Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Dé Àwọn Orílẹ̀-èdè Mìíràn
ORÍ Òkè Ólífì lẹ́bàá Bẹ́tánì ni Jésù ti gbé iṣẹ́ ìwàásù kan tí yóò yí ayé padà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Iṣẹ́ ìwàásù náà á bẹ̀rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta síhà ìwọ̀ oòrùn Òkè Ólífì. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á mú ọ̀rọ̀ ìhìn rere náà dé Jùdíà àti Samáríà nítòsí, lẹ́yìn náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yóò dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Iṣe 1:4, 8, 12.
Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì mú kí àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù láti àwọn àgbègbè tí a fi hàn lórí àwòrán tó wà nísàlẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ìwàásù tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe fún wọn lọ́jọ́ yẹn mú kí ó tètè ṣeé ṣe fún ẹ̀sìn Kristẹni láti gbilẹ̀ kíákíá.—Iṣe 2:9-11.
Kò pẹ́ púpọ̀ tí inúnibíni fi tú àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ká ní Jerúsálẹ́mù. Pétérù àti Jòhánù wà lára àwọn tó ran àwọn ará Samáríà lọ́wọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìn rere kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á. (Iṣe 8:1, 4, 14-16) Lẹ́yìn tí Fílípì jẹ́rìí fún ará Etiópíà kan lójú ọ̀nà aṣálẹ̀ tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ “láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Gásà,” ẹ̀sìn Kristẹni gbilẹ̀ dé Áfíríkà. (Iṣe 8:26-39) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àkókò yìí ni ìhìn rere náà tún sèso ní Lídà, tó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì, àti ní èbúté ti Jópà. (Iṣe 9:35, 42) Láti ibẹ̀, Pétérù kọjá lọ sí Kesaréà ó sì ran Kọ̀nílíù, ọ̀gá ọmọ ogun Róòmù, àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí a fẹ̀mí yàn.—Iṣe 10:1-48.
Pọ́ọ̀lù, tó ti ń fìgbà kan rí ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni, di àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ó rìnrìn àjò lórí ilẹ̀ àti lórí òkun nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti ìrìn àjò tó rìn lójú òkun lọ sí Róòmù. Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn mìíràn tan ìhìn Wo ojú ìwé 2.) Pétérù sì rìn jìnnà dé ìyànníyàn Bábílónì níhà ìlà oòrùn. (1Pe 5:13) Lóòótọ́, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀ dé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lábẹ́ ìdarí tó múná dóko látọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Nígbà tó fi máa di ọdún 60 sí 61 Sànmánì Tiwa, ‘a ti wàásù ìhìn rere náà nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’ (Kol 1:6, 23) Láti ìgbà náà wá, ìhìn rere ti tipa báyìí dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”
