Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dída Ẹ̀sìn Tòótọ́ Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Èké

Dída Ẹ̀sìn Tòótọ́ Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Èké

Ṣé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo èèyàn ń jọ́sìn?

Ṣé gbogbo ẹ̀sìn ni inú Ọlọ́run dùn sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó yàtọ̀ síra ni wọ́n ń kọ́ni?

Mt 7:13, 14; Jo 17:3; Ef 4:4-6

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Joṣ 24:15—Jóṣúà sọ pé a gbọ́dọ̀ pinnu bóyá Jèhófà la máa sìn àbí àwọn ọlọ́run míì

    • 1Ọb 18:19-40—Nípasẹ̀ wòlíì Èlíjà, Jèhófà jẹ́ ká rí i pé kò yẹ kí àwọn tó ń sin Ọlọ́run tòótọ́ tún máa jọ́sìn ọlọ́run míì

Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ọlọ́run míì, báwo ló sì ṣe máa ń rí lára ẹ̀ táwọn èèyàn bá ń jọ́sìn wọn?

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn èèyàn bá sọ pé òun làwọn ń sìn, àmọ́ tí wọ́n ń ṣe ohun tínú ẹ̀ ò dùn sí nínú ìjọsìn wọn?

Ais 1:13-15; 1Kọ 10:20-22; 2Kọ 6:14, 15, 17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ẹk 32:1-10—Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jọ́sìn ère ọmọ màlúù tí Áárónì ṣe, wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an

    • 1Ọb 12:26-30—Torí pé Ọba Jèróbóámù ò fẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó ṣe ère kan ó sì sọ pé Jèhófà ni ère náà ṣàpẹẹrẹ, ohun tó ṣe yìí mú káwọn èèyàn náà dẹ́ṣẹ̀

Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń jọ́sìn àwọn Ọlọ́run míì?

Kí ni Jèhófà ṣe nígbà táwọn èèyàn ẹ̀ lọ ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì?

Ond 10:6, 7; Sm 106:35-40; Jer 44:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 11:1-9—Àwọn obìnrin àjèjì tí Ọba Sólómọ́nì fẹ́ mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀, ìyẹn sì múnú bí Jèhófà

    • Sm 78:40, 41, 55-62—Ásáfù sọ pé ó dun Jèhófà gan-an nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí i tí wọ́n sì di abọ̀rìṣà, torí náà Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀

Ojú wo ni Jésù fi ń wo àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 16:6, 12—Jésù fi ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti tàwọn Sadusí wé ìwúkàrà torí pé ẹ̀kọ́ èké máa ń tètè tàn kálẹ̀, ó sì máa ń bomi la òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

    • Mt 23:5-7, 23-33—Jésù dẹ́bi fún àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí torí pé alágàbàgebè ni wọ́n, wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni

    • Mk 7:5-9—Jésù tú àṣírí àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí torí pé wọ́n ka àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ sí pàtàkì ju àṣẹ Ọlọ́run lọ

Ṣé Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jo 15:4, 5—Jésù sọ àpèjúwe àjàrà kan láti fi ṣàlàyé bó ṣe yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú òun àti láàárín ara wọn

    • Jo 17:1, 6, 11, 20-23—Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín gbogbo àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn òun

Ṣé ohun kan náà làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà gbọ́, ṣé ọ̀nà kan náà ni wọ́n sì ń gbà jọ́sìn Jèhófà?

Iṣe 16:4, 5; Ro 12:4, 5

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 11:20-23, 25, 26—Àwọn ará tó wà ní Áńtíókù àti Jerúsálẹ́mù jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n sì wà níṣọ̀kan

    • Ro 15:25, 26; 2Kọ 8:1-7—Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn àti pé wọ́n wà níṣọ̀kan

Ṣé gbogbo ẹ̀sìn tó sọ pé àwọn gba Jésù gbọ́ ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?

Ṣé Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn tó ń ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí Kristi àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ kọ́ni?

Iṣe 20:29, 30; 1Ti 4:1-3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 13:24-30, 36-43—Jésù fi àwọn ayédèrú Kristẹni wé èpò tó yọ jáde láàárín àlìkámà, ó sì sọ pé tó bá yá, àwọn ayédèrú Kristẹni máa wọnú ìjọ

    • 1Jo 2:18, 19—Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé àwọn aṣòdì sí Kristi ti wà nínú ìjọ Kristẹni lápá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá fàyè gba ẹ̀kọ́ èké àti ìwàkiwà nínú ìjọ Kristẹni?

Kí ló yẹ káwa Kristẹni ṣe ká lè máa bá a lọ láti wà níṣọ̀kan?

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni yẹra fún ìjọsìn èké?

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu?

Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu táwọn èèyàn bá ń ta ko ìjọsìn tòótọ́, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wa?