Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ilẹ̀ Ọba Gbógun Ti Ilẹ̀ Ìlérí

Àwọn Ilẹ̀ Ọba Gbógun Ti Ilẹ̀ Ìlérí

NÍ ỌDÚN 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn Ásíríà ṣẹ́gun ìlú Samáríà, tí í ṣe olú ìlú ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá. Báyìí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ara wọn lábẹ́ àkóso ilẹ̀ ọba kan tó jẹ́ òǹrorò lákòókò yẹn. Ìkangun apá àríwá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mesopotámíà ni ilẹ̀ Ásíríà wà, nítòsí odò Tígírísì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òdo tó tóbi jù lọ ní Agbègbè Ilẹ̀ Ọlọ́ràá náà. Nímírọ́dù ló tẹ àwọn ìlú tó tóbi jù lọ ní Ásíríà dó, ìyẹn Nínéfè àti Kálà. (Jẹ 10:8-12) Lákòókò Ṣálímánésà Kẹta, Ásíríà tàn dé apá ìwọ̀ oòrùn, títí lọ dé àgbègbè Síríà àti àríwá Ísírẹ́lì tó jẹ́ ilẹ̀ tó lómi tó sì máa ń méso jáde.

Lábẹ́ ìṣàkóso Ọba Tigilati-pílésà Kẹta (Púùlù), tí Bíbélì dárúkọ rẹ̀, Ásíríà bẹ̀rẹ̀ sí ni ilẹ̀ Ísírẹ́lì lára. Ogun tó ń jà kiri tún ṣàkóbá fún Júdà níhà gúúsù pẹ̀lú. (2Ọb 15:19; 16:5-18) Bí àkókò ti ń lọ ìkún “omi” Ásíríà ṣàn dé Júdà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó sì dé Jerúsálẹ́mù olú ìlú Júdà.—Ais 8:5-8.

Ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Senakéríbù, Ọba Ásíríà, gbógun wá sí Júdà. (2Ọb 18:13, 14) Ó ṣẹ́gun ìlú Júdà mẹ́rìndínláàádọ́ta, títí kan ìlú Lákíṣì, tó wà lójútáyé lágbègbè Ṣẹ́fẹ́là, ó sì kò wọn lẹ́rù lọ. Gẹ́gẹ́ bí àwòrán ilẹ̀ ti fi hàn, èyí túmọ̀ sí pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ti jagun kọjá Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ti fi olú ìlú Júdà yìí sáàárín. Nínú ìtàn tí Senakéríbù kọ sílẹ̀, ó fọ́nnu pé òun fi Hesekáyà pa mọ́ sínú “àgò bí ẹyẹ,” àmọ́ àkọsílẹ̀ àwọn ará Ásíríà kò sọ nípa bí áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣe pa àwọn ọmọ ogun Senakéríbù run.—2Ọb 18:17-36; 19:35-37.

Àkókò ti ń sún mọ́lé tí Ilẹ̀ Ọba Ásíríà máa wá sópin. Àwọn ará Mídíà, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ń gbé ní ilẹ̀ olókè gbágungbàgun tá a wá mọ̀ sí Ìráànì [Iran] lónìí, bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó ṣẹ́ kù lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà jà. Èyí mú kí ilẹ̀ Ásíríà pa àwọn àgbègbè tó ń ṣàkóso lé lórí níhà ìwọ̀ oòrùn tì, táwọn wọ̀nyẹn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ní gbogbo àkókò yìí, àwọn ará Bábílónì ti ń di alágbára ńlá, kódà wọ́n ti ṣẹ́gun ìlú Áṣúrì. Lọ́dún 632 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nínéfè—“ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀”—ṣubú sọ́wọ́ àpapọ̀ àwọn ará Bábílónì, Mídíà àtàwọn Síkítíánì, tí wọ́n jẹ́ arógunyọ̀ láti àríwá Òkun Dúdú, wọ́n sì pa á run. Èyí mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Náhúmù àti Sefanáyà ṣẹ.—Na 3:1; Sef 2:13.

Háránì ni òpin ti wá dé bá Ásíríà pátápátá. Nígbà tí agbo ọmọ ogun Bábílónì tó ti pinnu láti rẹ́yìn rẹ̀ gbéjà kò ó, àwọn ará Ásíríà gbìyànjú láti máa dènà wọn títí tí ìrànlọ́wọ́ á fi dé láti Íjíbítì. Àmọ́ nígbà tí Fáráò Nékò ń bọ̀ láti ìhà àríwá, Jòsáyà Ọba Jùdíà dè é lọ́nà ní Mẹ́gídò. (2Ọb 23:29) Nígbà tí Nékò fi máa dé Háránì níkẹyìn, ẹ̀pa ò bóró mọ́—Ilẹ̀ Ọba Ásíríà ti ṣubú.

Ilẹ̀ Ọba Bábílónì

Nígbà tó o bá gbọ́ gbólóhùn náà, “àwọn ọgbà tí a so rọ̀,” ìlú wo ló máa wá sọ́kàn rẹ? Bábílónì ni, tí í ṣe olú ìlú agbára ayé kan nígbàanì, tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi kìnnìún oníyẹ̀ẹ́ lápá. (Da 7:4) Ohun tó mú kí ìlú yìí lókìkí gan-an ni aásìkí, iṣẹ́ ajé, àti ìdásílẹ̀ ìsìn àti wíwo ìràwọ̀ sàsọtẹ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀. Ilẹ̀ títẹ́jú tó jẹ́ ilẹ̀ àbàtà níhà gúúsù Mesopotámíà ni ilẹ̀ ọba yìí fìdí kalẹ̀ sí, lágbedeméjì odò Tígírísì àti odò Yúfírétì. Ìlú ńlá náà ya sí ìhà méjèèjì odò Yúfírétì, àwọn odi rẹ̀ sì jẹ́ kó dà bíi pé kò sẹ́ni tó lè ṣẹ́gun rẹ̀.

