Àwọn Ilẹ̀ Tí Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Rẹ̀
NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Ọlọ́run, ó ní: “Jẹ́ kí ń ré kọjá, jọ̀wọ́, kí n sì rí ilẹ̀ dáradára tí ó wà ní òdì-kejì Jọ́dánì, ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá dáradára yìí.”—Di 3:25.
Kò ṣeé ṣe fún Mósè láti dé ibẹ̀, àmọ́ ó gun orí òkè ńlá kan tó dojú kọ ilẹ̀ Jẹ́ríkò, ó sì rí gbogbo ilẹ̀ náà—‘Gílíádì títí dé Dánì, àti ilẹ̀ Júdà títí dé òkun tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn, àti Négébù àti àfonífojì Jọ́dánì.’ (Di 3:27; 34:1-4) Ǹjẹ́ o ti gbọ́ àwọn orúkọ wọ̀nyẹn rí? Ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà?
Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní ló lè ṣèbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n ń kà nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. Wọn ò lè ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé kí Ábúráhámù ṣe, ìyẹn ni kí wọ́n rin gbogbo Ilẹ̀ Ìlérí náà já ní ìbú lóòró. (Jẹ 13:14-17) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń hára gàgà láti mọ ibi tí àwọn ilẹ̀ inú Bíbélì wà, àti bí wọ́n ṣe jẹ́ síra wọn.
Ìwé pẹlẹbẹ yìí, Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, jẹ́ ohun èlò tó o lè lò láti fi mú kí ìmọ̀ tó o ní nípa Ìwé Mímọ́ pọ̀ sí i. Ó ní fọ́tò àwọn ilẹ̀ tó wà ní tòótọ́ látijọ́, irú bí àgbègbè Gílíádì, èyí tí àwòrán rẹ̀ wà lẹ́yìn ìwé yìí. Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí pàápàá ń lani lóye, torí pé wọ́n á jẹ́ kí ìmọ̀ tó o ní nípa àwọn àgbègbè tí Bíbélì dárúkọ jinlẹ̀ sí i.
Àwòrán ilẹ̀ tó wà lójú ìwé 2 àti 3 ṣàfihàn àwọn ilẹ̀ tàbí àwọn àgbègbè pàtàkì-pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá wo ibi tí ilẹ̀ Ásíríà àti Íjíbítì wà, tó o sì rí bí wọ́n ṣe jìnnà sí Ilẹ̀ Ìlérí tó, wàá lè túbọ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn. (Ais 7:18; 27:13; Ho 11:11; Mik 7:12) Ilẹ̀ tó gùn àmọ́ tí kò fẹ̀ ni ibi tí à ń pè ní Ilẹ̀ Ìlérí. Ó wà ní àgbègbè kan tí àwọn ọ̀nà ńlá ti já síra nígbà àtijọ́, àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn sì máa ń fẹ́ láti gba àwọn oko ọkà, àwọn ọgbà àjàrà, àtàwọn oko ólífì ibẹ̀ tó ń so wọ̀ǹtìwọnti.—Di 8:8; Ond 15:5.
Ìgbà míì á wà tí wàá fẹ́ máa fi àwọn àwòrán ilẹ̀ náà wéra. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run rán Jónà níṣẹ́ lọ sí olú ìlú orílẹ̀-èdè Ásíríà, àmọ́ Táṣíṣì ló wọkọ̀ òkun lọ. (Jon 1:1-3) Ǹjẹ́ o rí àwọn àgbègbè wọ̀nyẹn nínú àwòrán ilẹ̀ àkọ́kọ́? Ṣùgbọ́n, má ṣi Táṣíṣì mú fún Tásù tí wọ́n ti bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù o. Wàá rí Tásù àtàwọn ìlú pàtàkì mìíràn nínú àwòrán ilẹ̀ tó ò ń wò yìí.
Ronú nípa bí ìrìn àjò Ábúráhámù ṣe gùn tó àti ojú ọ̀nà tó gbà bó o ṣe ń wo ibi tí àwọn ìlú bí Úrì, Háránì àti Jerúsálẹ́mù wà. Lẹ́yìn tí Jèhófà pè é láti Úrì, ó gbé Háránì, àtibẹ̀ ló sì ti ṣí lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Jẹ 11:28–12:1; Iṣe 7:2-5) Ó máa túbọ̀ rọrùn fún ọ láti fojú inú wo bí ìrìn àjò Ábúráhámù ṣe rí bó o bá ka àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbà Ayé Àwọn Baba Ńlá,” èyí tó wà ní ojú ìwé 6 àti 7.
Àwòrán ilẹ̀ àkọ́kọ́ àti èyí tó ò ń wò yìí kò dá lórí àkókò kan pàtó. Yàtọ̀ sí àwọn méjì yìí, gbogbo àwọn yòókù ló dá lórí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe wáyé tẹ̀ léra nínú ìtàn. Àwọn ìlú ńlá tàbí àwọn àlàyé tó wà nínú àwòrán ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan dá lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan pàtó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ibi tá a dárúkọ nínú àwọn àwòrán ilẹ̀ náà ló wà nínú Atọ́ka (èyí tó wà lójú ìwé 34 àti 35), ìsọfúnni ibẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí àwọn àwòrán ilẹ̀ tó bá kókó ọ̀rọ̀ tó ò ń ṣèwádìí lé lórí mu.
