Ìfaradà
Ṣé àwa Kristẹni nílò ìfaradà?
Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn kan ò ní gbọ́ ìwàásù wa àti pé wọ́n tiẹ̀ lè ṣenúnibíni sí wa?
Mt 10:22; Jo 15:18, 19; 2Kọ 6:4, 5
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Pe 2:5; Jẹ 7:23; Mt 24:37-39—Àwọn èèyàn ò fetí sí Nóà nígbà tó wàásù fún wọn, nígbà tí Ìkún Omi sì dé, Nóà àti ìdílé ẹ̀ nìkan ló là á já
-
2Ti 3:10-14—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé òun ti fara da ọ̀pọ̀ inúnibíni, ó wá rọ Tímótì pé kóun náà ní ìfaradà
-
Táwọn mọ̀lẹ́bí wa kan bá ń ṣe inúnibíni sí wa torí pé à ń sin Jèhófà, kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 4:3-11; 1Jo 3:11, 12—Torí pé Kéènì jẹ́ èèyàn burúkú, ó pa arákùnrin ẹ̀ Ébẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́
-
Jẹ 37:5-8, 18-28—Jèhófà jẹ́ kí Jósẹ́fù lá àlá kan, ó sì sọ fáwọn arákùnrin ẹ̀ nípa àlá náà, àmọ́ wọ́n jù ú sínú kòtò, wọ́n sì tà á fáwọn tó máa fi ṣẹrú
-
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù ikú tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa?
Tún wo Ifi 2:10
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Da 3:1-6, 13-18—Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ò jọ́sìn ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba sọ pé òun máa pa ẹnikẹ́ni tí kò bá jọ́sìn ère náà
-
Iṣe 5:27-29, 33, 40-42—Àwọn àpọ́sítélì ń bá a lọ láti máa wàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin kan sọ pé àwọn máa pa wọ́n tí wọn ò bá yéé wàásù
-
Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kódà tí wọ́n bá bá wa wí?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Nọ 20:9-12; Di 3:23-28; 31:7, 8—Wòlíì Mósè ò fi Jèhófà sílẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀ ò dùn nígbà tí Jèhófà bá a wí
-
2Ọb 20:12-18; 2Kr 32:24-26—Nígbà tí Ọba Hẹsikáyà dẹ́ṣẹ̀ tí wòlíì Jèhófà sì bá a wí, ńṣe ló rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà
-
Kí nìdí tó fi máa ń nira láti fara dà á táwọn kan bá fi Jèhófà sílẹ̀?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 73:2-24—Nígbà tí onísáàmù kan rí i pé nǹkan ń dùn fáwọn tí kò sin Jèhófà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì bóyá àǹfààní wá nínú kéèyàn máa sin Jèhófà
-
Jo 6:60-62, 66-68—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni kò tẹ̀ lé e mọ́, àpọ́sítélì Pétérù ò fi Jésù sílẹ̀ torí pé ó nígbàgbọ́
-
Kí ló máa jẹ́ ká lè ní ìfaradà?
Tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà
Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀
Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé látọkàn wá
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Da 6:4-11—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí wòlíì Dáníẹ́lì wà nínú ewu, ó ń bá a lọ láti máa gbàdúrà sí Jèhófà
-
Mt 26:36-46; Heb 5:7—Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó fìtara gbàdúrà, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀
-
Tá a bá ń lọ sípàdé déédéé
Tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú
Tá a bá ń ṣe ohun tó máa mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa tá a sì ń wá òdodo
Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára
Tá a bá ń rántí pé tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà tí ò bá tiẹ̀ rọrùn, inú ẹ̀ máa dùn sí wa
Tá a bá ń fara dà á tá a sì ń ṣe ohun tó tọ́, àǹfààní wo lá máa rí?
A máa múnú Jèhófà dùn
Owe 27:11; Jo 15:7, 8; 1Pe 1:6, 7
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Job 1:6-12; 2:3-5—Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà pé ó máa ń ṣe ohun rere fáwọn èèyàn kí wọ́n lè máa jọ́sìn ẹ̀. Kí ọ̀rọ̀ náà lè yanjú, Jóòbù ní láti fara da àwọn ìṣòro tó le kó lè fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa
-
Ro 5:19; 1Pe 1:20, 21—Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dópin jẹ́ ká rí ìdáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí: Ṣé èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tó bá wà nínú àdánwò tó le gan-an?
-
A máa fún àwọn ará wa níṣìírí kí wọ́n lè ní ìfaradà
Tá a bá ní ìfaradà, a máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa
Inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