Eré Ìnàjú
Ṣó burú táwa Kristẹni bá wáyè láti sinmi, ká sì tún gbádùn ara wa?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mk 6:31, 32—Ọwọ́ Jésù máa ń dí gan-an, síbẹ̀ ó ní kí òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá ibì kan tó pa rọ́rọ́ kí wọ́n lè sinmi
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa ṣeré ìnàjú débi pé a ò ní ráyè àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà mọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fáwọn eré ìnàjú tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ?
Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fáwọn eré ìnàjú tó ń gbé ìbínú àti ẹ̀mí ìdíje lárugẹ?
Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fáwọn eré ìnàjú tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ?
Báwo làwa Kristẹni ṣe lè mọ àwọn nǹkan tí kò yẹ ká máa fi dápàárá?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gba tàwọn míì rò ká tó pinnu irú eré ìnàjú tá a máa ṣe?