Irọ́
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó máa ń parọ́ tàbí tó máa ń yẹ àdéhùn?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ẹk 9:27, 28, 34, 35—Fáráò sọ pé òun máa jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ, àmọ́ kò mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ
Isk 17:11-15, 19, 20—Jèhófà fìyà jẹ Ọba Sedekáyà torí pé kò mú ìlérí tó ṣe fún ọba Bábílónì ṣẹ
Iṣe 5:1-10—Ananáyà àti Sàfírà sọ pé gbogbo owó táwọn rí nígbà táwọn ta ilẹ̀ àwọn làwọn kó wá fún ìjọ
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó máa ń ba àwọn míì jẹ́?
Sm 15:1-3; Owe 6:16-19; 16:28; Kol 3:9
Tún wo Owe 11:13; 1Ti 3:11
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Sa 16:1-4; 19:24-30—Olóòótọ́ èèyàn ni Méfíbóṣétì, àmọ́ Síbà tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ bà á jẹ́ lójú Dáfídì
Ifi 12:9, 10—Èṣù tó jẹ́ abanijẹ́ ń fẹ̀sùn kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tọ̀sántòru