Àwòrán ilẹ̀ tó gba ojú ewé méjì tó wà láàárín ìwé yìí (ojú ìwé 18 àti 19) ló fi ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìlú kéékèèké àtàwọn ìlú ńlá tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí hàn. Ìsọfúnni Lórí Àwòrán Ilẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí àwọn ìlú ńlá tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì àtàwọn ìlú ààbò mẹ́fà náà, bákan náà ni yóò jẹ́ kó o mọ̀ bóyá inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni a ti dárúkọ ibì kan tàbí inú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ni, tàbí pé a dárúkọ rẹ̀ nínú apá méjèèjì.
Joṣ, orí 15 sí 19) Síbẹ̀, àwòrán ilẹ̀ náà máa ń fi àwọn ìlú tó wà nítòsí ibì kan pàtó hàn, nípa bẹ́ẹ̀ yóò lè ṣeé ṣe fún ọ láti fojú inú wo bí wọ́n ṣe jìnnà síra wọn tó. A sàmì sí àwọn nǹkan pàtàkì téèyàn lè fi dá àwọn àgbègbè kan mọ̀ (irú bí òkè ńlá, odò àti àfonífojì olójú ọ̀gbàrá), a sì fi oríṣiríṣi àwọ̀ sàmì sí àwọn òkè gíga àtàwọn ibi tó jẹ́ ilẹ̀. Irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fojú inú wo bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì ṣe wáyé.
Àwọn olùṣèwádìí ò tíì mọ ibi tí àwọn ilẹ̀ kan tí Bíbélì dárúkọ wà, nípa bẹ́ẹ̀ a kò fi orúkọ irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ sínú àwòrán ilẹ̀ tó wà láàárín ìwé yìí. Bákan náà, kò ṣeé ṣe láti ṣàfihàn gbogbo ìlú ńlá àti ìlú kéékèèké, irú bí gbogbo àwọn ìlú tó wà nínú àkọsílẹ̀ nípa àwọn ààlà ìpínlẹ̀ láàárín ẹ̀yà kan sí òmíràn. (Ìsọfúnni síwájú sí i nípa àwọn ilẹ̀ tó wà nínú Bíbélì wà nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, tó wà ní ọ̀pọ̀ èdè. a Bó o bá ń lo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yìí àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó ń ṣàlàyé Bíbélì, jẹ́ kí ìwé pẹlẹbẹ yìí Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà máa wà nítòsí rẹ. Máa lò ó bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ gbogbo Ìwé Mímọ́, tó ṣàǹfààní gan-an nínú ìgbésí ayé rẹ.—2Ti 3:16, 17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Ti Kọ Bíbélì àti Àwọn Ìlú Pàtàkì Ibẹ̀
A1 ÍTÁLÌ
A2 RÓÒMÙ
A3 SÍSÍLÌ
A3 MÁLÍTÀ
D2 MAKEDÓNÍÀ
D2 Fílípì
D2 GÍRÍÌSÌ
D3 ÁTÉNÌ
D3 Kọ́ríńtì
D3 KÍRÉTÈ
D4 LÍBÍÀ
E3 Áńtíókù (ti Písídíà)
E3 Éfésù
E3 PÁTÍMỌ́SÌ
E3 RÓDÉSÌ
E4 MÉMÚFÍSÌ
E5 ÍJÍBÍTÌ
Ẹ2 ÉṢÍÀ KÉKERÉ
Ẹ3 Tásù
Ẹ3 Áńtíókù (ti Síríà)
Ẹ3 KÍPÍRỌ́SÌ
Ẹ4 Sídónì
Ẹ4 Damásíkù
Ẹ4 Tírè
Ẹ4 Kesaréà
Ẹ4 ILẸ̀ ÌLÉRÍ
Ẹ4 JERÚSÁLẸ́MÙ
Ẹ4 MÓÁBÙ
Ẹ4 Kádéṣì
Ẹ4 ÉDÓMÙ
F3 Ọgbà Édẹ́nì?
F3 ÁSÍRÍÀ
F3 Háránì
F3 SÍRÍÀ
F5 ARÉBÍÀ
G3 NÍNÉFÈ
G4 BÁBÍLÓNÌ
G4 KÁLÍDÍÀ
G4 Ṣúṣánì
G4 Úrì
GB3 MÍDÍÀ
[Àwọn Òkè]
Ẹ5 Òkè Sínáì
G2 ÒKÈ ÁRÁRÁTÌ
[Omi]
D3 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
Ẹ1 Òkun Dúdú
Ẹ5 Òkun Pupa
GB2 Òkun Kásípíà
GB5 Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà
[Odò]
E5 Odò Náílì
F3 Odò Yúfírétì
G3 Odò Tígírísì