Ìtùnú
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú tá a bá rẹ̀wẹ̀sì
Àníyàn
Wo “Àníyàn”
Ìbínú; ìrunú
Ohun tó mú káwọn kan máa bínú ni pé wọ́n ní ìṣòro tó pọ̀ gan-an
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Rut 1:6, 7, 16-18; 2:2, 19, 20; 3:1; 4:14-16—Náómì pa dà láyọ̀ nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà, táwọn èèyàn ràn án lọ́wọ́, tóun náà sì ran àwọn míì lọ́wọ́
-
Job 42:7-16; Jem 5:11—Torí pé Jóòbù nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó fara da ìṣòro ẹ̀, Jèhófà sì bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀
-
Ìdí táwọn míì fi ń bínú ni pé àwọn kan hùwà àìdáa sí wọn
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 1:6, 7, 10, 13-16—Pẹ̀nínà hùwà àìdáa sí Hánà, Àlùfáà Àgbà Élì sì tún sọ pé ńṣe ló mutí yó, èyí mú kínú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an
-
Job 8:3-6; 16:1-5; 19:2, 3—Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ olódodo àṣelékè fẹ́ tù ú nínú, ńṣe ni wọ́n dá kún ìṣòro ẹ̀
-
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
1Sa 1:9-11, 18—Lẹ́yìn tí Hánà sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ fún Jèhófà, ara tù ú
-
Job 42:7, 8, 10, 17—Jèhófà bù kún Jóòbù lẹ́yìn tó dárí ji àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta
-
Kí ọkàn máa dáni lẹ́bi
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Ọb 22:8-13; 23:1-3—Lẹ́yìn tí wọ́n ka Òfin Mósè fún Ọba Jòsáyà àtàwọn èèyàn Júdà, wọ́n rí i pé àwọn ti ṣohun tó burú gan-an
-
Ẹsr 9:10-15; 10:1-4—Inú àlùfáà Ẹ́sírà àtàwọn èèyàn náà bà jẹ́ gan-an torí àwọn kan lára wọn ti ṣàìgbọràn sí Jèhófà bí wọ́n ṣe fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì
-
Lk 22:54-62—Inú àpọ́sítélì Pétérù bà jẹ́ gan-an lẹ́yìn tó sọ nígbà mẹ́ta pé òun ò mọ Jésù
-
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
2Kr 33:9-13, 15, 16—Mánásè wà lára àwọn ọba tó burú jù nílẹ̀ Júdà; àmọ́ nígbà tó ronú pìwà dà, Jèhófà dárí jì í
-
Lk 15:11-32—Jésù sọ àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá láti jẹ́ ká mọ̀ pé, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá pátápátá
-
Ó máa ń dùn wá táwọn èèyàn bá já wa kulẹ̀, tí wọ́n bá hùwà òdalẹ̀ sí wa tàbí tí wọ́n ṣe ohun míì tí kò dáa sí wa
Wo “Ìjákulẹ̀”
Ó máa ń dùn wá tá a bá ṣàṣìṣe tàbí tá a bá dẹ́ṣẹ̀
Wo “Ìjákulẹ̀”
Tá a bá ń ronú pé a ò já mọ́ nǹkan kan
Wo “Iyè Méjì”
Ìbẹ̀rù pé a ò ní lè ṣe iṣẹ́ kan tí wọ́n gbé fún wa
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Ẹk 3:12; 4:11, 12—Léraléra ni Jèhófà fi wòlíì Mósè lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ tóun gbé fún un láṣeyọrí
-
Jer 1:7-10—Jèhófà fi wòlíì Jeremáyà lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ tóun gbé fún un láṣeyọrí
-
Owú; ìlara
Wo “Owú”
Téèyàn ò bá lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ torí ìṣòro àìlera tàbí ọjọ́ ogbó
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Ọb 20:1-3—Ọba Hẹsikáyà sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ nígbà tó ṣàìsàn tó le gan-an tó sì fẹ́ kú
-
Flp 2:25-30—Inú Ẹpafíródítù bà jẹ́ gan-an torí pé àwọn ará tó wà ní Fílípì gbọ́ pé ara ẹ̀ ò yá, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn torí ó gbà pé òun ti já àwọn ará kulẹ̀
-
-
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
-
2Sa 17:27-29; 19:31-38—Ọba mọyì Básíláì gan-an, ó sì sọ fún un pé kó tẹ̀ lé òun lọ sí Jerúsálẹ́mù, àmọ́ Básíláì ti darúgbó ó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ torí náà kò tẹ̀ lé ọba
-
Sm 41:1-3, 12—Nígbà tí Ọba Dáfídì ń ṣàìsàn tó le gan-an, ó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́
-
Mk 12:41-44—Jésù gbóríyìn fún opó kan torí gbogbo ohun tó ní ló fi ṣètọrẹ
-
Ẹ̀dùn ọkàn tí kò lọ bọ̀rọ̀ torí ìwà àìdáa táwọn kan hù sí wa
Wo “Ìwà Àìdáa”
Ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì; ìpayà
Wo “Ìbẹ̀rù”
Inúnibíni
Wo “Inúnibíni”