Ìdílé
Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀
Àwọn Òbí
Wo “Àwọn Òbí”
Àwọn Bàbá
Wo “Bàbá”
Àwọn Ìyá
Wo “Ìyá”
Àwọn Ọkọ, Àwọn Aya
Wo “Ìgbéyàwó”
Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin
Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ máa ṣe?
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 78:1-8—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ nípa ohun táwọn baba ńlá wọn ṣe lẹ́yìn tí Jèhófà fún wọn lófin, torí wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí i
-
Lk 2:51, 52—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ̀ tó jẹ́ aláìpé
-
Kí ló lè mú kó ṣòro fáwọn ọmọ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn?
Èrò wo ni Jèhófà ní nípa àwọn ọmọ tí kì í gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Di 21:18-21—Òfin Mósè sọ pé tí ọmọkùnrin kan bá jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ àti alágídí, tí kì í gbọ́ràn sáwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu, ńṣe ni kí wọ́n pa á
-
2Ọb 2:23, 24—Torí pé àwọn ọmọkùnrin kan tàbùkù sí wòlíì Èlíṣà tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run, abo bíárì méjì pa ọ̀pọ̀ lára wọn
-
Ojú wo ló yẹ káwọn òbí fi máa wo àǹfààní tí wọ́n ní láti tọ́ ọmọ?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Le 26:9—Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá lọ́mọ, wọ́n gbà pé ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni
-
Job 42:12, 13—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyà jẹ Jóòbù gan-an, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, Jèhófà sì fún òun àti ìyàwó ẹ̀ ní ọmọ mẹ́wàá míì
-
Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ káwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò máa ṣe síra wọn?
Àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn ọmọ tó ti dàgbà máa ṣe fáwọn òbí wọn àtàwọn òbí wọn àgbà?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 11:31, 32—Nígbà tí Ábúráhámù ń kúrò ní Úrì, ó mú Térà bàbá rẹ̀ dání, ó sì ń tọ́jú ẹ̀ títí tó fi kú
-
Mt 15:3-6—Jésù tọ́ka sí ohun tí Òfin Mósè sọ láti fi hàn pé ó yẹ káwọn ọmọ tó ti dàgbà máa tọ́jú àwọn òbí wọn
-
Àwọn Àna
Wo “Àwọn Àna”
Àwọn Òbí Àgbà
Wo “Àwọn Òbí Àgbà”