Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́
Ṣé ẹ̀yà tá a jẹ́, inú ìdílé tá a ti wá tàbí bá a ṣe lówó tó ló mú ká ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run?
Iṣe 17:26, 27; Ro 3:23-27; Ga 2:6; 3:28
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jo 8:31-40—Àwọn Júù kan ń fi Ábúráhámù yangàn pé baba ńlá àwọn ni; àmọ́, Jésù bá wọn wí torí pé wọn ò fìwà jọ Ábúráhámù rárá
Ṣó yẹ ká máa fojú tí kò dáa wo àwọn tí kìí ṣe ẹ̀yà wa tàbí tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè míì?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jon 4:1-11—Jèhófà fi sùúrù kọ́ wòlíì Jónà pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tiẹ̀ yàtọ̀ sí tàwọn ará Nínéfè, ó yẹ kó fàánú hàn sí wọn
Iṣe 10:1-8, 24-29, 34, 35—Àpọ́sítélì Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kóun máa rò pé àwọn tí kì í ṣe Júù jẹ́ aláìmọ́, torí náà ó ran Kọ̀nílíù àti ìdílé ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Kristẹni. Àwọn sì lẹni àkọ́kọ́ tí kì í ṣe Júù tó di Kristẹni
Ṣó yẹ káwọn Kristẹni tó jẹ́ olówó máa rò pé àwọn ṣe pàtàkì ju àwọn ará tó kù lọ tàbí kí wọ́n máa retí pé káwọn ará kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀?
Tẹ́nì kan bá jẹ́ alàgbà, ṣó yẹ kó ka ara ẹ̀ sí pàtàkì ju àwọn ará tó kù lọ tàbí kó máa le koko mọ́ wọn?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Di 17:18-20—Jèhófà kìlọ̀ fáwọn ọba tó jẹ ní Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ rò pé àwọn dáa ju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù lọ, torí pé lójú Jèhófà arákùnrin ni wọ́n jẹ́ sí ọba
Mk 10:35-45—Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wí torí pé wọ́n máa ń wá bí wọ́n ṣe máa jẹ ọ̀gá lé ara wọn lórí. (Tún wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 10:42, nwtsty-E, “lord it over them”)
Àwọn wo ni inú Ọlọ́run dùn sí?
Ṣó yẹ káwọn Kristẹni dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tó máa ń fẹ́ yí òfin ìjọba pa dà?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jo 6:14, 15—Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn fẹ́ fi jọba kó lè bá wọn yanjú àwọn ìṣòro tó wà lórílẹ̀-èdè wọn, àmọ́ kò gbà