Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bàbá

Bàbá

Kí ló yẹ káwọn bàbá máa ṣe fáwọn ọmọ wọn?

Di 6:6, 7; Ef 6:4; 1Ti 5:8; Heb 12:9, 10

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 22:2; 24:1-4—Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ Ísákì ọmọ rẹ̀ gan-an, torí náà ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ọmọ náà lè fẹ́ obìnrin tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

    • Mt 13:55; Mk 6:3—Àwọn kan máa ń pe Jésù ní “ọmọ káfíńtà,” àwọn míì sì ń pè é ní “káfíńtà”; ó ní láti jẹ́ pé Jóṣẹ́fù ló kọ́ Jésù ọmọ ẹ̀ ní iṣẹ́ náà

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa nífẹ̀ẹ́ bàbá wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn?

Ẹk 20:12

Tún wo Mt 6:9

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ho 11:1, 4—Jèhófà fi ara ẹ̀ wé bàbá kó lè fi hàn pé òun mọyì àwọn bàbá, ó sì tún fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn ẹ̀, ó sì máa ń fìfẹ́ bójú tó wọn bí bàbá kan ṣe máa ń ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀

    • Lk 15:11-32—Nínú àpèjúwe kan tí Jésù sọ, ó fi Jèhófà wé bàbá tó ń ṣàánú ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, àpèjúwe náà jẹ́ ká rí i pé Jésù mọyì àwọn bàbá