Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Tó Yẹ Kristẹni

Ìwà Tó Yẹ Kristẹni

Kí nìdí tó fi yẹ kí ìwà àwa Kristẹni bá ohun tá à ń kọ́ mu?

Àpẹẹrẹ ta ló yẹ káwa Kristẹni máa tẹ̀ lé?

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ táwa Kristẹni bá ń fi ìlànà Ọlọ́run sílò nígbèésí ayé wa?

Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sá fún ìwà tí kò dáa?

Owe 4:23-27; Jem 1:14, 15

Tún wo Mt 5:28; 15:19; Ro 1:26, 27; Ef 2:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 3:1-6—Éfà gba èrò burúkú láyè, ìyẹn sì mú kó hùwà tí kò dáa

    • Joṣ 7:1, 4, 5, 20-25—Ákánì kó bá ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tó ṣàìgbọràn sí Jèhófà

Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa hùwà tó dáa?

Ro 12:2; Ef 4:22-24; Flp 4:8; Kol 3:9, 10

Tún wo Owe 1:10-19; 2:10-15; 1Pe 1:14-16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 39:7-12—Ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ kí Jósẹ́fù bá òun sùn, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà

    • Job 31:1, 9-11—Jóòbù pinnu pé òun ò ní tẹjú mọ́ obìnrin míì yàtọ̀ sí ìyàwó òun

    • Mt 4:1-11—Sátánì dán Jésù wò, àmọ́ Jésù borí gbogbo àdánwò náà

Àwọn ìwà burúkú wo ló yẹ káwa Kristẹni máa sá fún?

Wo “Ìwà Burúkú

Àwọn àṣà burúkú wo ló yẹ káwa Kristẹni máa sá fún?

Wo “Àṣà Burúkú

Àwọn ìwà rere wo ló yẹ káwa Kristẹni máa hù?

Àánú

Wo “Àánú

Èso ti ẹ̀mí

Wo “Èso Tẹ̀mí

Ẹ̀mí ọ̀làwọ́

Wo “Ọ̀làwọ́

Gbà pé àwọn míì sàn jù ẹ́ lọ

Wo “Ìrẹ̀lẹ̀

Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

Ìbẹ̀rù Jèhófà

Job 28:28; Sm 33:8; Owe 1:7

Tún wo Sm 111:10

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ne 5:14-19—Torí pé Nehemáyà bẹ̀rù Jèhófà, nígbà tó jẹ́ gómìnà, kò rẹ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ

    • Heb 5:7, 8—Jésù ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀

Ìdúróṣinṣin

Ìfaradà; ìforítì; dúró gbọn-in

Mt 24:13; Lk 21:19; 1Kọ 15:58; Ga 6:9; Heb 10:36

Tún wo Ro 12:12; 1Ti 4:16; Ifi 2:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Heb 12:1-3—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àpẹẹrẹ Jésù láti gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ní ìfaradà

    • Jem 5:10, 11—Jémíìsì sọ̀rọ̀ nípa bí Jóòbù ṣe ní ìfaradà tí Jèhófà sì bù kún un

Ìfẹ́ Jèhófà ni kó o fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ

Mt 6:33; Ro 8:5; 1Kọ 2:14-16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Heb 11:8-10—Torí pé Ábúráhámù gbà pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan, ó ṣe tán láti máa gbé inú àgọ́ nílẹ̀ àjèjì

    • Heb 11:24-27—Àwọn ìpinnu tí wòlíì Mósè ṣe láyé ẹ̀ fi hàn pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà

Ìfọkànsin Ọlọ́run

1Ti 6:6; 2Pe 2:9; 3:11

Tún wo 1Ti 5:4; 2Ti 3:12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 10:1-7—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kèfèrí ni Kọ̀nílíù, Jèhófà kíyè sí i pé ó jẹ́ ẹni tó ní ìfọkànsìn, tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tó máa ń gbàdúrà gan-an, tó sì tún jẹ́ ọ̀làwọ́

    • 1Ti 3:16—Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá kan pé kéèyàn ní ìfọkànsin Ọlọ́run

Ìgboyà

Wo “Ìgboyà

Ìgbọràn

Wo “Ìgbọràn

Ìrẹ̀lẹ̀; ìmọ̀wọ̀n ara ẹni

Wo “Ìrẹ̀lẹ̀

Ìtẹ́lọ́rùn

Wo “Ìtẹ́lọ́rùn

Ìtẹríba

Ef 5:21; Heb 13:17

Tún wo Jo 6:38; Ef 5:22-24; Kol 3:18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 22:40-43—Jésù máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ nígbà gbogbo, kódà nígbà tí kò bá rọrùn rárá

