Àwọn Òbí
Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣètò ìgbéyàwó?
Èrò wo ló yẹ káwọn òbí ní nípa àwọn ọmọ wọn?
Tún wo “Àwọn Ọmọdé; Àwọn Ọ̀dọ́”
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 33:4, 5—Jékọ́bù gbà pé ẹ̀bùn pàtàkì làwọn ọmọ tí Jèhófà fún òun
-
Ẹk 1:15, 16, 22; 2:1-4; 6:20—Ámúrámù àti Jókébédì ni bàbá àti ìyá Mósè, àwọn méjèèjì múra tán láti kú torí kí wọ́n lè dáàbò bo ọmọ wọn
-
Kí ló yẹ káwọn òbí máa ṣe fáwọn ọmọ wọn?
Di 6:6, 7; 11:18, 19; Owe 22:6; 2Kọ 12:14; 1Ti 5:8
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà?
Tún wo 2Ti 3:14, 15
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 2:18-21, 26; 3:19—Àwọn òbí Sámúẹ́lì mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn kó lè máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà níbẹ̀, àmọ́ wọ́n máa ń bẹ̀ ẹ́ wò déédéé kí wọ́n lè pèsè àwọn nǹkan tó nílò fún un. Nígbà tọ́mọ náà wá dàgbà, ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
-
Lk 2:51, 52—Jésù ń gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ̀ lẹ́nu, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n
-
Ibo làwọn òbí ti lè rí ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ond 13:2-8—Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì kan sọ fún Mánóà pé Jèhófà máa mú kí ìyàwó ẹ̀ bí ọmọkùnrin kan, Mánóà bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn mọ bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ náà
-
Sm 78:3-8—Jèhófà fẹ́ káwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láwọn nǹkan táwọn fúnra wọn ti kọ́ látinú Bíbélì
-
Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti ń sin Jèhófà ni wọ́n ti tọ́ ọmọ kan dàgbà, kí ló lè mú kó pinnu pé òun ò ní sin Jèhófà?
Ìgbà wo ló yẹ káwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Di 29:10-12, 29; 31:12; Ẹsr 10:1—Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá kóra jọ láti jọ́sìn, wọ́n máa ń mú àwọn ọmọ wọn dání káwọn náà lè kẹ́kọ̀ọ́
-
Lk 2:41-52—Jósẹ́fù àti Màríà sábà máa ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, wọ́n sì máa ń mú Jésù àtàwọn àbúrò ẹ̀ dání
-
Àpẹẹrẹ wo ló yẹ káwọn òbí tẹ̀ lé nípa bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn tó lè pa wọ́n lára?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ẹk 19:4; Di 32:11, 12—Jèhófà fi ara ẹ̀ wé ẹyẹ idì tó máa ń gbé àwọn ọmọ ẹ̀, tó máa ń dáàbò bò wọ́n, tó sì ń tọ́jú wọn
-
Ais 49:15—Jèhófà ṣèlérí pé òun máa tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ òun, òun sì máa dáàbò bò wọ́n lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ju bí abiyamọ tó lójú àánú ṣe ń ṣàánú ọmọ ẹ̀
-
Mt 2:1-16—Sátánì gbìyànjú láti pa Jésù nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, ó darí àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n jẹ́ abọ̀rìṣà lọ sọ́dọ̀ Ọba Hẹ́rọ́dù, àmọ́ Jèhófà ní kí Jósẹ́fù mú ìdílé ẹ̀ lọ sí Íjíbítì kí wọ́n má bàa pa ọmọ ẹ̀
-
Mt 23:37—Jésù fi bó ṣe ń wù ú láti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ wé bí abo adìyẹ kan ṣe máa ń kó àwọn ọmọ ẹ̀ sábẹ́ ìyẹ́ ẹ̀, kó lè dáàbò bò wọ́n
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ìbálòpọ̀?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Le 15:2, 3, 16, 18, 19; Di 31:10-13—Òfin Mósè sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, Jèhófà sì pàṣẹ pé káwọn ọmọdé máa wà níbi tí wọ́n ti ń ka Òfin náà
-
Sm 139:13-16—Dáfídì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ó dá àwọn ẹ̀yà ara wa lọ́nà ìyanu, ẹ̀yà ìbímọ sì wà lára àwọn ẹ̀yà ara náà
-
Owe 2:10-15—Tá a bá gba ìmọ̀ àti ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú àtàwọn ẹlẹ́tàn
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí máa fìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí?
Owe 13:24; 29:17; Jer 30:11; Ef 6:4
Tún wo Sm 25:8; 145:9; Kol 3:21
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 32:1-5—Òótọ́ ni pé Dáfídì jìyà ohun tó ṣe nígbà tó dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ ara tù ú nígbà tó mọ̀ pé Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn
-
Jon 4:1-11—Wòlíì Jónà fìbínú sọ̀rọ̀ sí Jèhófà, síbẹ̀ Jèhófà fi sùúrù kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àánú
-
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìbáwí jẹ́ ara ọ̀nà táwọn òbí gbà ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn?
Tún wo Owe 15:32; Ifi 3:19