Jésù “Ní Ilẹ̀ Àwọn Júù”
Jésù “Ní Ilẹ̀ Àwọn Júù”
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pétérù ń wàásù fún Kọ̀nílíù, ó sọ fún un nípa ohun tí Jésù ṣe “ní ilẹ̀ àwọn Júù àti ní Jerúsálẹ́mù.” (Iṣe 10:39) Àwọn apá ibo gan-an ni Jésù ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mánigbàgbé tó ṣe?
Jùdíà, níbi tí Jésù ti ṣe díẹ̀ lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an wà lára “ilẹ̀ àwọn Júù.” (Lk 4:44) Lẹ́yìn tí Jòhánù ri Jésù bọmi, Jésù lo ogójì ọjọ́ nínú aginjù Júdà (tàbí Jùdíà), ìyẹn àgbègbè kan báyìí tó gbẹ táútáú tí kò lólùgbé, tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti ìgárá ọlọ́ṣà kì í sì í wọ́n níbẹ̀. (Lk 10:30) Nígbà kan, tí Jésù ń ti Jùdíà lọ sí ìhà àríwá, ó jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà kan lẹ́bàá ìlú Síkárì.—Jo 4:3-7.
Àyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé Gálílì ni Jésù ti ṣe iṣẹ́ ìwàásù jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń lọ síhà gúúsù ní Jerúsálẹ́mù fún àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún, ìhà àríwá Ilẹ̀ Ìlérí ló ti lo apá tó pọ̀ jù lọ nínú ọdún méjì àkọ́kọ́ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Jo 7:2-10; 10:22, 23) Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńláńlá lẹ́bàá Òkun Gálílì àti lórí òkun náà. Rántí pé ó pàṣẹ fún omi Òkun Gálílì tí ń ru gùdù láti dákẹ́ jẹ́ẹ́, ó sì tún rìn lórí òkun náà. Ó wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn látinú ọkọ̀ ní àwọn etíkun olókùúta náà. Látinú ìdílé àwọn apẹja àti àwọn àgbẹ̀ tó wà nítòsí ibẹ̀ làwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti jáde wá.—Mk 3:7-12; 4:35-41; Lk 5:1-11; Jo 6:16-21; 21:1-19.
Kápánáúmù tó wà lẹ́bàá etíkun, tí í ṣe ‘ìlú Jésù,’ ni Jésù fi ṣe ibùjókòó nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì. (Mt 9:1) Ẹ̀bá òkè nítòsí ibẹ̀ ló wà nígbà tó ṣe Ìwàásù orí Òkè tó lókìkí gan-an yẹn. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó wọkọ̀ ojú omi láti àgbègbè Kápánáúmù lọ sí Mágádánì, Bẹtisáídà tàbí ibòmíràn nítòsí.
Kíyè sí i pé “ìlú ńlá” ti Jésù alára yìí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Násárétì, níbi tó gbé dàgbà; kò jìnnà sí Kánà, níbi tó ti sọ omi di ọtí wáìnì; kò jìnnà sí Náínì, níbi tó ti jí ọmọkùnrin opó kan dìde; kò sì jìnnà sí Bẹtisáídà, níbi tó ti fi iṣẹ́ ìyanu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] ènìyàn tó sì la ojú ọkùnrin afọ́jú kan.
Lẹ́yìn Ìrékọjá ti ọdún 32 Sànmánì Tiwa, Jésù ré kọjá lọ sí àríwá níhà Tírè àti Sídónì, àwọn ibùdókọ̀ òkun Foníṣíà. Lẹ́yìn náà ló wá mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò dé díẹ̀ lára àwọn ìlú Hélénì mẹ́wàá tó ń jẹ́ Dekapólì. Itòsí Kesaréà ti Fílípì (F2) ni Jésù wà nígbà tí Pétérù sọ pé òun mọ̀ ọ́n sí Mèsáyà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí Òkè Hámónì ni ìpaláradà ti wáyé kété lẹ́yìn náà. Nígbà tó yá, Jésù wàásù ní àgbègbè Pèríà, ní òdì kejì Jọ́dánì.—Mk 7:24-37; 8:27–9:2; 10:1; Lk 13:22, 33.