rere náà kálẹ̀ dé àwọn apá ibi tó pọ̀ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Pọ́ọ̀lù ní in lọ́kàn láti dé Sípéènì. ([Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 32]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bí Ẹ̀sìn Kristẹni Ṣe Gbilẹ̀
Àwọn Ibi Tí A Ti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìn Rere Náà
B1 ÍLÍRÍKÓNÌ
B1 ÍTÁLÌ
B1 Róòmù
D1 MAKEDÓNÍÀ
D2 GÍRÍÌSÌ
D2 Áténì
D2 KÍRÉTÈ
D3 Kírénè
D3 LÍBÍÀ
E1 BÍTÍNÍÀ
E2 GÁLÁTÍÀ
E2 ÉṢÍÀ
E2 FÍRÍJÍÀ
E2 PANFÍLÍÀ
E2 KÍPÍRỌ́SÌ
E3 ÍJÍBÍTÌ
E4 ETIÓPÍÀ
Ẹ1 PỌ́ŃTÙ
Ẹ2 KAPADÓKÍÀ
Ẹ2 SÌLÍṢÍÀ
Ẹ2 MESOPOTÁMÍÀ
Ẹ2 SÍRÍÀ
Ẹ3 SAMÁRÍÀ
Ẹ3 Jerúsálẹ́mù
Ẹ3 JÙDÍÀ
F2 MÍDÍÀ
F3 Bábílónì
F3 ÉLÁMÙ
F4 ÁRÉBÍÀ
G2 PÁTÍÀ
[Omi]
D2 Òkun Mẹditaréníà
E1 Òkun Dúdú
Ẹ4 Òkun Pupa
F3 Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 32, 33]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìrìn Àjò Pọ́ọ̀lù
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Àkọ́kọ́ (Iṣe 13:1-14:28)
GB3 Áńtíókù (ti Síríà)
GB3 Séléúkíà
G4 KÍPÍRỌ́SÌ
G3 Sálámísì
G4 Páfósì
G3 PANFÍLÍÀ
F3 Pẹ́gà
F3 PÍSÍDÍÀ
F2 Áńtíókù (ti Písídíà)
G2 Íkóníónì
G2 LIKAÓNÍÀ
G2 Lísírà
G3 Déébè
G2 Lísírà
G2 Íkóníónì
F2 Áńtíókù (ti Písídíà)
F3 PÍSÍDÍÀ
G3 PANFÍLÍÀ
F3 Pẹ́gà
F3 Atalíà
GB3 Áńtíókù (ti Síríà)
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Ẹlẹ́ẹ̀kejì (Iṣe 15:36–18:22)
GB3 Áńtíókù (ti Síríà)
GB3 SÍRÍÀ
GB3 SÌLÍṢÍÀ
GB3 Tásù
G3 Déébè
G2 Lísírà
G2 Íkóníónì
F2 Áńtíókù (ti Písídíà)
F2 FÍRÍJÍÀ
G2 GÁLÁTÍÀ
Ẹ2 MÁÍSÍÀ
Ẹ2 Tíróásì
Ẹ1 SÁMÓTÍRÁSÌ
E1 Neapólísì
E1 Fílípì
D1 MAKEDÓNÍÀ
E1 Áńfípólì
E1 Tẹsalóníkà
E1 Bèróà
D2 GÍRÍÌSÌ
E2 Áténì
E2 Kọ́ríńtì
E3 ÁKÁYÀ
Ẹ2 Éfésù
G4 Kesaréà
GB5 Jerúsálẹ́mù
GB3 Áńtíókù (ti Síríà)
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Ẹlẹ́ẹ̀kẹta (Iṣe 18:22–21:19)
GB3 SÍRÍÀ
GB3 Áńtíókù (ti Síríà)
G2 GÁLÁTÍÀ
F2 FÍRÍJÍÀ
GB3 SÌLÍṢÍÀ
GB3 Tásù
G3 Déébè
G2 Lísírà
G2 Íkóníónì
F2 Áńtíókù (ti Písídíà)
Ẹ2 Éfésù
Ẹ2 ÉṢÍÀ
Ẹ2 Tíróásì
E1 Fílípì
D1 MAKEDÓNÍÀ
E1 Áńfípólì
E1 Tẹsalóníkà
E1 Bèróà
D2 GÍRÍÌSÌ
E2 Áténì
E2 Kọ́ríńtì
E1 Bèróà
E1 Tẹsalóníkà
E1 Áńfípólì
E1 Fílípì
Ẹ2 Tíróásì
Ẹ2 Ásósì
Ẹ2 Mítílénè
Ẹ2 KÍÓSÌ
Ẹ2 SÁMÓSÌ
Ẹ3 Mílétù
Ẹ3 Kọ́sì
Ẹ3 RÓDÉSÌ
F3 Pátárà
GB4 Tírè
GB4 Tólémáísì
G4 Kesaréà
GB5 Jerúsálẹ́mù
Ìrìn Àjò sí Róòmù (Iṣe 23:11–28:31)
GB5 Jerúsálẹ́mù
G4 Kesaréà
GB4 Sídónì
F3 Máírà
F3 LÍKÍÀ
Ẹ3 Kínídọ́sì
E3 KÍRÉTÈ
E4 KÁÚDÀ
A3 MÁLÍTÀ
A3 SÍSÍLÌ
A3 Sírákúsì
A1 ÍTÁLÌ
B2 Régíómù
A1 Pútéólì
A1 Róòmù
Ojú Ọ̀nà Ẹlẹ́sẹ̀ (Wo inú ìtẹ̀jáde)
[Ìjọ méje]
Ẹ2 Págámù
Ẹ2 Tíátírà
Ẹ2 Sádísì
Ẹ2 Símínà
Ẹ2 Éfésù
F2 Filadẹ́fíà
F2 Laodíkíà
[Àwọn ìbòmíì]
Ẹ3 PÁTÍMỌ́SÌ
F2 Kólósè
F5 Alẹkisáńdíríà
F5 ÍJÍBÍTÌ
G1 BÍTÍNÍÀ
G5 Jópà
G5 Lídà
G5 Gásà
GB1 PỌ́ŃTÙ
GB2 KAPADÓKÍÀ
GB4 Damásíkù
GB4 Pẹ́là
[Omi]
Òkun Mẹditaréníà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 33]
Gbọ̀ngàn ìwòran ní Mílétù, ìlú tí Pọ́ọ̀lù ti pàdé àwọn alàgbà tó wá láti Éfésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 33]
Pẹpẹ Súúsì ní Págámù. Àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú yìí gbé “ni ibi tí ìtẹ́ Sátánì wà”—Iṣi 2:13