Bíbá Ayé Ṣọ̀rẹ́
Ta ló ń darí ayé yìí?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Lk 4:5-8—Sátánì sọ pé òun máa fún Jésù ní gbogbo ìjọba ayé, Jésù ò sì sọ pé kò láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀
-
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà tá a bá gbìyànjú láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé?
Tún wo Jem 1:27
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Kr 18:1-3; 19:1, 2—Jèhófà bá Ọba Jèhóṣáfátì wí torí pé ó bá Áhábù tó jẹ́ ọba búburú ṣọ̀rẹ́
-
Tá a bá mọ èrò Ọlọ́run nípa ayé yìí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ pinnu àwọn tá a máa bá ṣọ̀rẹ́?
Wo “Ọ̀rẹ́”
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ní irú èrò tọ́pọ̀ èèyàn ní nípa owó àtàwọn nǹkan ìní?
Wo “Kíkó Ohun Ìní Jọ”
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ní irú èrò tọ́pọ̀ èèyàn ní nípa ìṣekúṣe àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara?
Kí nìdí tí kò fi yẹ káwa Kristẹni máa júbà àwọn ọkùnrin, obìnrin tàbí ẹgbẹ́ èyíkéyìí?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Iṣe 12:21-23—Jèhófà pa Hẹ́rọ́dù Ágírípà Kìíní torí pé ó gbà káwọn èèyàn jọ́sìn òun
-
Ifi 22:8, 9—Áńgẹ́lì alágbára kan ò gbà kí àpọ́sítélì Jòhánù jọ́sìn òun, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé Jèhófà nìkan ló yẹ ká jọ́sìn
-
Kí nìdí táwa Kristẹni kì í fi í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ká máa sọ pé orílẹ̀-èdè wa ló dáa jù?
Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í jọ́sìn pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn míì?
Kí nìdí táwa Kristẹni fi fara mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà dípò ìlànà tí aráyé ń tẹ̀ lé?
Lk 10:16; Kol 2:8; 1Tẹ 4:7, 8; 2Ti 4:3-5
Tún wo Lk 7:30
Kí nìdí tọ́pọ̀ èèyàn fi sábà máa ń kórìíra àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n sì máa ń ṣenúnibíni sí wa?
Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti nífẹ̀ẹ́ ayé?
Báwo làwa Kristẹni ṣe ń fi inúure àti ìfẹ́ hàn sáwọn tí kò jọ́sìn Jèhófà?
Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ, ká sì máa pa òfin ìjọba mọ́?