Ìjákulẹ̀
Táwọn èèyàn bá já wa kulẹ̀, tí wọ́n ṣe ohun tó dùn wá tàbí tí wọ́n dalẹ̀ wa
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 8:1-6—Inú wòlíì Sámúẹ́lì bà jẹ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé ó gbọ́dọ̀ yan ọba fáwọn
-
1Sa 20:30-34—Inú Jónátánì bà jẹ́ nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ bàbá rẹ̀ bínú sí i, tó sì kàn án lábùkù
-
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Sm 55:12-14, 16-18, 22—Áhítófẹ́lì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Ọba Dáfídì dalẹ̀ rẹ̀, àmọ́ Dáfídì kó gbogbo ìṣòro rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, ara sì tù ú
-
2Ti 4:16-18—Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù níṣòro, àwọn èèyàn pa á tì, àmọ́ ó ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún un, ìyẹn sì mú kó lókun
-
Tá a bá ń ronú nípa ibi tá a kù sí àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Sm 51:1-5—Inú Ọba Dáfídì bà jẹ́ gan-an torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó dá
-
Ro 7:19-24—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ò já mọ́ nǹkan kan nígbà tó ronú nípa bí èrò burúkú ṣe máa ń mú kó wu òun láti ṣe ohun tí kò dáa
-
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
1Ọb 9:2-5—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà kà á sí adúróṣinṣin
-
1Ti 1:12-16—Láìka bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá sẹ́yìn ṣe pọ̀ tó, ó dá a lójú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí òun
-