Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbáwí

Ìbáwí

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Bíbélì ló dáa jù láti fi báni wí?

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo wa la nílò ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà?

Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń báni wí?

Owe 3:11, 12; Heb 12:7-9

Tún wo Di 8:5; Owe 13:24; Ifi 3:19

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Sa 12:9-13; 1Ọb 15:5; Iṣe 13:22—Ọba Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, síbẹ̀ Jèhófà fìfẹ́ bá a wí, ó sì dárí jì í

    • Jon 1:1-4, 15-17; 3:1-3—Jèhófà bá wòlíì Jónà wí torí pé ó sá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tó fún un, àmọ́ ó tún fún Jónà láǹfààní láti pa dà lọ ṣe iṣẹ́ náà

Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìbáwí tí Jèhófà bá fún wa?

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá kọ ìbáwí Jèhófà?

Owe 1:24-26; 13:18; 15:32; 29:1

Tún wo Jer 7:27, 28, 32-34

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jer 5:3-7—Àwọn èèyàn Jèhófà kọ ìbáwí rẹ̀, wọn ò sì yíwà pa dà, torí náà Jèhófà túbọ̀ fún wọn ní ìbáwí tó le sí i

    • Sef 3:1-8—Àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù kọ ìbáwí Jèhófà, torí náà wọ́n fa àjálù bá ara wọn

Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá gba ìbáwí Jèhófà?

Owe 4:13; 1Kọ 11:32; Tit 1:13; Heb 12:10, 11

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Di 30:1-6—Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá jẹ́ onígbọràn, Jèhófà máa bù kún wọn

    • 2Kr 7:13, 14—Jèhófà jẹ́ kí Ọba Sólómọ́nì mọ àwọn nǹkan rere tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn òun tí wọ́n bá gba ìbáwí òun

Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìbáwí tí wọ́n fún àwọn míì?

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa yọ̀ nígbà táwọn míì bá ṣàṣìṣe, tó sì yẹ kí wọ́n bá wọn wí lọ́nà tó le?

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà ṣe wá láǹfààní?

Joṣ 1:8; Jem 1:25

Tún wo Di 17:18, 19; Sm 119:97

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Kr 22:11-13—Ọba Dáfídì fi Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà á máa bù kún un tó bá ṣáà ti ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún un

    • Sm 1:1-6—Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn tó bá ń ka òfin òun, tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lé e lórí

Kí nìdí táwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn fi máa ń bá wọn wí?

Wo “Àwọn Òbí

Kí ló yẹ káwọn ọmọ ṣe táwọn òbí wọn bá ń bá wọn wí?