Ìmọ̀ràn
Ohun tó yẹ ká ṣe tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn
Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí Bíbélì máa tọ́ wa sọ́nà?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gba ìmọ̀ràn dípò ká máa ṣàwáwí?
Tún wo Owe 1:23-31; 15:31
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 15:3, 9-23—Nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì gba Ọba Sọ́ọ̀lù nímọ̀ràn, ńṣe ló ń ṣàwáwí dípò táá fi gba ìmọ̀ràn, torí náà Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba
-
2Kr 25:14-16, 27—Àwọn wòlíì Jèhófà fún Ọba Amasááyà nímọ̀ràn torí ìwà àìdáa tó hù, àmọ́ ọba náà ò gbà, torí náà inú Jèhófà ò dùn sí i mọ́, kò sì dáàbò bò ó
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alábòójútó tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn?
1Tẹ 5:12; 1Ti 5:17; Heb 13:7, 17
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
3Jo 9, 10—Àpọ́sítélì Jòhánù dá Díótíréfè lẹ́bi torí pé kì í bọ̀wọ̀ fáwọn alábòójútó nínú ìjọ
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ́tí sáwọn àgbàlagbà?
Tún wo Job 12:12; 32:7; Tit 2:3-5
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 23:16-18—Ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì fi ju Ọba Dáfídì lọ. Jónátánì fún Dáfídì nímọ̀ràn, ó fetí sí i, ìmọ̀ràn náà sì fún un lókun
-
1Ọb 12:1-17—Ọba Rèhóbóámù ò fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n táwọn àgbà ọkùnrin fún un, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fetí sí ìmọ̀ràn tó le koko táwọn ọ̀dọ́ bíi tiẹ̀ fún un, èyí sì dá wàhálà sílẹ̀
-
Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn obìnrin olóòótọ́ àtàwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lè fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n?
Job 32:6, 9, 10; Owe 31:1, 10, 26; Onw 4:13
Tún wo Sm 119:100
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 25:14-35—Ábígẹ́lì fún Ọba Dáfídì nímọ̀ràn, ìyẹn ò sì jẹ́ kí Dáfídì pa ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀
-
2Sa 20:15-22—Ìmọ̀ràn tí obìnrin ọlọ́gbọ́n kan fún àwọn ará ìlú Ébẹ́lì gba ẹ̀mí wọn là
-
2Ọb 5:1-14—Ọmọbìnrin kékeré kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì fún ọ̀gágun kan nímọ̀ràn nípa bó ṣe lè rí ìwòsàn kó sì bọ́ lọ́wọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀ tó ń ṣe é
-
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
Tún wo Lk 6:39
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Kr 10:13, 14—Ọba Sọ́ọ̀lù lọ wádìí lọ́dọ̀ abẹ́mìílò dípò kó wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì kú torí pé ó jẹ́ aláìṣòótọ́
-
2Kr 22:2-5, 9—Ọba Ahasáyà kú torí pé ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn burúkú
-
Job 21:7, 14-16—Jóòbù ò fara mọ́ èrò àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà
-
Bá a ṣe lè fúnni nímọ̀ràn
Tá a bá fẹ́ fúnni nímọ̀ràn, kí nìdí tó fi yẹ ká gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, ká fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ látẹnu àwọn tọ́rọ̀ náà kàn, ká sì lóye ohun tó ṣẹlẹ̀, ká tó ṣe bẹ́ẹ̀?
Tún wo Owe 25:8
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 1:9-16—Kí Àlùfáà Àgbà Élì tiẹ̀ tó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ló ti bá Hánà wí lọ́nà tó le koko, ńṣe ló kàn gbà pé obìnrin olóòótọ́ yìí ti mutí yó
-
Mt 16:21-23—Àpọ́sítélì Pétérù bá Jésù wí láìronú jinlẹ̀, ó sì fún Jésù nímọ̀ràn tó lè mú kó ṣe ohun tí Sátánì fẹ́ dípò ohun tí Jèhófà fẹ́
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká tó fún ẹnì kan nímọ̀ràn?
