Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayẹyẹ

Ayẹyẹ

Ayẹyẹ táwọn Kristẹni máa ń ṣe

Kí ni ayẹyẹ kan ṣoṣo tí Bíbélì sọ pé àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe?

Àwọn èèyàn Ọlọ́run gbádùn kí wọ́n máa pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run

Di 31:12; Heb 10:24, 25

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 30:1, 6, 13, 14, 18-27—Ọba Hẹsikáyà ṣètò àjọyọ̀ Ìrékọjá kan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló sì wà níbẹ̀

Àwọn ayẹyẹ táwa Kristẹni kì í ṣe

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ táwọn ẹlẹ́sìn èké dá sílẹ̀?

1Kọ 10:21; 2Kọ 6:14-18; Ef 5:10, 11

Tún wo “Dída Ẹ̀sìn Tòótọ́ Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Èké

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ẹk 32:1-10—Jèhófà bínú gan-an sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n gbìyànjú láti da ẹ̀sìn tòótọ́ pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn èké

    • Nọ 25:1-9—Jèhófà fìyà jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ torí pé wọ́n lọ́wọ́ sí ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà, wọ́n forí balẹ̀ fún òrìṣà, wọ́n sì tún ṣe ìṣekúṣe

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 2:1-5—Àkókò tí ìjọba Róòmù pàṣẹ pé kí wọ́n ka àwọn èèyàn ni wọ́n bí Jésù; kò sì jọ pé ìjọba Róòmù lè sọ pé káwọn Júù tó ti di ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí rìnrìn àjò láti lọ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà òtútù

    • Lk 2:8, 12—Nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà níta, kò sì jọ pé wọ́n lè wà níta gbangba lóṣù December tí òtútù máa ń mú gan-an

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 40:20-22—Abọ̀rìṣà ni Fáráò, ó sì pààyàn nígbà tó ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹ̀

    • Mt 14:6-11—Ọba Hẹ́rọ́dù kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gan-an. Nígbà tó ń ṣe ọjọ́ ìbí ẹ̀, ó pa Jòhánù Arinibọmi

Àwọn ayẹyẹ tó wà nínú Òfin Mósè

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, títí kan àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe nígbà yẹn?

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa pa òfin Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́?

Ayẹyẹ orílẹ̀-èdè

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ tí ìjọba fi ń rántí àwọn ohun tí wọ́n ti gbé ṣe?

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ayẹyẹ tí wọ́n fi ń rántí àwọn ogun tí orílẹ̀-èdè ti jà?

Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń júbà àwọn olókìkí èèyàn?

Ẹk 20:5; Ro 1:25

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 12:21-23—Ọlọ́run fìyà jẹ Ọba Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní torí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run, àmọ́ ó gbà kí àwọn èèyàn júbà òun

    • Iṣe 14:11-15—Àpọ́sítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù kò gbà káwọn èèyàn júbà àwọn

    • Ifi 22:8, 9—Áńgẹ́lì Jèhófà kan ò gbà kí Jòhánù jọ́sìn òun