Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì àti Ti Róòmù Nípa Lórí Àwọn Júù
Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì àti Ti Róòmù Nípa Lórí Àwọn Júù
IBI tí a mọ̀ sí Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì bẹ̀rẹ̀ sí í gbòòrò láti ibi àwọn òkè ńlá Makedóníà. Níbi àwọn òkè ńlá yìí ni Alẹkisáńdà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lẹ́ni ogún ọdún ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà àtiṣẹ́gun àwọn ìlú tó wà ní apá ìlà oòrùn. Lọ́dún 334 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí Hẹ́lísípọ́ńtì (Dadinẹ́sì), níbi ààlà ilẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà. Bí “àmọ̀tẹ́kùn” tí ń bẹ́ gìjà-gìjà, làwọn Gíríìkì tí ń jagun fún Alẹkisáńdà yìí ṣe ń jà lọ ràì tí wọ́n sì ń ṣẹ́gun. (Da 7:6) Alẹkisáńdà borí àwọn ará Páṣíà nítòsí Tírọ́ì tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ibi Odò Gíráníkọ́sì, Alẹkisáńdà sì ṣẹ́gun wọn ní ìlú Ísọ́sì.
Àwọn Gíríìkì kógun wọ Síríà àti Fòníṣíà, wọ́n sì ṣẹ́gun ìlú Tírè lẹ́yìn tí wọ́n ti dó tì í fún oṣù méje. (Isk 26:4, 12) Alẹkisáńdà dá Jerúsálẹ́mù sí, ṣùgbọ́n ó ṣẹ́gun Gásà. (Sek 9:5) Gbàrà tó dé Íjíbítì, ló tẹ ìlú Alẹkisáńdíríà tó wá di ojúkò káràkátà àti ẹ̀kọ́ ìwé dó. Nígbà tí Alẹkisáńdà tún padà gba Ilẹ̀ Ìlérí kọjá, ó tún ṣẹ́gun àwọn ará Páṣíà, ní Gọgamílà, tó wà nítòsí àwókù Nínéfè.
Alẹkisáńdà dorí kọ gúúsù láti ṣẹ́gun àwọn ibùdó àkóso Páṣíà tó wà ní Bábílónì, Ṣúṣánì (Súsà) àti Pasẹpólísì. Lẹ́yìn náà ló yára la gbogbo ilẹ̀ abẹ́ àkóso Páṣíà kọjá, títí lọ dé ibi Odò Íńdọ́sì tó wà ní ilẹ̀ Pakísítánì òde òní. Láàárín ọdún mẹ́jọ péré, Alẹkisáńdà ti ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè tó pọ̀ jù lọ lára gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé nígbà yẹn. Ṣùgbọ́n ní ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tó ti di ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, Da 8:8.
àrùn ibà lù ú pa ní Bábílónì.—Ọwọ́ àwọn Hélénì [ará Gíríìsì] ranlẹ̀ dáadáa ní Ilẹ̀ Ìlérí. Àwọn kan tó ti wà lára àwọn ọmọ ogun Alẹkisáńdà rí ń gbé ní àgbègbè náà. Nígbà tó sì fi máa di ọ̀rúndún kìíní, àwùjọ àwọn tí ń sọ èdè Gíríìkì ti tẹ ìlú (Dekapólì) dó. (Mt 4:25; Mk 7:31) Bẹ́ẹ̀ ló di pé Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù wà ní èdè Gíríìkì. Kóínè (èdè Gíríìkì ti tẹrú tọmọ ń sọ) ni wọ́n sì fi tan ẹ̀kọ́ Kristẹni kálẹ̀ nílé lóko.
Ilẹ̀ Ọba Róòmù
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn? Ìlú Róòmù—tí kò ju àpapọ̀ àwọn abúlé kóó-kòò-kó kan létí Odò Táíbà lọ tẹ́lẹ̀—wá di àjànàkú tí ń migbó kìjikìji. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí kì í bà á tì àti ìjọba àjùmọ̀ṣe tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ń lò mú kó ṣeé ṣe fún un láti gba gbogbo àgbègbè tó wà lábẹ́ àkóso àwọn ọ̀gágun Alẹkisáńdà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti di àràbà tápá ò lè ká mọ́, ìyẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà tó kọ́kọ́ gbà fara hàn gẹ́gẹ́ bí ‘ẹranko tí ń bani lẹ́rù’ tí Dáníẹ́lì rí nínú ìran.—Da 7:7.
Ilẹ́ Ọba Róòmù gbilẹ̀ láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì títí lọ dé Àríwá Áfíríkà, ó sì gbilẹ̀ láti Òkun Àtìláńtíìkì tó fi dé Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà. Nítorí pé ilẹ̀ ọba náà yí òkun Mẹditaréníà ká, Òkun Wa (Mare Nostrum) làwọn ará Róòmù ń pè é.
