Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orukọ Atọrunwa naa Jálẹ̀ Awọn Sanmanni

Orukọ Atọrunwa naa Jálẹ̀ Awọn Sanmanni

Orukọ Atọrunwa naa Jálẹ̀ Awọn Sanmanni

JEHOFAH ỌLỌRUN nfẹ́ ki eniyan mọ̀ ki ó si lo orukọ rẹ̀. Eyi hàn gbangba lati inu otitọ-iṣẹlẹ naa pe Oun ṣe iṣipaya orukọ Rẹ̀ fun awọn eniyan meji akọkọ lori ilẹ-aye. A mọ̀ pe orukọ Ọlọrun kò ṣajeji si Adam ati Efa nitori pe lẹhin tí Efa bí Cain, ní ibamu pẹlu ọrọ Hebrew ní ipilẹṣẹ, Efa sọ pe: “Mo ti bí ọkunrin kan pẹlu iranlọwọ [Jehofah].”​—⁠Genesis 4:1.

Lẹhin naa a kà pe awọn ọkunrin olootọ bii Enoch ati Noah “bá Ọlọrun [tootọ] rìn. (Genesis 5:24; 6:9) Awọn naa pẹlu, nigba naa, gbọdọ ti mọ orukọ Ọlọrun. Orukọ naa la Ikun Omi nla naa já pẹlu ọkunrin olododo naa Noah ati idile rẹ̀. Laika ìdìtẹ̀ titobi tí ó dide lẹhin naa ní Babel si, awọn olootọ iranṣẹ Ọlọrun nbá a lọ lati maa lo orukọ rẹ̀. Ó farahan ní igba ọgọrọọrun ninu awọn ofin tí Ọlọrun fun Israel. Ninu iwe Deuteronomy nikan, ó farahan ní igba 551.

Ní ọjọ awọn onidajọ, dajudaju awọn ọmọ Israel kò tiju lati lo orukọ Ọlọrun. Ani wọn tilẹ lò ó ninu kíkí ẹnikinni-keji wọn paapaa. A kà á (lede Hebrew ipilẹṣẹ) nipa Boaz tí ó nkí awọn olukore rẹ̀ pe: “Ki [Jehofah] wà pẹlu yin.” Wọn dá a lohun pada nipa sisọ pe: “Ki [Jehofah] bukun fun ọ.”​—⁠Ruth 2:4.

Jakejado ọrọ-itan awọn ọmọ Israel ní taarata titi dé akoko igba tí wọn ṣẹ́rípadà si Judah lẹhin ìkólẹ́rú wọn ní Babylon, orukọ Jehofah ni wọn nbá a lọ ní lílò lojoojumọ. Ọba David, ẹni bii ọkàn-àyà Ọlọrun funraarẹ̀, lo orukọ atọrunwa naa lọna pupọ jaburata, ó farahan lọpọ igba ninu awọn psalm tí ó kọ. (Iṣe 13:22) Orukọ Ọlọrun ni a tún fi sinu ọpọ awọn orukọ ti ara-ẹni awọn ọmọ Israel. Nipa bayii a kà nipa Adonijah (“Oluwa mi ni Jah”​—⁠“Jah” jẹ ikekuru Jehofah), Isaiah (“Igbala Jehofah”), Jonathan (“Jehofah Ti Fi Funni”), Micah (“Tani ó dabi Jah?”), ati Joshua (“Jehofah Ni Igbala”).

Lẹhin Ode Bibeli

Ẹri-ami tún wà pẹlu lati awọn orisun lẹhin ode Bibeli nipa lilo orukọ atọrunwa naa lọna pupọ jaburata nigba laelae. Ní 1961 a ṣe awari ibojì inu apata igba laelae kan nibi tí kò jinna pupọ si apá osi iha iwọ-oorun Jerusalem, ní ibamu pẹlu irohin tí ó wà ninu Israel Exploration Journal (Idipọ 13, No. 2). Lara awọn ogiri rẹ̀ ni awọn ọrọ-akọle Hebrew wà tí ó farahan bi eyi tí a ti kọ ní apá ilaji ọgọrun ọdun kẹjọ B.C.E. Awọn ọrọ-akọle naa ní awọn gbolohun bii “Jehofah ni ọba gbogbo ayé” ninu.

Ní 1966 irohin kan ni a tẹ̀ sinu Israel Exploration Journal (Idipọ 16, No. 1) nipa awọn àfọ́kú ìkòkò-amọ̀ pẹlu ikọwe Hebrew lara wọn ni a rí ní Arad, ní iha guusu Israel. Awọn wọnyi ni a kọ ní apá ilaji ọgọrun ọdun keje B.C.E. Ọ̀kan lara wọn ni lẹta kan tí a kọ si ọkunrin kan tí a npè ní Eliashib. Lẹta naa bẹrẹ bayii: “Si oluwa mi Eliashib: Ki Jehofah fun ọ ní alaafia.” Ipari rẹ̀ si kà bayii: “Oun ngbé ninu ile Jehofah.”

Ní 1975 ati 1976, awọn awalẹpitan tí wọn nṣiṣẹ ní Negeb ṣawari akojọ awọn ọrọ-akọle Hebrew ati ti Phoenicia kan tí a kọ sara awọn ogiri rírẹ́, awọn ìṣà ìkó-nkan-pamọ si titobi ati awọn ohun-elo okuta. Awọn ọrọ-akọle naa ní ninu ọrọ Hebrew naa fun Ọlọrun, ati orukọ ­Ọlọrun paapaa, YHWH, ní awọn lẹta Hebrew. Ní Jerusalem funraarẹ̀, ní lọọlọọ yii ni a ṣawari fadaka kekere kan, gigun gbọọrọ tí a ká papọ, tí ó ti wà ṣaaju igbekun ní Babylon. Awọn oluwadii sọ pe nigba tí wọn tú u, wọn rí orukọ Jehofah lede Hebrew tí a kọ si i lara.​—⁠Biblical Archaeology Review, ­March/April 1983, oju-ewe 18.

