Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Padà Sí Ilẹ̀ Wọn
Ọ̀WỌ́ àwọn òkè ńláńlá méjì pàtàkì ló yí ilẹ̀ olókè tó tẹ́jú tá a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Ìráànì lónìí ká, ìyẹn ni, ọ̀wọ́ àwọn òkè Ẹ́líbọ́sì (tó wà ní gúúsù Òkun Kásípíà) àti ọ̀wọ́ àwọn òkè Ságírósì (tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà). Àwọn àfonífojì gígùn tó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tó sì ní àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí koríko bò ló là wọ́n láàárín. Ojú ọjọ́ máa ń dára gan-an láwọn àfonífojì wọ̀nyí, àmọ́ láwọn apá ibí gíga, tó gbẹ táútáú, tí afẹ́fẹ́ sì máa ń gbá mọ́ féfé, ojú ọjọ́ máa ń tútù gan-an nígbà òtútù. Ìtòsí ibí ni aṣálẹ̀ tó jẹ́ ilẹ̀ olókè tó tẹ́jú wà, níbi tí èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí. Àgbègbè tó fẹ̀ lọ rabidun yìí, ní apá ìlà oòrùn Mesopotámíà, ni Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà ti jáde wá.
Apá àríwá ilẹ̀ olókè tó tẹ́jú yìí ni àwọn ará Mídíà fìdí kalẹ̀ sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tó yá, wọ́n tàn dé Àméníà àti Sìlíṣíà. Àmọ́ àwọn ará Páṣíà ní tiwọn wà ní apá gúúsù ilẹ̀ olókè títẹ́jú náà, ìyẹn ìhà ìlà oòrùn Àfonífojì Tígírísì. Nígbà ìṣàkóso Kírúsì, ní ìlàjì ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ìjọba méjèèjì yìí para pọ̀, wọ́n sì di Agbára Ayé Mídíà òun Páṣíà.
Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Kírúsì ṣẹ́gun Bábílónì. Ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì nasẹ̀ dé ilẹ̀ Íńdíà níhà ìlà oòrùn. Lápá ìwọ̀ oòrùn, ó nasẹ̀ dé ilẹ̀ Íjíbítì àti ibi tó wá di ilẹ̀ Tọ́kì lónìí. Ó wá bá a mu gẹ́lẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà gẹ́gẹ́ bí “béárì” arebipa tó “jẹ ẹran púpọ̀.” (Da 7:5) Ìṣàkóso Kírúsì jẹ́ ìṣàkóso aláàánú tó sì ń gba nǹkan mọ́ra. Ó pín ilẹ̀ ọba náà sí ẹlẹ́kùnjẹkùn. Gómìnà kan ló ń ṣàkóso ẹkùn kan, lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ ará Páṣíà, àmọ́ àwọn baálẹ̀ táwọn náà ní agbára díẹ̀ níkàáwọ́ máa ń wà lábẹ́ rẹ̀. Wọ́n yọ̀ǹda fún àwọn èèyàn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ ọba náà kí wọ́n máa bá àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìsìn wọn lọ.
Ìlànà yìí ni Kírúsì tẹ̀ lé tó fi gba àwọn Júù láyè láti padà sí Jerúsálẹ́mù láti lọ mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò, kí wọ́n sì tún Jerúsálẹ́mù kọ́, gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sírà àti Nehemáyà ṣe fi hàn. Ǹjẹ́ o rò pé ọ̀nà tí Ábúráhámù gbà láti Yúfírétì wá sí Kákémíṣì ni àwùjọ ńlá yìí gbà padà, àbí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀nà Tádímórì àti Damásíkù tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà ni wọ́n gbà? Bíbélì kò sọ. (Wo ojú ìwé 6 àti 7.) Bí àkókò ti ń lọ, àwọn Júù tún tẹ̀ dó sí àwọn apá ibòmíràn ní ilẹ̀ ọba náà, irú bí àgbègbè tí odò Náílì ti wọnú òkun àti láwọn apá ìkangun gúúsù lọ́hùn-ún. Àwọn Júù tí kò fi Bábílónì sílẹ̀ pọ̀ díẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí ni ìdí tí àpọ́sítélì Pétérù fi ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà náà. (1Pe 5:13) Dájúdájú, kékeré kọ́ ni Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà ṣe nínú báwọn Júù ṣe dẹni tí kò gbé lójú kan mọ́ lákòókò ìjọba Gíríìsì àti Róòmù, tí wọ́n di agbára ayé lẹ́yìn náà.