Sm 32:8; 73:23, 24; Owe 3:5, 6
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ẹk 3:13-18—Wòlíì Mósè sọ pé kí Jèhófà sọ bí òun ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bi òun
-
1Ọb 3:5-12—Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì wà lọ́dọ̀ọ́, dípò kó gbára lé òye ara ẹ̀, ó bẹ Jèhófà pé kó fún òun ní ọgbọ́n, èyí sì mú kí Jèhófà bù kún un
-
Tá a bá fẹ́ fún ẹnì kan nímọ̀ràn, kí nìdí tó fi yẹ kó dá lé ohun tó wà nínú Bíbélì?
Sm 119:24, 105; Owe 19:21; 2Ti 3:16, 17
Tún wo Di 17:18-20
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 4:1-11—Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi dá a lóhùn, kì í ṣe ọgbọ́n ara ẹ̀
-
Jo 12:49, 50—Jésù sọ pé àwọn nǹkan tóun gbọ́ látọ̀dọ̀ Bàbá òun lòun ń kọ́ àwọn èèyàn, ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn
-
Tá a bá fẹ́ fún ẹnì kan nímọ̀ràn, kí nìdí tó fi yẹ ká fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ẹni náà sọ̀rọ̀, ká sì tún gbóríyìn fún un nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀?
Tún wo Ais 9:6; 42:1-3; Mt 11:28, 29
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Kr 19:2, 3—Jèhófà ní kí wòlíì kan lọ bá Ọba Jèhóṣáfátì wí, kó sì tún gbóríyìn fún un torí àwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe
-
Ifi 2:1-4, 8, 9, 12-14, 18-20—Nígbà tí Jésù fẹ́ fún àwọn ìjọ kan nímọ̀ràn, ó kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn
-
Tí Kristẹni kan bá sọ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan rẹ́ òun jẹ tàbí pé ó sọ̀rọ̀ òun láìdáa, kí nìdí tó fi yẹ ká sọ fún un pé kó kọ́kọ́ lọ bá onítọ̀hún kí wọ́n lè jọ sọ̀rọ̀?
Tún wo Le 19:17
Tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí Kristẹni kan, báwo la ṣe lè jẹ́ kó rí i pé ó yẹ kó fi àánú hàn, kó ní sùúrù, kó sì múra tán láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́?
Mt 18:21, 22; Mk 11:25; Lk 6:36; Ef 4:32; Kol 3:13
Tún wo Mt 6:14; 1Kọ 6:1-8; 1Pe 3:8, 9
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 18:23-35—Jésù sọ àpèjúwe kan tó wọni lọ́kàn gan-an, ká lè rí i pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa dárí jini
-
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù láti fún ẹnì kan nímọ̀ràn tó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí kò bá tiẹ̀ bá ẹni náà lára mu?
Sm 141:5; Owe 17:10; 2Kọ 7:8-11
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 15:23-29—Wòlíì Sámúẹ́lì ò bẹ̀rù láti fún Ọba Sọ́ọ̀lù nímọ̀ràn
-
1Ọb 22:19-28—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Áhábù halẹ̀ mọ́ wòlíì Mikáyà tó sì fìyà jẹ ẹ́, Mikáyà ò yí ọ̀rọ̀ tó sọ fún ọba náà pa dà
-
Báwo la ṣe lè fún ẹnì kan nímọ̀ràn, tá ò sì ní mú kẹ́ni náà fi Jèhófà sílẹ̀?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Lk 22:31-34—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pétérù ṣe àwọn àṣìṣe tó lágbára, Jésù gbà pé kò ní fi Jèhófà sílẹ̀, ó máa ṣàtúnṣe tó yẹ, ó sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́
-
Flm 21—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Fílémónì ní ìmọ̀ràn tó dáa, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lójú pé ó máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà
-
Tá a bá fẹ́ fún àwọn tó ní ìdààmú ọkàn nímọ̀ràn, báwo ló ṣe yẹ ká ṣe é?
Tá a bá fẹ́ fún ẹnì kan tó hùwà àìtọ́ nímọ̀ràn, báwo la ṣe lè jẹ́ kó mọ̀ pé ńṣe la fẹ́ ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fún ẹni tá a fẹ́ fún nímọ̀ràn, ì báà jẹ́ ọmọdé, àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin?
Tẹ́nì kan ò bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú, kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà bá a wí lọ́nà tó lágbára?