itumọ wọn niti Iwe-mimọ Hebrew, tí wọn si tipa bayii pa ohun tí Smith ati Goodspeed pè ní “adùn ọrọ ti ipilẹṣẹ” mọ́.
Bi o tiwu ki o ri, eyi tí ó pọ̀ julọ ninu awọn itumọ wọnyi, ani nigba tí wọn bá tilẹ fi orukọ Ọlọrun kún Iwe-mimọ Hebrew paapaa, maa nfò ó dá ninu Iwe-mimọ Greek Kristian, “Majẹmu Titun” naa. Kinni idi naa fun eyi? Idalare kankan ha wà fun fifi orukọ Ọlọrun kún apá tí ó kẹhin ninu Bibeli?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 Awọn iwe tí a tẹ̀ lori iṣẹ yii ní awọn ọgọrun ọdun diẹ lẹhin naa, bi o tiwu ki o ri, ní orukọ atọrunwa naa tí a kọ sípẹ́lì rẹ̀ ní Jehova.
^ ìpínrọ̀ 6 Genesis 15:2; Exodus 6:3; 15:3; 17:16; 23:17; 33:19; 34:23; Deuteronomy 3:24. Tyndale pẹlu fi orukọ Ọlọrun sinu Ezekiel 18:23 ati Eze 36:23, ninu awọn itumọ tirẹ̀ tí a fi ṣe afikun ní opin The New Testament, Antwerp, 1534.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]
Awọn atumọ Authorized Version pa orukọ Ọlọrun, Jehofah, mọ́ ninu kiki ẹsẹ mẹrin pere, wọn fi ỌLỌRUN ati OLUWA ṣe àfidípò ní gbogbo awọn ibi tí ó kù
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Bi lilo orukọ Ọlọrun bá jẹ́ eyi tí “kò si ní ibamu rara,” eeṣe tí ó fi farahan ní iye tí ó fẹrẹẹ tó 7,000 igba ninu ọrọ-aarin-iwe Hebrew ti ipilẹṣẹ?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Iṣọta si Orukọ Ọlọrun Kẹ̀?
Titi di isinsinyi, kò si itumọ Bibeli ti lọọlọọ yii ní ede Afrikaans (ede tí awọn ara South Africa tí awọn babanla wọn jẹ́ Dutch nsọ) tí ó ní orukọ Ọlọrun ninu. Eyi jẹ iyalẹnu, niwọn bi ọpọ itumọ tí a ṣe si awọn ede ibilẹ tí wọn nsọ ní orilẹ-ede yẹn ti nlo orukọ naa ní fàlàlà. Ẹ jẹ ki a wo bi eyi ṣe bẹrẹ.
Ní August 24, 1878, ìpàrọwà alagbara kan ni a ṣe nibi ipade Society of True Afrikaners (G.R.A.) pe ki a ṣe itumọ Bibeli lede Afrikaans. Ọdun mẹfa lẹhin naa, koko-ọran naa ni a mú wá si ojutaye lẹẹkan si i, ati pe lẹhin-ọ-rẹhin a ṣe ipinnu lati tẹsiwaju ki wọn si tumọ Bibeli lati inu awọn ede ipilẹṣẹ. Iṣẹ naa ni a fi si ìkáwọ́ S. J. du Toit, Ọga-agba Patapata fun Eto Ẹkọ-iwe ní Transvaal.
Ninu lẹta itọni kan tí a kọ si du Toit ni imọran yii wà pe: “Orukọ gidi naa fun Oluwa, Jehovah tabi Jahvê, ni a gbọdọ fisilẹ laitumọ [eyiini ni pe, a kò gbọdọ fi Oluwa tabi Ọlọrun ṣe àfidípò rẹ̀] jálẹ̀jálẹ̀.” S. J. du Toit tumọ iwe Bibeli meje si ede Afrikaans, orukọ naa Jehofah si farahan jálẹ̀jálẹ̀.
Awọn itẹjade South Africa miiran, pẹlu, ní akoko kan ní orukọ Ọlọrun ninu. Fun apẹẹrẹ, ninu De Korte Catechismus (Catechism Kukuru Naa), lati ọwọ J. A. Malherbe, 1914, ohun tí ó tẹle e yii farahan: “Kinni orukọ giga julọ fun Ọlọrun?” Ki si ni idahun rẹ̀? “Jehovah, eyi tí a kọ ní OLUWA ní awọn lẹta gàdàgbà-gàdàgbà ninu Bibeli wa. [Orukọ] yii ni a kò fi igba kan rí fi fun ẹda eyikeyi.”