Lẹ́yìn tí àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun ilẹ̀ Bábílónì, níbi tí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti máa ń móoru gan-an, wọ́n sọ ìlú náà di ibùjókòó ìṣètò ìlú. Ṣúṣánì, tó ti jẹ́ olú ìlú Élámù nígbà kan rí wà lára àwọn ìlú tó jẹ́ ìlú ọba. Ìlú yìí ni Ahasuwérúsì Ọba Páṣíà náà, (tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni Sásítà Kìíní) ti fi Ẹ́sítérì ṣe ayaba rẹ̀ nígbà kan rí tó sì fọ́ ètekéte kan láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run yán-án-yán jákèjádò ilẹ̀ ọba gbígbòòrò yẹn. Àwọn olú ìlú méjì mìíràn tó tún wà ní Mídíà òun Páṣíà ni Ekibátánà (tó wà ní àgbègbè tó ga tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] mítà, tí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ̀ sì máa ń gbádùn mọ́ni). Bákan náà ni Paságedì, (tí òun náà jẹ́ àgbègbè gíga bákan náà. Nǹkan bí àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta [650] kìlómítà ni síhà gúúsù ìlà oòrùn).
Báwo ni agbára ayé yẹn ṣe dópin? Nígbà tí Mídíà òun Páṣíà wà ní òtéńté agbára rẹ̀, ó gbìyànjú láti paná ọ̀tẹ̀ tí àwọn Gíríìkì gbé dìde níhà àríwá ilẹ̀ ọba náà. Ní àkókò yìí, ilẹ̀ Gírísì pín sí ẹkùn ìlú mẹ́rin tí wọ́n ń dá ìjọba ara wọn ṣe, tí wọ́n sì jẹ́ arógunyọ̀. Àmọ́ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin para pọ̀ láti ṣẹ́gun àwọn agbo ọmọ ogun Páṣíà nínú ogun àjàkú-akátá tó wáyé ní ìlú Márátọ̀n àti Sálámísì. Èyí ló pilẹ̀ bí ilẹ̀ Gíríìsì, tó ti dọ̀kan, ṣe wá gborí mọ́ Mídíà òun Páṣíà lọ́wọ́.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà
A2 MAKEDÓNÍÀ
A2 TÍRÉSÌ
A4 Kírénè
A4 LÍBÍÀ
B2 Bìsáńṣíọ̀mù
B2 LÌDÍÀ
B3 Sádísì
B4 Mémúfísì (Nófì)
B4 ÍJÍBÍTÌ
B5 No-ámónì (Tíbésì)
B5 Síénè
D3 SÌLÍṢÍÀ
D3 Tásù
D3 Ísọ́sì
D3 Kákémíṣì
D3 Tádímórì
D3 SÍRÍÀ
D3 Sídónì
D3 Damásíkù
D3 Tírè
D4 Jerúsálẹ́mù
E2 Fásísì
E2 ÀMÉNÍÀ
E3 ÁSÍRÍÀ
E3 Nínéfè
E4 Bábílónì
Ẹ3 MÍDÍÀ
Ẹ3 Ekibátánà (Akimétà)
Ẹ3 HAIRIKÁNÍÀ
Ẹ4 Ṣúṣánì (Súsà)
Ẹ4 ÉLÁMÙ
Ẹ4 Paságedì
Ẹ4 Pasẹpólíìsì
Ẹ4 PÁṢÍÀ
F3 PÁTÍÀ
F4 DIRANGÍÁNÀ
G2 Marakáńdà (Samakáńdì)
G3 SOGIDÍÁNÀ
G3 BÁKÍTÍRÍÀ
G3 ÁRÍÀ
G4 ARAKÓṢÍÀ
G4 GEDIRÓSÍÀ
GB5 ÍŃDÍÀ
[Àwọn ìbòmíì]
A2 GÍRÍÌSÌ
A3 Márátọ̀n
A3 Áténì
A3 Sálámísì
D1 SÍKÍTÍÀ
D4 Élátì (Élótì)
D4 Témà
E4 ARÉBÍÀ
[Àwọn Òkè]
Ẹ3 ÒKÈ Ẹ́LÍBỌ́SÌ
Ẹ4 ÒKÈ SÁGÍRÓSÌ
[Omi]
B3 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
D2 Òkun Dúdú
D5 Òkun Pupa
Ẹ2 Òkun Kásípíà
Ẹ4 Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà
[Odò]
B4 Náílì
D3 Yúfírétì
E3 Tígírísì
GB4 Íńdọ́sì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn ọmọ ogun Kírúsì ní láti gba àwọn Òkè Ságírósì kọjá kí wọ́n tó ó lè dé Bábílónì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Òkè: Ọ̀nà Àbáwọlé Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Pasẹpólíìsì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Inú Àkámọ́: Sàréè Kírúsì ní Paságedì