Iṣẹ́
Báwo ni iṣẹ́ ṣe lè mú kéèyàn láyọ̀?
Tẹ́nì kan bá já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, àwọn àǹfààní wo ló máa rí?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 16:16-23—Dáfídì mọ orin kọ dáadáa débi pé wọ́n yàn án láti máa kọrin fún ọba Ísírẹ́lì kára lè tu ọba náà
-
2Kr 2:13, 14—Hiramu-ábì já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà, torí náà Ọba Sólómọ́nì lò ó nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ńlá tó ṣe
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa ṣiṣẹ́ kára?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 24:10-21—Torí pé ó máa ń wu Rèbékà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tó sì tún jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ó ṣe ju ohun tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù béèrè
-
Flp 2:19-23—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún Tímótì torí pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ó sì tún nírẹ̀lẹ̀
-
Kí nìdí táwa Kristẹni kò fi gbọ́dọ̀ ya ọ̀lẹ?
Owe 13:4; 18:9; 21:25, 26; Onw 10:18
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Owe 6:6-11—Ọba Sólómọ́nì lo àpẹẹrẹ èèrà ká lè rí ìdí tó fi yẹ ká máa ṣiṣẹ́ kára, ká má sì ya ọ̀lẹ
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè rówó gbọ́ bùkátà ara wa?
Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè rówó gbọ́ bùkátà ìdílé wa?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Rut 1:16, 17; 2:2, 3, 6, 7, 17, 18—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé opó ni Rúùtù, ó ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó Náómì, ìyá ọkọ rẹ̀
-
Mt 15:4-9—Torí pé àwọn kan fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run, wọ́n kọ̀ láti tọ́jú òbí wọn, àmọ́ Jésù bá wọn wí
-
Tá a bá ṣiṣẹ́ kára tá a sì ní owó tàbí ohun ìní, kí ló yẹ ká máa ṣe?
Dípò ká máa lé ohun ìní ju bó ṣe yẹ lọ, irú èrò wo ló yẹ ká ní?
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ká lè gbọ́ bùkátà ara wa?
Mt 6:25, 30-32; Lk 11:2, 3; 2Kọ 9:10
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 31:3-13—Lábánì rẹ́ Jékọ́bù jẹ nígbà tó bá a ṣiṣẹ́, àmọ́ Jèhófà rí i pé Jékọ́bù máa ń ṣiṣẹ́ kára, torí náà ó bù kún un
-
Jẹ 39:1-6, 20-23—Jèhófà fìbùkún sí gbogbo iṣẹ́ tí Jósẹ́fù ṣe nígbà tó jẹ́ ẹrú nílé Pọ́tífárì àti nígbà tó wà lẹ́wọ̀n
-
Kí nìdí tí iṣẹ́ wa ò fi gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì sí wa ju ìjọsìn Ọlọ́run?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Lk 12:15-21—Jésù sọ àpèjúwe kan tó kọ́ wa pé kò bọ́gbọ́n mu láti jẹ́ kí owó àtàwọn nǹkan ìní ṣe pàtàkì sí wa ju àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà
-
1Ti 6:17-19—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ olówó pé kí wọ́n má ṣe máa fojú àbùkù wo àwọn ará tó kù, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé “kí wọ́n máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere”
-
Àwọn ìlànà wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa nípa iṣẹ́ tá a máa ṣe?
-
Ẹk 20:4; Iṣe 15:29; Ef 4:28; Ifi 21:8—Ṣé iṣẹ́ yìí ò ní mú kí n ṣe nǹkan tí Jèhófà ò fẹ́?
-
Ẹk 21:22-24; Ais 2:4; 1Kọ 6:9, 10; 2Kọ 7:1—Ṣé iṣẹ́ yìí ò ní mú káwọn míì máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, tíyẹn á sì mú kémi náà jẹ̀bi?
-
Ro 13:1-7; Tit 3:1, 2—Ṣé iṣẹ́ yìí ò ní mú kí n rú òfin ìjọba?
-
2Kọ 6:14-16; Ifi 18:2, 4—Ṣé iṣẹ́ yìí ò ní mú kí n máa lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké tàbí kí n máa tì í lẹ́yìn?
Máa ṣiṣẹ́ fún Jèhófà
Iṣẹ́ wo ló ṣe pàtàkì jù sí àwa Kristẹni?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi ohun tẹ́nì kan ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà wé ti ẹlòmíì?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Mt 25:14, 15—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé ó mọ ohun tágbára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ gbé lẹ́nì kọ̀ọ̀kan
-
Lk 21:2-4—Jésù sọ ohun tó fi hàn pé ó mọyì owó kékeré tí opó kan tó jẹ́ aláìní fi ṣètọrẹ
-
Ta ló ń fún wa lágbára tá a fi ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá fún wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
2Kọ 4:7; Ef 3:20, 21; Flp 4:13
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Ti 4:17—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Olúwa fún òun lágbára nígbà tóun nílò rẹ̀
-
Kí nìdí tá a fi máa ń láyọ̀ tá a bá ń fìtara ṣiṣẹ́ Jèhófà?