Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ísírẹ́lì Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Yí i Ká

Ísírẹ́lì Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Yí i Ká

Ísírẹ́lì Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Yí i Ká

JÈHÓFÀ sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Lọ kúrò ní Úrì ní Mesopotámíà sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’ Lákòókò yìí àwọn orílẹ̀-èdè kan ló ń gbé lórí ilẹ̀ yẹn tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn sì tún wà yí i ká.—Jẹ 12:1-3; 15:17-21.

Nígbà tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń ṣí lọ kúrò ní Íjíbítì, wọ́n mọ̀ pé àwọn lè dojú kọ àtakò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá, bí “àwọn abàṣẹwàá Móábù.” (Ẹk 15:14, 15) Àwọn Ámálékì, àwọn ọmọ Móábù, àwọn Ámónì àti àwọn Ámórì ló ń gbé ní àgbègbè ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbà kọjá lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Nu 21:11-13; Di 2:17-33; 23:3, 4) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á sì tún bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá pàdé ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun yóò fún wọn.

Ọlọ́run sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa “mú àwọn orílẹ̀-èdè” méje tó jẹ́ “elénìyàn púpọ̀ kúrò.” Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì tí ìparun tọ́ sí. Ìwà ìbàjẹ́ tó burú jáì làwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ń hù, ìwàkiwà sì kún inú ẹ̀sìn wọn. Lára àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń jọ́sìn ni Báálì (tó sábà máà ń ní ìrísí ọwọ̀n òkúta tí a gbẹ́ bíi ti ẹ̀yà ìbímọ), Mólékì (ère tí wọ́n ń fi ọmọ rúbọ sí) àti Áṣítórétì (Ásítátè) tí í ṣe abo ọlọ́run ìbímọlémọ.—Di 7:1-4; 12:31; Ẹk 23:23; Le 18:21-25; 20:2-5; Ond 2:11-14; Sm 106:37, 38.

Nígbà mìíràn Bíbélì pe gbogbo àgbègbè tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “Kénáánì,” ìyẹn láti àríwá Sídónì títí lọ dé “àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì.” (Nu 13:2, 21; 34:2-12; Jẹ 10:19) Ní àwọn ìgbà mìíràn, Bíbélì á lo orúkọ onírúurú orílẹ̀-èdè, ìpínlẹ̀ adàjọbaṣe tàbí àwọn ènìyàn tó wà ní ilẹ̀ náà. Dáńfó gedegbe làwọn orílẹ̀-èdè kan wà, àwọn bíi Filísínì tí wọ́n wà ní etíkun àti àwọn ará Jébúsì tí wọ́n wà ní ibi àwọn òkè ńlá lẹ́bàá Jerúsálẹ́mù. (Nu 13:29; Joṣ 13:3) Bí àkókò ti ń lọ ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wà tàbí ààlà ìpínlẹ̀ wọn yí padà.—Jẹ 34:1, 2; 49:30; Joṣ 1:4; 11:3; Ond 1:16, 23-26.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Ámórì ni ẹ̀yà tó lágbára jù lọ. a (Di 1:19-21; Joṣ 24:15) Àwọn ló gba ilẹ̀ Móábù títí lọ dé ibi àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé “aṣálẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù” ní wọ́n ṣì ń pe àgbègbè tó wà ní òdì kejì Jẹ́ríkò. Àwọn ọba Ámórì yìí ló ń ṣàkóso Báṣánì àti Gílíádì.—Nu 21:21-23, 33-35; 22:1; 33:46-51.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbágbáágbá ni Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn ò mú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run dẹ́bi fún kúrò pátápátá, àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀hún ló sì wá di ìdẹkùn fún wọn nígbà tó yá. (Nu 33:55; Joṣ 23:13; Ond 2:3; 3:5, 6; 2Ọb 21:11) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàpà kó sínú ìjàngbọ̀n bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, èyíkéyìí nínú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní gbogbo àyíká yín.”—Di 6:14; 13:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó ti rí ní ti orúkọ náà “àwọn ọmọ Kénáánì,” ó lè jẹ́ pé orúkọ tó kó gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Ámórì pọ̀ ni orúkọ náà, “àwọn Ámórì,” ó sì lè jẹ́ ẹ̀yà kan pàtó ló ń tọ́ka sí.—Jẹ 15:16; 48:22.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 11]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Orílẹ̀-èdè Tí a Óò Lé Kúrò Ní Ilẹ̀ Ìlérí

