‘Nígbà Tí Jèhófà Gbé Àwọn Onídàájọ́ Dìde’
‘Nígbà Tí Jèhófà Gbé Àwọn Onídàájọ́ Dìde’
KÒ ṢÒRO láti rí ibi tí Òkè Tábórì (F4) wà lórí àwòrán ilẹ̀. Gúúsù ìwọ̀-oòrùn Òkun Gálílì ló wà, níbi Àfonífojì Jésíréélì. Ìwọ ṣáà fojú inú wo ẹgbàárùn-ún [10,000] ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n pé jọ sórí òkè náà. Jèhófà lo Onídàájọ́ Bárákì àti Dèbórà, wòlíì obìnrin, láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ láti gbógun lọ bá Jábínì ọba ilẹ̀ Kénáánì tó ti ń fojú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì gbolẹ̀ fún ogún ọdún. Lábẹ́ ìdarí Sísérà tó jẹ́ olórí ogun, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] kẹ̀kẹ́ ogun Jábínì Ọba, tí wọ́n ní àwọn dòjé irin tó lè pani kú fin-ínfin-ín, wọ́n gbéra láti Háróṣétì wá sí ipadò gbígbẹ ti odò Kíṣónì, tó wà láàárín Mẹ́gídò àti Òkè Tábórì.
Onídàájọ́ Bárákì kó àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lọ sí àfonífojì náà láti lọ wà á kò pẹ̀lú agbo ọmọ ogun Sísérà. Jèhófà gba ogun yìí jà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa jíjẹ́ kí alagbalúgbú omi ya dé lójijì láti sọ ipadò náà di ẹrẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ̀tẹ̀, tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Sísérà sì ń rì sí i. Èyí mú kí jìnnìjìnnì bo àwọn ará Kénáánì. (Ond 4:1-5:31) Ọ̀kan péré nìyẹn lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà jà fún Ísírẹ́lì tó sì fi àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́ ní àkókò àwọn Onídàájọ́.
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn ará Kénáánì tán, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jogún ilẹ̀ wọn. Wàyí o, kíyè sí ibi tí àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà Léfì fìdí kalẹ̀ sí. Àwọn ìlú tó di ti ẹ̀yà Síméónì, tó jẹ́ ẹ̀yà kékeré, wà nínú ìpínlẹ̀ ti Júdà. Lẹ́yìn ikú Jóṣúà, ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀-èdè náà, wọ́n ya ìyàkuyà nípa tẹ̀mí, wọ́n sì di oníwàkiwà. Ísírẹ́lì sì wá “wà nínú hílàhílo gidigidi” nítorí pé àwọn ọ̀tà rẹ̀ fòòró rẹ̀. Nígbà tí ìyọ́nú tún sún Jèhófà láti ṣíjú àánú wò wọ́n, ‘Ó gbé àwọn onídàájọ́ dìde’—àwọn ọkùnrin méjìlá tí wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ àti ìgboyà—tí wọ́n ń gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ fún odindi ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún.—Ond 2:15, 16, 19.
Gídíónì Onídàájọ́ lo ọ̀ọ́dúnrún [300] ọmọ ogun tí kò dira púpọ̀, ṣùgbọ́n ti ẹsẹ̀ wọ́n yá nílẹ̀, láti gbógun ti ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [135,000] jagunjagun tó ti Mídíánì wá. Àárín Òkè Gíbóà àti Òkè Mórè ni wọ́n ti ja ìjà ọ̀hún. Nígbà tí Gídíónì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tà náà, ó lépa wọn lọ sínú aṣálẹ̀, ní ìlà oòrùn.—Ond 6:1-8:32.
Jẹ́fútà, ọmọ Gílíádì látinú ẹ̀yà Mánásè, gba àwọn ìlú Ísírẹ́lì tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì tí ń pọ́n wọn lójú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ojú Ọ̀nà Ọba, téèyàn lè gbà já sí Ramoti-gílíádì àti àgbègbè Áróérì ni Jẹ́fútà gbà kó bàa lè ṣẹ́gun.—Ond 11:1-12:7.
Àgbègbè etíkun tó yí Gásà àti Áṣíkẹ́lónì ká ni Sámúsìnì ti fi àjùlọ han àwọn Filísínì. Gásà wà ní àgbègbè tó lómi dáadáa tó sì dára gan-an fún iṣẹ́ àgbẹ̀. Sámúsìnì lo ọ̀ọ́dúnrún [300] kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láti tanná ran àwọn pápá ọkà, àwọn ọgbà àjàrà àti àwọn oko ólífì àwọn Filísínì.—Ond 15:4, 5.
Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣe fi hàn, tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà tí àwọn onídàájọ́ náà ti wá ṣe fi hàn, kò sí ibi tí àwọn onídàájọ́ ò sí ní ilẹ̀ ìlérí. Ibi yòówù kí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ wọn, ohun tó dájú ni pé lákòókò ìṣòro, Jèhófà ràdọ̀ bo àwọn èèyàn rẹ̀ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ẹ̀yà Àwọn Onídàájọ́
Àwọn Onídàájọ́
1. Ótíníẹ́lì (Tribe of Mánásè)
2. Éhúdù (Tribe of Júdà)
3. Ṣámúgárì (Tribe of Júdà)
4. Bárákì (Tribe of Náfútálì)
5. Gídíónì (Tribe of Ísákárì)
6. Tólà (Tribe of Mánásè)
7. Jáírì (Tribe of Mánásè)
8. Jẹ́fútà (Tribe of Gádì)
9. Íbísánì (Tribe of Áṣérì)
10. Ẹ́lónì (Tribe of Sébúlúnì)
11. Ábídónì (Tribe of Éfúráímù)
12. Sámúsìnì (Tribe of Júdà)
Ààlà Ilẹ̀ Ẹ̀yà Kọ̀ọ̀kan (Wo inú ìtẹ̀jáde)
Àwọn Ìlú Àdádó ti Mánásè
Ẹ4 Dórì
Ẹ5 Mẹ́gídò
Ẹ5 Táánákì
F4 Ẹ́ń-dórì
F5 Bẹti-ṣéánì (Bẹti-ṣánì)
F5 Íbíléámù (Gati-rímónì)
Àwọn Ìlú Àdádó ti Síméónì
D9 Ṣárúhénì (Ṣááráímù) (Ṣílíhímù)
D10 Bẹti-lẹ́báótì (Bẹti-bírì)
E8 Étérì (Tókénì)
E9 Síkílágì
E9 Áyínì
E9 Hasari-súsà?
E9 Áṣánì
E9 Bíá-ṣébà
E10 Hasari-ṣúálì
Ẹ9 Étámì
Ẹ9 Bẹti-mákábótì
Ẹ9 Bẹ́túélì? (Kẹ́sílì?)
Ẹ9 Ṣébà? (Jéṣúà)
Ẹ10 Baalati-béérì (Báálì)
Ẹ10 Ésémù
Àwọn Ìlú Ìsádi Àwọn Ọmọ Léfì
Ẹ8 Hébúrónì
F3 Kédéṣì
F6 Ṣékémù
GB4 Gólánì
GB5 Ramoti-gílíádì
GB8 Bésérì
Ojú Ọ̀nà Pàtàkì
B10 Ojú Ọ̀nà Òkun
G10 Ojú Ọ̀nà Ọba
Àwọn Ẹ̀yà Ísírẹ́lì
DÁNÌ (D7)
E7 Jópà
Ẹ8 Sórà
JÚDÀ (D9)
D8 Áṣíkẹ́lónì
D9 Gásà
D9 Ṣárúhénì (Ṣááráímù) (Ṣílíhímù)
D10 Bẹti-lẹ́báótì (Bẹti-bírì)
D12 Ásímónì
D12 Kádéṣì
E7 Jábínéélì
E8 Étérì (Tókénì)
E9 Síkílágì
E9 Áyínì
E9 Hasari-súsà?
E9 Áṣánì
E9 Bíá-ṣébà
E10 Hasari-ṣúálì
Ẹ8 Léhì
Ẹ8 Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Ẹ8 Hébúrónì
Ẹ9 Étámì
Ẹ9 Bẹti-mákábótì
Ẹ9 Bẹ́túélì? (Kẹ́sílì?)
Ẹ9 Ṣébà? (Jéṣúà)
Ẹ10 Baalati-béérì (Báálì)
Ẹ10 Ésémù
ÁṢÉRÌ (Ẹ3)
Ẹ2 Tírè
Ẹ4 Háróṣétì
Ẹ4 Dórì
F1 Sídónì
MÁNÁSÈ (Ẹ5)
Ẹ6 Ṣámírù (Samáríà)
Ẹ6 Pírátónì
F6 Ṣékémù
G6 Ebẹli-méhólà
ÉFÚRÁÍMÙ (Ẹ7)
Ẹ7 Timunati-sérà
F6 Tápúà
F6 Ṣílò
F7 Bẹ́tẹ́lì (Lúsì)
NÁFÚTÁLÌ (F3)
F2 Bẹti-ánátì
F3 Kédéṣì
G3 Hásórì
SÉBÚLÚNÌ (F4)
Ẹ4 Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
ÍSÁKÁRÌ (F5)
Ẹ5 Mẹ́gídò
Ẹ5 Kédéṣì (Kíṣíónì)
Ẹ5 Táánákì
F4 Ẹ́ń-dórì
F5 Bẹti-ṣítà
F5 Bẹti-ṣéánì (Bẹti-ṣánì)
F5 Íbíléámù (Gati-rímónì)
BẸ́ŃJÁMÍNÌ (F7)
F7 Gílígálì
F8 Jerúsálẹ́mù
DÁNÌ (G2)
G2 Dánì (Láíṣì)
MÁNÁSÈ (GB3)
GB4 Gólánì
GÁDÌ (I6)
G6 Súkótù
G6 Pénúélì
G6 Mísípà (Mísípè)
G7 Jógíbéhà
GB5 Ramoti-gílíádì
GB7 Rábà
GB7 Ebẹli-kérámímù
RÚBẸ́NÌ (GB8)
G7 Héṣíbónì
G9 Áróérì
GB7 Mínítì
GB8 Bésérì
[Àwọn ìbòmíì]
I1 Damásíkù
[Àwọn Òkè]
F4 Òkè Tábórì
F4 Mórè
F6 Òkè Ébálì
F5 Òkè Gíbóà
F6 Òkè Gérísímù
[Omi]
D5 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
F9 Òkun Iyọ̀
G4 Òkun Gálílì
[Àwọn Odò]
B11 A.O. Íjíbítì
F4 Odò Jọ́dánì
G6 A.O. Jábókù
G9 A.O. Áánónì
G11 A.O. Séréédì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àfonífojì Jésíréélì wà ní ìsàlẹ̀ Òkè Tábórì, ní ìpínlẹ̀ Ísákárì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Sísérà rì sínú ẹrẹ̀ tó wà ní ojú ọ̀gbàrá Kíṣónì