Apẹẹrẹ miiran ti lilo orukọ Ọlọrun ni a rí ninu ohun tí a nfi iṣina pè ní Awọn Lẹta Lachish. Awọn lẹta wọnyi, tí a kọ sara awọn àpáàdì, ni a rí laarin awọn ọdun 1935 ati 1938 ninu awọn iparun-bajẹ Lachish, ilu olodi olokiki naa ninu ọrọ-itan Israel. Wọn farahan bi eyi tí a kọ lati ọwọ ijoye-oṣiṣẹ kan lẹnu ibode Judea si ọga rẹ̀, tí a npè ní Yaosh, ní Lachish, lasiko ogun naa laarin Israel ati Babylon ní opin ọgọrun ọdun keje B.C.E.

Ninu gbogbo awọn èéfọ́ mẹjẹẹjọ tí wọn ṣee kà naa, meje bẹrẹ ìhìn-iṣẹ wọn pẹlu ìkíni iru bii: “Ki Jehofah jẹ ki asiko yii ṣoju oluwa mi ninu ilera daradara!” Lapapọ, orukọ Ọlọrun farahan ní igba mọkanla ninu awọn ìhìn-iṣẹ mejeeje naa, ní titọkafihan lọna tí ó ṣe kedere pe orukọ Jehofah ni a lò ninu ibarasọrọpọ ojoojumọ titi di opin ọgọrun ọdun keje B.C.E.

Ani awọn keferi alakoso paapaa mọ̀ wọn si lo orukọ atọrunwa naa nigba tí wọn bá nsọrọ nipa Ọlọrun awọn ọmọ Israel. Nipa bayii, lara Okuta Moab, Ọba Mesha ti Moab ṣogo nipa awọn iwa-akin ológun rẹ̀ lodisi Israel, tí ó si sọ pe: “Chemosh sọ fun mi pe, ‘Lọ, gba Nebo lọwọ Israel!’ Nitori naa mo lọ ní òru mo si bá a jà lati owurọ titi di ọ̀sán, mo gbà á, mo pa gbogbo wọn . . . Mo si mú [awọn ohun-elo] Jehofah wá lati ibẹ, mo nwọ́ wọn nílẹ̀ niwaju Chemosh.”

Ninu itọkasi si awọn ìlò tí kii ṣe lati inu Bibeli nipa orukọ Ọlọrun, Theologisches Wörterbuch zum Alten Testament (Iwe Atumọ-ọrọ Ẹkọ-isin ti Majẹmu Laelae), ninu Idipọ kẹta, ìlà 538, sọ pe: “Nipa bayii awọn ẹri-ami alakọsilẹ mọkandinlogun nipa Tetragrammaton ninu jhwh jẹrii si ṣiṣee gbarale M[asoretic] T[ext] (akojọpọ majẹmu laelae lede Hebrew lati ọwọ Masoret); pupọ si i ni a le reti, leke gbogbo rẹ̀ lati inu ibi tí a nkó awọn ohun igba laelae pamọ si tí ó wà ní Arad.”​—⁠A tumọ rẹ̀ lati inu ede Germany.

A Kò Gbagbe Orukọ Ọlọrun

Jíjẹ́ ojulumọ pẹlu ati lilo orukọ Ọlọrun yii nbá a lọ titi di igba ayé Malachi, ẹni tí ó gbé ayé ní nkan bii 400 ọdun ṣaaju akoko Jesu. Ninu iwe Bibeli tí njẹ orukọ rẹ̀, Malachi fun orukọ atọrunwa naa ní ijẹpataki, ní lílò ó ní 48 igba lapapọ.

Bi ọjọ ti ngori ọjọ, ọpọ awọn Jew ni wọn ngbé ibi tí ó jinna-réré si ilẹ Israel, tí awọn kan kò si le ka Bibeli lede Hebrew mọ́. Fun idi yii, ní ọgọrun ọdun kẹta B.C.E., a bẹrẹsi tumọ apakan Bibeli tí ó wà nigba naa (“Majẹmu Laelae”) si ede Greek, ede titun ti a nsọ jakejado. Ṣugbọn orukọ Ọlọrun jẹ eyi tí a dagunla si. Awọn atumọ fi i si ipo rẹ̀ nipa kikọ ọ ní bi a ti ṣe nkọ ọ lede Hebrew. Awọn ẹ̀dà igba laelae ti Septuagint lede Greek tí a pamọ di ọjọ wa jẹrii si eyiini.

Sibẹsibẹ, kinni ipo naa ti rí nigba tí Jesu wà lori ilẹ-aye? Bawo ni a ṣe le mọ̀ boya oun ati awọn apostle rẹ̀ lo orukọ Ọlọrun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ninu lẹta yii, tí a kọ sara àfọ́kù ìkòkò-amọ̀ kan ní apá ilaji ọgọrun ọdun keje B.C.E., orukọ Ọlọrun farahan lẹẹmeji.

[Credit Line]

(Israel Department of Antiquities and Museums ni ó gbà wa láyè lati lo aworan yii)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Orukọ Ọlọrun ni a rí pẹlu awọn Lẹta Lachish ati lara Okuta Moab