FILÍSÍÀ (E8)

D8 Áṣíkẹ́lónì

D9 Gásà

E8 Áṣídódì

E8 Gátì

E9 Gérárì

KÉNÁÁNÌ (E8)

B10 ÀWỌN ÁMÁLÉKÌ

D12 Hasari-ádáárì (Ádáárì?)

D12 Kádéṣì (Kadeṣi-báníà)

E8 Lákíṣì

E9 Bíá-ṣébà

E10 ÀWỌN ÁMÓRÌ

E11 NÉGÉBÙ

Ẹ4 Dórì

Ẹ5 Mẹ́gídò

Ẹ5 Táánákì

Ẹ6 Áfékì

Ẹ6 ÀWỌN HÍFÌ

Ẹ7 ÀWỌN JÉBÚSÌ

Ẹ8 Bẹti-ṣémẹ́ṣì

Ẹ8 Hébúrónì (Kiriati-ábà)

Ẹ9 ÀWỌN ỌMỌ HÉTÌ

Ẹ9 Débírì

Ẹ10 Árádì (Ọmọ Kénáánì)

Ẹ10 ÀWỌN KÉNÌ

Ẹ11 Ákírábímù

F4 ÀWỌN GẸ́GÁṢÌ

F6 Ṣékémù

F7 ÀWỌN PÉRÍSÌ

F7 Gílígálì

F7 Jẹ́ríkò

F8 Jerúsálẹ́mù

G2 ÀWỌN HÍFÌ

G2 Dánì (Láíṣì)

G3 Hásórì

FÒNÍṢÍÀ (F2)

Ẹ2 Tírè

F1 Sídónì

ÉDÓMÙ (F12)

F11 SÉÍRÌ

G11 Bósírà

ÀWỌN ÁMÓRÌ (SÍHÓNÌ) (G8)

G6 GÍLÍÁDÌ

G7 Ṣítímù

G7 Héṣíbónì

G9 Áróérì

SÍRÍÀ (GB1)

G2 Baali-gádì

G2 ÀWỌN HÍFÌ

I1 Damásíkù

MÓÁBÙ (GB10)

ÀWỌN ÁMÓRÌ (ÓGÙ) (I5)

G6 GÍLÍÁDÌ

GB3 BÁṢÁNÌ

GB4 Áṣítárótì

GB4 Édíréì

ÁMÓNÌ (I7)

GB7 Rábà

[Aṣálẹ̀]

GB12 AṢÁLẸ̀ ARÉBÍÀ

[Àwọn Òkè]

Ẹ4 Òkè Kámẹ́lì

Ẹ11 Òkè Hóórì

G1 Òkè Hámónì

G8 Òkè Nébò

[Omi]

D6 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)

F9 Òkun Iyọ̀

G4 Òkun Gálílì

[Àwọn Odò]

B11 A.O. Íjíbítì

F6 Odò Jọ́dánì

G6 A.O. Jábókù

G9 A.O. Áánónì

G11 A.O. Séréédì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀tún: Ógù ọba àwọn Ámórì ṣàkóso ní Báṣánì, àwọn èèyàn mọ ilẹ̀ yìí dáadáa gẹ́gẹ́ bí ibi tí àwọn akọ màlúù àti àgùntàn pọ̀ sí

Ìsàlẹ̀: Aginjù Júdà wà ní òdì kejì Móábù, Òkun Iyọ̀ sì là wọ́n láàárín

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú àwọn orílẹ̀-èdè tí ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké bíi Báálì, Mólékì, àti Áṣítórétì, abo ọlọ́run ìbímọlémọ (tó wà nínú àwòrán yìí) kúrò