Jésù lo ọ̀sẹ̀ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Jerúsálẹ́mù, “ìlú ńlá ti Ọba ńlá,” àti ní àyíká rẹ̀. (Mt 5:35) O lè rí àwọn ìlú ìtòsí ibẹ̀ tó o ti kà nípa wọn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere nínú àwòrán níhìn-ín, àwọn ìlú bí Ẹ́máọ́sì, Bẹ́tánì, Bẹtifágè àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.—Lk 2:4; 19:29; 24:13; wo “Àgbègbè Jerúsálẹ́mù,” nínú àwòrán inú àkámọ́ lójú ìwé 18.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 29]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ilẹ̀ Ìlérí (Lákòókò Jésù)
Ilẹ̀ Náà Nígbà Tí Jésù Wà Láyé
Àwọn Ìlú Dekapólì
Ẹ5 Hípò
Ẹ6 Pẹ́là
Ẹ6 Sitopólísì
F5 Gádárà
F7 Gérásà
G5 Díónì
G9 Filadẹ́fíà
GB1 Damásíkù
GB4 Ráfánà
I5 Kánátà
Ojú Ọ̀nà Pàtàkì (Wo inú ìtẹ̀jáde)
Ọ̀nà Tààrà Láti Gálílì sí Jerúsálẹ́mù (Wo inú ìtẹ̀jáde)
Ọ̀nà Mìíràn Láti Gálílì Tó Gba Pèríà Kọjá Lọ sí Jerúsálẹ́mù (Wo inú ìtẹ̀jáde)
A11 Gásà
B6 Kesaréà
B8 Jópà
B9 Lídà
B12 Bíá-ṣébà
D4 Tólémáísì
D8 SAMÁRÍÀ
D8 Antipátírísì
D8 Arimatíà
D9 Ẹ́máọ́sì
D10 JÙDÍÀ
D11 Hébúrónì
D12 ÍDÚMÍÀ
E1 Sídónì
E2 Tírè
E3 FONÍṢÍÀ
E4 GÁLÍLÌ
E4 Kánà [ti Gálílì]
E5 Sẹ́pórísì
E5 Násárétì
E5 Náínì
E7 Samáríà
E7 Síkárì
E9 Éfúráímù
E9 Bẹtifágè
E9 Jerúsálẹ́mù
E9 Bẹ́tánì
E10 Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
E10 Hẹ́ródíọ́mù
E10 AGINJÙ JÚDÀ
E12 Màsádà
Ẹ4 Kórásínì
Ẹ4 Bẹtisáídà
Ẹ4 Kápánáúmù
Ẹ4 Mágádánì
Ẹ5 Tìbéríà
Ẹ5 Hípò
Ẹ6 Bẹ́tánì? (ní òdì kejì Jọ́dánì)
Ẹ6 Sitopólísì
Ẹ6 Pẹ́là
Ẹ6 Sálímù
Ẹ6 Áínónì
Ẹ9 Jẹ́ríkò
F1 ÁBÍLÉNÈ
F2 Kesaréà ti Fílípì
F4 Gámálà
F5 Ábílà?
F5 Gádárà
F7 PÈRÍÀ
F7 Gérásà
G3 ÍTÚRÉÀ
G5 Díónì
G6 DEKAPÓLÌ
G9 Filadẹ́fíà
GB1 Damásíkù
GB3 TÍRÁKÓNÍTÌ
GB4 Ráfánà
GB12 ARÉBÍÀ
I1 Kánátà
[Àwọn Òkè]
E7 Òkè Ébálì
E7 Òkè Gérísímù
F2 Òkè Hámónì
[Omi]
B6 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
Ẹ4 Òkun Gálílì
Ẹ10 Òkun Iyọ̀ (Òkun Òkú)
[Odò]
Ẹ7 Odò Jọ́dánì
[Ìsun Omi àti Kànga]
E7 Ibi Ìsun Omi Jékọ́bù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Òkun Gálílì. Kápánáúmù ló wà lápá òsì lọ́wọ́ iwájú. Apá gúúsù ìwọ̀-oòrùn Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́nésárẹ́tì ni a gbà wò ó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Orí Òkè Gérísímù làwọn ará Samáríà ti ń jọ́sìn. Òkè Ébálì ló wà lápá ẹ̀yìn nínú àwòrán