Orúkọ Oyè
Ṣó yẹ káwa Kristẹni máa lo orúkọ oyè fáwọn tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Lk 18:18, 19—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn dáadáa ni Jésù, kò gbà káwọn èèyàn pe òun ní “Olùkọ́ Rere,” torí ó gbà pé Jèhófà nìkan lẹ́ni rere
Kí nìdí táwa Kristẹni kì í fi í pe àwọn tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ láwọn orúkọ oyè bíi “Baba” tàbí “Aṣáájú”?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 23:9-12—Jésù sọ pé a ò gbọ́dọ̀ lo àwọn orúkọ oyè bíi “Baba” tàbí “Aṣáájú” nínú ìjọsìn wa
1Kọ 4:14-17—Bíi bàbá ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn, síbẹ̀ kò sí ẹnì kankan tó pè é ní Baba wa Pọ́ọ̀lù tàbí orúkọ oyè míì
Kí nìdí tó fi bá a mu pé káwa Kristẹni máa ṣe bí ọmọ ìyá, ká sì máa pe ara wa ní arákùnrin àti arábìnrin?
Tún wo Iṣe 12:17; 18:18; Ro 16:1
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 12:46-50—Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó ń sin Jèhófà ni arákùnrin àti arábìnrin òun
Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa lo orúkọ oyè fáwọn aláṣẹ ìjọba, olóṣèlú, adájọ́, àtàwọn aláṣẹ míì?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Iṣe 26:1, 2, 25—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo orúkọ oyè fáwọn aláṣẹ ìjọba bí Ágírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì