Ìgbàgbọ́
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ka ìgbàgbọ́ sí ohun tó ṣe pàtàkì?
Jo 3:16, 18; Ga 3:8, 9, 11; Ef 6:16; Heb 11:6
Tún wo 2Kọ 5:7
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Heb 11:1–12:3—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí, ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ bí Ébẹ́lì àti Jésù Kristi
Jem 2:18-24—Bíi ti Ábúráhámù, Jémíìsì sọ pé ó yẹ ká ṣe ohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́
Kí ló máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára?
Ro 10:9, 10, 17; 1Kọ 16:13; Jem 2:17
Tún wo Heb 3:12-14
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Kr 20:1-6, 12, 13, 20-23—Nígbà táwọn ọ̀tá wá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, Ọba Jèhóṣáfátì jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ pé, tí wọ́n bá fẹ́ ṣàṣeyọrí wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn wòlíì rẹ̀
1Ọb 18:41-46—Nígbà tí òjò ò rọ̀ fún àkókò gígùn, wòlíì Èlíjà ṣe ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ní ti pé ó fi sùúrù dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