    • 1Pe 3:1-6—Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún ọkọ wọn bíi ti Sérà

Ìwà Mímọ́

2Kọ 11:3; 1Ti 4:12; 5:1, 2, 22; 1Pe 3:1, 2

Tún wo Flp 4:8; Tit 2:3-5

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 39:4-12—Léraléra ni ìyàwó Pọ́tífárì ń fi ìṣekúṣe lọ Jósẹ́fù, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà fún un, torí ó fẹ́ jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run

    • Sol 4:12; 8:6—Ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì jẹ́ olóòótọ́ sí olólùfẹ́ rẹ̀, ó jẹ́ mímọ́ torí kò ṣèṣekúṣe

Ìwà títọ́

Wo “Ìwà Títọ́

Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ẹ́ lógún

Jẹ́ olóòótọ́

Jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo

Lk 16:10

Tún wo Jẹ 6:22; Ẹk 40:16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Da 1:3-5, 8-20—Wòlíì Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́ta ṣègbọràn sí ohun tí Òfin Mósè sọ nípa irú oúnjẹ tó yẹ kí wọ́n jẹ àtèyí tí kò yẹ kí wọ́n jẹ

    • Lk 21:1-4—Jésù gbóríyìn fún opó aláìní kan tó fi owó tó kéré gan-an sínú àpótí ọrẹ, torí ohun tó ṣe yẹn fi hàn pé ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára

Má ṣe àṣejù

Máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì

Onw 4:9, 10; 1Kọ 16:16; Ef 4:15, 16

Tún wo Sm 110:3; Flp 1:27, 28; Heb 13:17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Kr 25:1-8—Ọba Dáfídì ṣètò àwọn akọrin àtàwọn tó ń lo ohun èlò ìkọrin fún ìjọsìn Jèhófà, gbogbo wọn gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ wọn dáadáa

    • Ne 3:1, 2, 8, 9, 12; 4:6-8, 14-18, 22, 23; 5:16; 6:15—Nígbà táwọn èèyàn Jèhófà ń kọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù, Jèhófà bù kún wọn bí wọ́n ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n parí iṣẹ́ náà láàárín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta (52) péré

Máa fúnni níṣìírí; máa gbéni ró

Ais 35:3, 4; Ro 1:11, 12; Heb 10:24, 25

Tún wo Ro 15:2; 1Tẹ 5:11

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 23:15-18—Nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù ń wá bó ṣe máa pa Dáfídì, Jónátánì fún Dáfídì níṣìírí

    • Iṣe 15:22-31—Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìgbìmọ̀ olùdarí fi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn ìjọ, àwọn lẹ́tà náà sì fún àwọn ará níṣìírí

Máa ṣe aájò àlejò

Wo “Aájò Àlejò

Máa sòótọ́

Ojú àánú

Wo “Ojú Àánú

Ọ̀rọ̀ onínúure, ọ̀rọ̀ rere

Owe 12:18; 16:24; Kol 4:6; Tit 2:6-8

Tún wo Owe 10:11; 25:11; Kol 3:8

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 45:2—Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Mèsáyà jẹ́ ká mọ̀ pé Ọba tí Jèhófà yàn á máa sọ ọ̀rọ̀ rere

    • Lk 4:22—Nígbà táwọn èèyàn gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára tí Jésù sọ, ó wú wọn lórí gan-an

Ọ̀wọ̀

Flp 2:3, 4; 1Pe 3:15

Tún wo Ef 5:33; 1Pe 3:1, 2, 7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Nọ 14:1-4, 11—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò bọ̀wọ̀ fún wòlíì Mósè àti Áárónì tó jẹ́ àlùfáà àgbà, àmọ́ lójú Jèhófà, òun gangan ni wọn ò bọ̀wọ̀ fún

    • Mt 21:33-41—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká mọ nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn wòlíì Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀

Ṣe tán láti dárí jini

Wo “Ìdáríjì

Tẹpá mọ́ṣẹ́; tọkàntọkàn

Wo “Iṣẹ́

Tẹra mọ́ àdúrà gbígbà

Wà létòlétò

Yẹra fún ojúsàájú