Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ilẹ̀ Kan Tí Ó Dára Tí ó Sì Ní Àyè Gbígbòòrò”

“Ilẹ̀ Kan Tí Ó Dára Tí ó Sì Ní Àyè Gbígbòòrò”

IBI igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún kan tí ń jó ni Mósè wà nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé òun á “dá [àwọn ènìyàn òun] nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, [òun á] sì mú wọn gòkè wá . . . sí ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.”—Ẹk 3:8.

Àwọn àwòrán méjì tí a fi kọ̀ǹpútà yà yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye bí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ojú ilẹ̀ àti àgbègbè Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí. (A túbọ̀ mú kí àwòrán ojú ilẹ̀ yìí hàn ketekete kí ìdíwọ̀n tá a lò lè tóbi.) Wo àtẹ ìsọfúnni tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ kó o lè mọ bí ojú ilẹ̀ ṣe ga sí ní ìfiwéra pẹ̀lú ìtẹ́jú òkun.

Àtẹ ìsọfúnni ṣàlàyé ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àgbègbè tó yí ilẹ̀ náà ká. Àlàyé nípa àwọn àgbègbè náà àti ibi tí a ti tọ́ka sí wọn nínú Bíbélì wà nínú ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial” (Ẹ̀kọ́ 1, ojú ìwé 270 sí 278) àti nínú ìwé Insight on the Scriptures (Apá Kejì, ojú ìwé 568 sí 571). a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Bí Ojú Ilẹ̀ Náà Ṣe Rí

Àtẹ Ìsọfúnni Nípa Àwọn Àgbègbè Ilẹ̀ Ìlérí

A. Etí Òkun Ńlá

B. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Jọ́dánì

1. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áṣérì

2. Ilẹ̀ Etíkun Dórì

3. Pápá Ìjẹko Ṣárónì

4. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Filísíà

5. Àfonífojì Tó Bẹ̀rẹ̀ Láti Ìlà Oòrùn Lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn

a. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò

b. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Jésíréélì

D. Àwọn Òkè Tó Wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Jọ́dánì

1. Òkè Gálílì

2. Òkè Kámẹ́lì

3. Òkè Samáríà

4. Ṣẹ́fẹ́là (òkè kékeré)

5. Ilẹ̀ Olókè ti Júdà

6. Aginjù Júdà

7. Négébù

8. Aginjù Páránì

E. Árábà (Àfonífojì Ńlá)

1. Adágún Omi Húlà

2. Àgbègbè Òkun Gálílì

3. Àfonífojì Jọ́dánì

4. Òkun Iyọ̀ (Òkun Òkú)

5. Árábà (gúúsù Òkun Iyọ̀)

Ẹ. Àwọn Òkè àti Ilẹ̀ Títẹ́jú ní Ìlà Oòrùn Jọ́dánì

1. Báṣánì

2. Gílíádì

3. Ámónì àti Móábù

4. Òkè Olórí Pẹrẹsẹ ti Édómù

F. Àwọn Òkè Lẹ́bánónì

[Àwòrán ilẹ̀]

Òkè Hámónì

Dánì

Jerúsálẹ́mù

Bíá-ṣébà

Àwòrán Ilẹ̀ Ìlérí tí A Bá Gé E Láàárín Méjì

mítà ẹsẹ̀ bàtà

2,500 7,500

2,000 6,000

1,500 4,500

1,000 3,000

500 1,500

0 0 (Ìtẹ́jú Òkun)

-500 -1,500

Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Filísíà

Ṣẹ́fẹ́là

Ilẹ̀ Olókè ti Júdà

Aginjù Júdà

Àfonífojì Ńlá

Òkun Iyọ̀

Ilẹ̀ Móábù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Òkè Hámónì (2,814 mítà; 9,232 ẹsẹ̀ bàtà)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Etí Òkun Iyọ̀; ibi tó relẹ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé (nǹkan bí 400 mítà; ó fi 1,300 ẹsẹ̀ bàtà wà ní ìsàlẹ̀ ìtẹ́jú òkun)