Àwọn ará Bábílónì dá àwọn ipa ọ̀nà ìṣòwò sílẹ̀ jákèjádò aṣálẹ̀ olókùúta ní àríwá Arébíà. Ní àkókò kan, Ọba Nábónídọ́sì tiẹ̀ gbé ní Témà, ó sì wá fi Bẹliṣásárì sílẹ̀ ní Bábílónì kó máa ṣàkóso lọ.

Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bábílónì gbé ogun wá ja ilẹ̀ Kénáánì. Lẹ́yìn tí Nebukadinésárì ṣẹ́gun àwọn ará Íjíbítì ní Kákémíṣì lọ́dún 625 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ará Bábílónì tẹ̀ síwájú sí ìhà gúúsù ní Hámátì, níbi tí wọ́n tún ti ṣẹ́gun àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n sá padà sẹ́yìn. Lẹ́yìn náà ni àwọn ará Bábílónì gba etíkun kọjá sí Àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì, wọ́n sì pa ìlú Áṣíkẹ́lónì run bí wọ́n ti ń lọ. (2Ọb 24:7; Jer 47:5-7) Nígbà tí Bábílónì ń ja àwọn ogun wọ̀nyí, Júdà fi ara rẹ̀ sábẹ́ ìṣàkóso wọn.—2Ọb 24:1.

Lọ́dún 618 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọba Jèhóákímù ti Júdà ṣọ̀tẹ̀. Èyí mú kí Bábílónì rán àwọn ọmọ ogun tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè ìtòsí láti lọ bá Júdà jà, lẹ́yìn náà, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì wá sàga ti Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ṣẹ́pá rẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, Ọba Sedekáyà àti ìjọba rẹ̀ lọ lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Íjíbítì, èyí mú kí ìbínú àwọn ará Bábílónì túbọ̀ ru, wọ́n sì pinnu láti rẹ́yìn Júdà pátápátá. Bẹ́ẹ̀ làwọn ará Bábílónì tún gbógun wá lẹ́ẹ̀kan sí i tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ìlú Júdà run. (Jer 34:7) Níkẹyìn, Nebukadinésárì dojú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kọ Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.—2Kr 36:17-21; Jer 39:10.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ilẹ̀ Ọba Bábílónì/Ásíríà

Ilẹ̀ Ọba Ásíríà

B4 Mémúfísì (Nófì)

B4 Sóánì

B5 ÍJÍBÍTÌ

D2 KÍPÍRỌ́SÌ (KÍTÍMÙ)

D3 Sídónì

D3 Tírè

D3 Mẹ́gídò

D3 Samáríà

D4 Jerúsálẹ́mù

D4 Áṣíkẹ́lónì

D4 Lákíṣì

E2 Háránì

E2 Kákémíṣì

E2 Áápádì

E2 Hámátì

E3 Ríbúlà

E3 SÍRÍÀ

E3 Damásíkù

Ẹ2 Gósánì

Ẹ2 MESOPOTÁMÍÀ

F2 MÍNÌ

F2 ÁSÍRÍÀ

F2 Kọ́sábádì

F2 Nínéfè

F2 Kálà

F2 Áṣúrì

F3 BABILÓNÍÀ

F3 Bábílónì

F4 KÁLÍDÍÀ

F4 Érékì

F4 Úrì

G3 Ṣúṣánì

G4 ÉLÁMÙ

Ilẹ̀ Ọba Bábílónì

D3 Sídónì

D3 Tírè

D3 Mẹ́gídò

D3 Samáríà

D4 Jerúsálẹ́mù

D4 Áṣíkẹ́lónì

D4 Lákíṣì

E2 Háránì

E2 Kákémíṣì

E2 Áápádì

E2 Hámátì

E3 Ríbúlà

E3 SÍRÍÀ

E3 Damásíkù

E5 Témà

Ẹ2 Gósánì

Ẹ2 MESOPOTÁMÍÀ

Ẹ4 ARÉBÍÀ

F2 MÍNÌ

F2 ÁSÍRÍÀ

F2 Kọ́sábádì

F2 Nínéfè

F2 Kálà

F2 Áṣúrì

F3 BABILÓNÍÀ

F3 Bábílónì

F4 KÁLÍDÍÀ

F4 Érékì

F4 Úrì

G3 Ṣúṣánì

G4 ÉLÁMÙ

[Àwọn ìbòmíì]

G2 MÍDÍÀ

Ojú Ọ̀nà Pàtàkì (Wo inú ìtẹ̀jáde)

[Omi]

B3 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)

E5 Òkun Pupa

GB1 Òkun Kásípíà

GB5 Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà

[Odò]

B5 Náílì

GB1 Yúfírétì

F3 Tígírísì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Gegele Lákíṣì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àpẹẹrẹ ìlú Mẹ́gídò ayé ọjọ́un

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwòrán àwọn ọgbà alásorọ̀ ilẹ̀ Bábílónì