Jerúsálẹ́mù àti Tẹ́ńpìlì Tí Jésù Bá Láyé
Jerúsálẹ́mù àti Tẹ́ńpìlì Tí Jésù Bá Láyé
KÒ PẸ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìbí Jésù tí Jósẹ́fù àti Màríà fi gbé e lọ sí Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Baba rẹ̀ ọ̀run fi orúkọ Òun fúnra rẹ̀ sí. (Lk 2:22-39) Nígbà tí Jésù di ọmọ ọdún méjìlá, tó lọ síbẹ̀ láti lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, òye rẹ̀ ṣe àwọn olùkọ́ tó wà nínú tẹ́ńpìlì ní kàyééfì. (Lk 2:41-51) Iṣẹ́ kíkọ́ gbogbo tẹ́ńpìlì náà lápapọ̀, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ilé kíkọ́ tí Hẹ́rọ́dù Ńlá ṣe, ń bá a lọ fún ohun tó lé ní “ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta.”—Jo 2:20.
Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lọ síbi àwọn àjọyọ̀ tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù, níbi tó ti sábà máa ń kọ́ àwọn àwùjọ ènìyàn. Nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló lé àwọn olùpààrọ̀ owó àti àwọn oníṣòwò jáde kúrò nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì.—Mt 21:12; Jo 2:13-16.
Ní apá àríwá tẹ́ńpìlì náà, níbi odò adágún Bẹtisátà, Jésù mú ọkùnrin kan tó ti jìyà fún ọdún méjìdínlógójì lára dá. Ọmọ Ọlọ́run tún la ojú afọ́jú kan, nípa sísọ fún un pé kó lọ wẹ̀ nínú odò adágún Sílóámù ní apá ìhà gúúsù ìlú náà.—Jo 5:1-15; 9:1, 7, 11.
Jésù sábà máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásárù, Màríà àti Màtá, ní Bẹ́tánì tó wà ní “nǹkan bí ibùsọ̀ méjì” sí ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù. (Jo 11:1, 18, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé New World Translation of the Holy Scriptures—With References; 12:1-11; Lu 10:38-42; 19:29; wo “Jerúsálẹ́mù àti Àyíká Rẹ̀,” ojú ewé 18.) Ní ọjọ́ mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù gba orí Òkè Ólífì kọjá wá sí Jerúsálẹ́mù. Ìwọ ṣáà fi ọkàn yàwòrán bó ṣe tẹsẹ̀ dúró, tó yíjú wo ìlú náà lápá ìwọ̀ oòrùn tó sì sọkún lé e lórí. (Lk 19:37-44) Àwòrán tó wà lápá òkè ní ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí jẹ́ irú ohun tó o máa rí gẹ́lẹ́. Lẹ́yìn náà ló gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ẹnubodè tó wà níhà ìlà oòrùn ló gbà wọlé. Ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ń hó ìhó ayọ̀ tẹ̀ lé e lẹ́yìn láti fi hàn pé àwọn tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọba Ísírẹ́lì lọ́la.—Mt 21:9-12.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ṣáájú ikú Jésù wáyé yálà nínú ìlú Jerúsálẹ́mù tàbí lẹ́bàá ìlú náà: bíi ní ọgbà Gẹtisémánì, níbi tí Jésù ti gbàdúrà; gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn; ilé Káyáfà; ààfin Gómìnà Pílátù àti, ní Gọ́gọ́tà níkẹyìn.—Mk 14:32, 53–15:1, 16, 22; Jo 18:1, 13, 24, 28.
Lẹ́yìn àjíǹde Jésù, ó fara hàn nínú ìlú Jerúsálẹ́mù àti ní àyíká rẹ̀. (Lk 24:1-49) Ẹ̀yìn náà ló wá gba orí Òkè Ólífì gòkè re ọ̀run.—Iṣe 1:6-12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù/Hẹ́rọ́dù
Àwọn Ohun Tó Wà Ní Tẹ́ńpìlì
1. Ibi Mímọ́ Jù Lọ
2. Ibi Mímọ́
3. Pẹpẹ Ẹbọ Sísun
4. Òkun Dídà
5. Àgbàlá Àwọn Àlùfáà
6. Àgbàlá Ísírẹ́lì
7. Àgbàlá Àwọn Obìnrin
8. Àgbàlá Àwọn Kèfèrí
9. Àgánrándì Onírin (Sórégì)
10. Ìloro Ọba
11. Ìloro Sólómọ́nì
TẸ́ŃPÌLÌ
Ẹnubodè
Àgbàlá Àwọn Àlùfáà
Ẹnubodè
Ibi Mímọ́ Jù Lọ
Pẹpẹ Ẹbọ Sísun
Ibi Mímọ́
Àgbàlá Ísírẹ́lì
Àgbàlá Àwọn Obìnrin
Òkun Dídà
Ẹnubodè
Ìloro Sólómọ́nì
Àgánrándì Onírin (Sórégì)
Àgbàlá Àwọn Kèfèrí
Gate
Ìloro Ọba
Àwọn Ẹnubodè
Ilé Gogoro Àǹtóníà
Afárá
Gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn?
ÀFONÍFOJÌ TÍRÓPÓÓNÌ
Odò Adágún Sílóámù
Ọ̀nà Omi
Ilé Káyáfà?
Ààfin Gómìnà
Gọ́gọ́tà?
Gọ́gọ́tà?
Odò Adágún Bẹtisátà
Ọgbà Gẹtisémánì?
ÒKÈ ÓLÍFÌ
ÀFONÍFOJÌ KÍDÍRÓNÌ
Ojúsun omi Gíhónì
Ẹ́ń-rógélì
ÀFONÍFOJÌ HÍNÓMÙ (GẸ̀HẸ́NÀ)
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Bí Jerúsálẹ́mù òde òní ṣe rí bí a bá gba apá ìwọ̀ oòrùn wò ó: (A) tẹ́ńpìlì àti àyíká rẹ̀, (B) ọgbà Gẹtisémánì, (D) Òkè Ólífì, (E) aginjù Júdà, (Ẹ) Òkun Òkú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Bí apá ìwọ̀ oòrùn ṣe rí nígbà tí Jésù wà láyé bí a bá wò ó látorí Òkè Ólífì