Àwọn Ọmọdé; Àwọn Ọ̀dọ́
Èrò Ọlọ́run nípa àwọn ọmọdé
Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ ṣeyebíye lójú rẹ̀?
Di 6:6, 7; 14:28, 29; Sm 110:3; 127:3-5; 128:3, 4; Jem 1:27
Tún wo Job 29:12; Sm 27:10; Owe 17:6
Tún wo “Ìdílé”
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 1:27, 28—Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn bímọ, kí wọ́n sì kún inú ayé
-
Jẹ 9:1—Lẹ́yìn Ìkún Omi, Ọlọ́run sọ fún Nóà àtàwọn ọmọkùnrin ẹ̀ pé kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì kún ayé
-
Jẹ 33:5—Ọkùnrin olóòótọ́ náà Jékọ́bù ka àwọn ọmọ ẹ̀ sí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bù kún òun
-
Mk 10:13-16—Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé bíi ti Bàbá rẹ̀
-
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń hùwà àìdáa sáwọn ọmọdé?
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká retí pé káwọn ọmọdé máa ṣiṣẹ́ tó yẹ kí àgbàlagbà máa ṣe?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 33:12-14—Jékọ́bù rọra rìnrìn àjò kí ìrìn náà má bàa nira jù fáwọn ọmọ ẹ̀
-
Ṣé Ọlọ́run ló yẹ ká dá lẹ́bi tí ìyà bá ń jẹ àwọn ọmọdé?
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé òun máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ tọmọdé tàgbà?
Tí òbí kan ò bá fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀ tàbí tó ń fìyà jẹ wọ́n, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ náà ò ní wúlò tó àwọn ọmọ míì tàbí pé wọ́n máa ṣe irú àṣìṣe tí òbí wọn ṣe?
Tún wo Di 30:15, 16
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Ọb 18:1-7; 2Kr 28:1-4—Bàbá Hẹsikáyà burú gan-an débi pé ó pa àwọn ọmọ ẹ̀ kan, àmọ́ Hẹsikáyà ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì di ọba tó dáa
-
2Ọb 21:19-26; 22:1, 2—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá Jòsáyà, ìyẹn Ámọ́nì jẹ́ ọba burúkú, Jòsáyà di ọba tó dáa
-
1Kọ 10:11, 12—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àṣìṣe táwọn míì ṣe, ká sì pinnu pé a ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀
-
Flp 2:12, 13—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé Jèhófà máa gbà wá là tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí i
-
Ohun tó yẹ káwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ máa ṣe
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ọmọ tó ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí tí ọ̀kan lára wọn bẹ̀rù Ọlọ́run?
Táwọn òbí ọmọ kan bá bẹ̀rù Ọlọ́run, ṣẹ́yẹn wá túmọ̀ sí pé ọmọ náà ti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Le 10:1-3, 8, 9—Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé àwọn ọmọ Áárónì Àlùfáà Àgbà mutí yó ni Jèhófà ṣe pa wọ́n
-
1Sa 8:1-5—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wòlíì tó jẹ́ olódodo ni Sámúẹ́lì, àwọn ọmọ ẹ̀ jẹ́ oníwà ìbàjẹ́
-
Kí ló yẹ káwọn ọmọ máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn?
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa lọ sípàdé ìjọ?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 15:32-38—Àwọn ọmọdé náà máa ń gbọ́ ìwàásù Jésù
-
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọdé máa jọ́sìn òun?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 17:4, 8-10, 41, 42, 45-51—Nígbà tí Dáfídì wà lọ́dọ̀ọ́, Jèhófà lò ó láti pa òmìrán burúkú kan tó ń pẹ̀gàn Jèhófà
-
2Ki 5:1-15—Jèhófà lo ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan láti ran Náámánì tó jẹ́ olórí ọmọ ogun ọba Síríà lọ́wọ́ kó lè mọ Ọlọ́run tòótọ́
-
Mt 21:15, 16—Jésù mọyì àwọn ọmọdé tó bọ̀wọ̀ fún un
-
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ọmọ tí òbí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Nọ 16:25, 26, 32, 33—Nígbà táwọn ọkùnrin kan ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì, Jèhófà fìyà jẹ àwọn ọkùnrin náà àtàwọn ìdílé wọn tó tì wọ́n lẹ́yìn
-
Nọ 26:10, 11—Jèhófà pa Kórà, àmọ́ kò pa àwọn ọmọ ẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọ̀dọ́ ronú dáadáa kí wọ́n tó yan ọ̀rẹ́?
Tún wo 2Ti 3:1-5
Irú àwọn èèyàn wo ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ Kristẹni máa bá ṣọ̀rẹ́?