Abẹ́ àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni àwọn Júù wà, nítorí náà, Ilẹ̀ Ọba Róòmù nípa lórí wọn. (Mt 8:5-13; Iṣe 10:1, 2) Ìrìbọmi Jésù àti ikú rẹ̀ wáyé nígbà ìṣàkóso Olú Ọba Tìbéríù. Àwọn alákòóso ìlú Róòmù kan ṣenúnibíni lọ́nà rírorò sí àwọn Kristẹni ṣùgbọ́n wọn ò lè pa ìsìn tòótọ́ run. Lẹ́yìn ọ̀rúndún mẹ́tàlá, ẹ̀ya àwọn ará Jámánì ní àríwá àti àwọn akóguntini tí ń ṣí kirí ní ìlà oòrùn, tẹ ilẹ̀ ọba náà lórí ba.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 26]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì
Lẹ́yìn ikú Alẹkisáńdà, mẹ́rin lára àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ọba gbígbòòro náà
▪ Kasáńdà
▫ Lisimákù
○ Tólẹ́mì Kìíní
• Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní
A2 ▪ GÍRÍÌSÌ
A2 ▪ Áténì
A2 ▪ ÁKÁYÀ
A3 ○ Kírénè
A3 ○ LÍBÍÀ
B2 ▫ Bìsáńṣíọ̀mù
B3 ○ KÍPÍRỌ́SÌ
B4 ○ No-ámónì (Tíbésì)
D3 Pálímírà (Tádímórì)
D3 ○ Gérásà
D3 ○ Filadẹ́fíà
D3 ○ Jerúsálẹ́mù
D5 ○ Síénè
G2 • Alẹkisáńdíríà Magiánà
Ojú Ọ̀nà Alẹkisáńdà
A2 ▪ MAKEDÓNÍÀ
A2 ▪ Pẹ́là
A2 ▫ TÍRÉSÌ
B2 ▫ Tírọ́ì
B2 ▫ Sádísì
B2 ▫ Éfésù
B2 ▫ Gọ́díọ̀mù
D2 ▫ Áńkarà
D3 • Tásù
D3 • Ísọ́sì
D3 • Áńtíókù (ti Síríà)
D3 ○ Tírè
D4 ○ Gásà
B4 ○ ÍJÍBÍTÌ
B4 ○ Mémúfísì
B4 ○ Alẹkisáńdíríà
B4 ○ Omi Aṣálẹ̀ Síwà
B4 ○ Mémúfísì
D4 ○ Gásà
D3 ○ Tírè
D3 ○ Damásíkù
D3 • Alépò
E3 • Nísíbísì
E3 • Gọgamílà
E3 • Bábílónì
E3 • Ṣúṣánì
Ẹ4 • PÁṢÍÀ
Ẹ4 • Pasẹpólísì
Ẹ4 • Paságedì
Ẹ3 • MÍDÍÀ
Ẹ3 • Ekibátánà
Ẹ3 • Rééjì
Ẹ3 • Hẹkatómífílọ́sì
Ẹ3 • PÁTÍÀ
G3 • ÁRÍÀ
G3 • Alẹkisáńdíríà ti Áríà
G3 • Alẹkisáńdíríà Purọfitásíà
F4 • DIRANGÍÁNÀ
G4 • ARAKÓṢÍÀ
G4 • Alẹkisáńdíríà ti Arakoṣíórọ̀mù
GB3 • Kábúlù
G3 • Dirapúsákà
GB3 • Alẹkisáńdíríà Tibi Odò Ókísọ̀
G3 • Dirapúsákà
G3 • BÁKÍTÍRÍÀ
G3 • Bákítírà
G2 • Dábẹ́ńtì
G2 • SOGIDÍÁNÀ
G2 • Marakáńdà
G2 • Bùkárà
G2 • Marakáńdà
GB2 • Alẹkisáńdíríà Ẹ́síkátè
G2 • Marakáńdà
G2 • Dábẹ́ńtì
G3 • Bákítírà
G3 • BÁKÍTÍRÍÀ
G3 • Dirapúsákà
GB3 • Kábúlù
GB3 • Tásílà
GB5 • ÍŃDÍÀ
GB4 • Alẹkisáńdíríà
G4 • GEDIRÓSÍÀ
F4 • Púrà
Ẹ4 • PÁṢÍÀ
F4 • Alẹkisáńdíríà
F4 • KARIMÁNÍÀ
Ẹ4 • Paságedì
Ẹ4 • Pasẹpólísì
Ẹ3 • Ṣúṣánì
E3 • Bábílónì
[Àwọn ìbòmíì]
A3 KÍRÉTÈ
E4 ARÉBÍÀ
[Omi]
B3 Òkun Mẹditaréníà
D5 Òkun Pupa
Ẹ4 Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà
G5 Òkun Arébíà
[Odò]
B4 Náílì
E3 Yúfírétì
E3 Tígírísì
G4 Íńdọ́sì
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 27]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Ọba Róòmù
A1 ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ
A3 SÍPÉÈNÌ
B1 JÀMÁNÍÀ
B2 GỌ́Ọ̀LÙ
B2 ÍTÁLÌ
B2 Róòmù
B3 Kátéèjì
D2 ÍLÍRÍKÓNÌ
D3 GÍRÍÌSÌ
D3 Ákíṣíọ́mù
D3 Kírénè
E2 Bìsáńṣíọ̀mù (Kọnsitantinópù)
E3 ÉṢÍÀ KÉKERÉ
E3 Éfésù
E3 Alépò
E3 Áńtíókù (ti Síríà)
E3 Damásíkù
E3 Gérásà (Járáṣì)
E3 Jerúsálẹ́mù
E3 Alẹkisáńdíríà
E4 ÍJÍBÍTÌ
[Omi]
A2 Òkun Àtìláńtíìkì
D3 Òkun Mẹditaréníà
E2 Òkun Dúdú
E4 Òkun Pupa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nígbà tí Tólẹ́mì Kejì tún ìlú Rábà kọ́ tán, ó sọ ọ́ ní Filadẹ́fíà. Àwókù gbọ̀ngàn ìṣeré ńlá kan ní ìlú Róòmù rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìlú Gérásà (Járáṣì) ní Dekapólì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn ojú ọ̀nà tí ilẹ̀ ọba Róòmù ṣe, bí irú èyí nítòsí Alépò, gbòòrò títí lọ dé Yúróòpù, Àríwá Áfíríkà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Àwọn Kristẹni rìnrìn àjò gba ọ̀nà yìì kọjá láti tan òtítọ́ Bíbélì kálẹ̀