Ẹ̀rí Ọkàn
Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà fún ní ẹ̀rí ọkàn?
Tún wo 2Kọ 4:2
Tẹ́nì kan ò bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀?
Tẹ́nì kan bá ṣáà ti gbà pé ohun tó dáa lòun ń ṣe, ṣéyẹn náà ti tó?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Kr 18:1-3; 19:1, 2—Jèhófà bínú sí Ọba Jèhóṣáfátì torí pé ó ran Áhábù tó jẹ́ ọba búburú lọ́wọ́
-
Iṣe 22:19, 20; 26:9-11—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé nígbà kan, òun gbà pé ó dáa bóun ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tóun sì ń fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa wọ́n
-
Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 24:2-7—Torí pé ẹ̀rí ọkàn Ọba Dáfídì ń ṣiṣẹ́ dáadáa, kò hùwà àìdáa sí Ọba Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà
-
Báwo làwa èèyàn aláìpé ṣe lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Ọlọ́run?
Ef 1:7; Heb 9:14; 1Pe 3:21; 1Jo 1:7, 9; 2:1, 2
Tún wo Ifi 1:5
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ais 6:1-8—Jèhófà fi wòlíì Àìsáyà lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jì í
-
Ifi 7:9-14—Ẹbọ ìràpadà Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa hùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára ká máa bàa kó ẹ̀dùn ọkàn bá arákùnrin tàbí arábìnrin tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ kò tíì lágbára?
Kí ló yẹ ká pinnu nípa ẹ̀rí ọkàn wa?