Ìyá
Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí ìyá máa ṣe?
Owe 31:17, 21, 26, 27; Tit 2:4
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 21:8-12—Nígbà tí Sérà kíyè sí i pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ọmọ òun ṣe yẹ̀yẹ́, Sérà ní kí Ábúráhámù lé Íṣímáẹ́lì lọ kó lè dáàbò bo ọmọ ẹ̀
-
1Ọb 1:11-21—Nígbà tí Bátí-ṣébà gbọ́ pé Ádóníjà ń gbìyànjú láti fi ara ẹ̀ jọba, Bátí-ṣébà lọ sọ fún Ọba Dáfídì pé kó tètè fi Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ jọba kó lè dáàbò bò ó
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwa ọmọ máa jẹ́ onígbọràn sáwọn ìyá wa, ká sì máa bọlá fún wọn?
Ẹk 20:12; Di 5:16; 27:16; Owe 1:8; 6:20-22; 23:22
Tún wo 1Ti 5:9, 10
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Pe 3:5, 6—Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé torí pé Sérà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó dà bí ìyá fún àwọn ọmọbìnrin tó pọ̀
-
Owe 31:1, 15, 21, 28—Ìyá Ọba Lémúẹ́lì fún ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n nípa ìgbéyàwó, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ẹni iyì làwọn obìnrin àtàwọn ìyá jẹ́
-
2Ti 1:5; 3:15—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún Yùníìsì ìyá Tímótì, torí pé ó kọ́ ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti kékeré, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Kristẹni
-