Ìwà Títọ́
Kí ni ìwà títọ́?
Sm 18:23-25; 26:1, 2; 101:2-7; 119:1-3, 80
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Le 22:17-22—Jèhófà sọ pé tẹ́nì kan bá fẹ́ fi ẹran rúbọ, ara ẹran náà gbọ́dọ̀ “dá ṣáṣá,” kò sì gbọ́dọ̀ ní àbùkù kankan. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “dá ṣáṣá” jọ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ìwà títọ́,” èyí jẹ́ ká rí i pé tẹ́nì kan bá jẹ́ oníwà títọ́, ẹni náà á máa sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn ẹ̀
-
Job 1:1, 4, 5, 8; 2:3—Bí Jóòbù ṣe gbé ìgbé ayé ẹ̀ jẹ́ ká rí i pé tẹ́nì kan bá fẹ́ jẹ́ oníwà títọ́, ó gbọ́dọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà, kó máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, kó sì yẹra fún àwọn nǹkan tó lè múnú bí Jèhófà
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ oníwà títọ́?
Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ oníwà títọ́?
Tún wo Owe 27:11; 1Jo 5:3
Báwo la ṣe lè jẹ́ oníwà títọ́, ká sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀?
Tún wo Di 5:29; Ais 48:17, 18
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Job 31:1-11, 16-33—Jóòbù fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nínú gbogbo ohun tó ń ṣe, ó máa ń sá fún ìṣekúṣe, ó sì máa ń buyì kún àwọn èèyàn. Kì í bọ̀rìṣà, Jèhófà nìkan ló ń sìn, ó sì mọyì àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ju owó àtàwọn nǹkan ìní lọ
-
Da 1:6-21—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn tí kò sin Jèhófà ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ wà, wọ́n ń pa òfin Jèhófà mọ́, títí kan èyí tó sọ̀rọ̀ nípa irú oúnjẹ tí kò yẹ kí wọ́n jẹ
-
Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tí kò dáa léraléra, ṣé ó ṣì lè pa dà jẹ́ oníwà títọ́?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Ọb 9:2-5; Sm 78:70-72—Torí pé Ọba Dáfídì ronú pìwà dà, Jèhófà dárí jì í, kódà ó sọ pé Dáfídì rìn pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn
-
Ais 1:11-18—Jèhófà sọ pé àwọn èèyàn òun ti dá ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, àmọ́ ó ṣèlérí fún wọn pé òun máa dárí jì wọ́n tí wọ́n bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì yíwà pa dà
-