Ninu Die Katkisasieboek (catechism kan tí a tẹjade lati ọwọ Federated Sunday School Commission ti Ṣọọṣi Alatunṣe Dutch ní South Africa) ni ibeere tí ó tẹle e yii farahan: “Nigba naa awa kò ha nilati lo orukọ naa Jehovah tabi OLUWA laelae bi? Eyiini ni ohun tí awọn Jew nṣe . . . Eyiini kii ṣe itumọ ofin-aṣẹ naa. . . . A le lo Orukọ rẹ̀, ṣugbọn kii ṣe lasan.” Titi di aipẹ yii, awọn àtúntẹ̀ (iwe orin) ti Die Halleluja pẹlupẹlu ní orukọ naa Jehofah ninu diẹ lara awọn orin rẹ̀.
Bi o tiwu ki o ri, itumọ du Toit kò lokiki, ati pe ní ọdun 1916 ni a yan Ajọ fun Itumọ Bibeli kan lati bojuto ṣiṣe Bibeli lede Afrikaans. Ajọ yii ti pinnu lati fo orukọ naa Jehofah dá ninu Bibeli. Ní 1971 ajọ naa Bible Society of South Africa gbé “itumọ ká ṣì maa wò ó” kan lara iwọnba diẹ ninu awọn iwe Bibeli lede Afrikaans jade. Bi o tilẹ jẹ pe a mẹnukan orukọ Ọlọrun ninu inasẹ-ọrọ naa, a kò lò ó ninu awọn ọrọ-aarin-iwe itumọ naa. Bakan naa, ní 1979 itumọ titun ti “Majẹmu Titun” ati Psalm farahan, oun pẹlu si fo orukọ Ọlọrun dá.
Siwaju si i, lati 1970 mimẹnukan orukọ naa Jehofah ni a ti yọ kuro ninu Die Halleluja. Ati pe atunṣe itẹjade kẹfa ti ẹ̀dà Die Katkisasieboek, tí a tẹ̀ lati ọwọ Ṣọọṣi Alatunṣe ti Dutch ní South Africa, pẹlupẹlu fo orukọ naa dá nisinsinyi.
Nitootọ, awọn isapa lati sọ orukọ naa Jehofah di olóògbé ni a kò fi mọ sori awọn iwe nikan. Ṣọọṣi Alatunṣe ti Dutch kan ní Paarl ti fi igba kan rí ní okuta-igun-ile kan lara eyi tí a kọ awọn ọrọ yii si JEHOVAH JIREH (“Jehofah Yoo Pese”). Aworan ṣọọṣi yii ati okuta-igun-ile rẹ̀ farahan ninu ẹ̀dà October 22, 1974, ti iwe-irohin Ji! lede Afrikaans. Lati igba naa, wọn ti fi okuta-igun-ile miiran tí ó ní awọn ọrọ wọnyi DIE HERE SAL VOORSIEN (“OLUWA Yoo Pese”) dipo rẹ̀. Ẹsẹ iwe-mimọ tí a yàn ati ọjọ tí ó wà lori okuta-igun-ile naa ni a kò yipada, ṣugbọn orukọ naa Jehofah ni a ti yọ kuro.
Fun idi eyi, ọpọ awọn Afrikaners lonii ni kò mọ orukọ Ọlọrun. Awọn ọmọ-ẹgbẹ ṣọọṣi tí wọn mọ̀ ọ́n nyẹra fun lílò rẹ̀. Awọn miiran tilẹ njiyan lodisi i, ní sisọ pe OLUWA ni orukọ Ọlọrun tí wọn si nfẹsunkan awọn Ẹlẹrii Jehofah pe wọn ti hùmọ̀ orukọ naa Jehofah.
[Àwọn àwòrán]
Ṣọọṣi Alatunṣe ti Dutch kan ní Paarl, South Africa. Ní ipilẹṣẹ, orukọ naa Jehofah ni a gbẹ́ sara okuta-igun-ile (tí ó wà loke lápá ọ̀tún). Lẹhin eyi, a ṣe àfidípò rẹ̀ (loke lápá òsì)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Orukọ Ọlọrun gẹgẹ bi Yohoua farahan ní 1278 ninu iṣẹ Pugio fidei gẹgẹ bi a ti rí i ninu iwe-alafọwọkọ yii (tí a kọ ní ọgọrun ọdun ikẹtala tabi ikẹrinla) tí ó wá lati yàrá ikowepamọ St. Geneviève, Paris, France (folio 162b)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ninu itumọ tirẹ̀ niti awọn iwe maraarun akọkọ ti Bibeli, tí a tẹjade ní 1530, William Tyndale fi orukọ Ọlọrun sinu Exodus 6:3. Oun ṣalaye lílò tí oun lo orukọ naa ninu isọfunni kan tí a kọ papọ pẹlu itumọ naa
[Credit Line]
(American Bible Society Library, New York, ni ó yọnda fun wa lati lo aworan yii)