Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbẹ̀rù

Ìbẹ̀rù

Gbígbọ̀n jìnnìjìnnì; ìbẹ̀rùbojo

Di 20:8; Ond 7:3; Owe 29:25

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ẹk 32:1-4, 21-24—Áárónì gbà láti ṣe ère fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí ó ń bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn náà máa ṣe fóun

    • Mk 14:50, 66-72—Nígbà tí wọ́n mú Jésù, gbogbo àwọn àpọ́sítélì sá lọ torí pé ẹ̀rù bà wọ́n, kódà ìbẹ̀rù mú kí Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:

    • 2Kr 20:1-17, 22-24—Ẹ̀rù ba Ọba Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Ọlọ́run tó kù nígbà táwọn ọ̀tá tó lágbára wá bá wọn jà, àmọ́ Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì gbà wọ́n là

    • Lk 12:4-12—Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n máa bẹ̀rù èèyàn, kò sì yẹ kí wọ́n máa ṣàníyàn nípa ohun tí wọ́n máa sọ tí wọ́n bá ní láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn níwájú àwọn aláṣẹ, torí pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́