ORÍ KẸTÀDÍNLÓGÚN
Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run?
-
Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa?
-
Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń dáhùn àdúrà wa?
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká ka àdúrà sí àǹfààní ńlá, kí sì nìdí tá a fi ní láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọni nípa rẹ̀?
ILẸ̀ ayé kéré jọjọ tá a bá fi wé ọ̀run tó lọ salalu. Kódà, gbogbo orílẹ̀-èdè ayé kò ju ẹ̀kán omi kan látinú korobá lọ lójú Ọlọ́run tó jẹ́ “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 115:15; Aísáyà 40:15) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́. Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́.” (Sáàmù 145:18, 19) Ìwọ tiẹ̀ ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ná! Òyígíyigì Ẹlẹ́dàá wà nítòsí wa yóò sì gbọ́ wa tá a bá “ké pè é ní òótọ́.” O ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà!
2 Àmọ́, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ gbà á lọ́nà tó fẹ́. Báwo la ṣe lè gbàdúrà lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ tá ò bá mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àdúrà? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àdúrà, nítorí pé àdúrà ni yóò jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ?
3. Kí ni ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà?
3 Ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà ni pé, òun fúnra rẹ̀ ló ní ká máa gbàdúrà sí òun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wá Fílípì 4:6, 7) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kọ ètò onínúure tí Alákòóso Tó Gá Jù Lọ láyé àti lọ́run ṣe fún wa yìí!
níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (4. Báwo ni gbígbàdúrà sí Jèhófà déédéé ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ lágbára?
4 Ìdí mìíràn tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé ni pé, ó jẹ́ ọ̀nà kan tá a fi lè jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ lágbára. Tó bá jẹ́ pé ojúlówó ọ̀rẹ́ làwọn kan ń bára wọn ṣe, tí kì í ṣe ọ̀rẹ́ dábẹ̀-n-yànkọ, kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ gba nǹkan lọ́wọ́ ara wọn nìkan ni wọn yóò máa bára wọn sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ ara wọn, bí wọ́n bá sì ṣe ń bá ara wọn sọ ohun tó wà lọ́kàn kálukú wọn ni okùn ọ̀rẹ́ wọn á túbọ̀ máa lágbára. Àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà fi àwọn nǹkan kan jọ èyí. Nínú ìwé yìí, o ti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀pọ̀ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Jèhófà, àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. O ti mọ̀ pé ẹni gidi ni. Àdúrà jẹ́ àǹfààní Jákọ́bù 4:8.
tó o fi lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Bàbá rẹ ọ̀run. Bó o bá ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà.—KÍ LA GBỌ́DỌ̀ ṢE KÍ ỌLỌ́RUN TÓ LÈ GBỌ́ ÀDÚRÀ WA?
5. Kí ló fi hàn pé gbogbo àdúrà kọ́ ni Jèhófà ń gbọ́?
5 Ǹjẹ́ gbogbo àdúrà ni Jèhófà ń gbọ́? Wo ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ nígbà ayé wòlíì Aísáyà. Ó ní: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Ìyẹn fi hàn pé àwọn nǹkan kan wà tó jẹ́ pé tá a bá ń ṣe wọ́n, Ọlọ́run ò ní gbọ́ àdúrà wa. Nítorí náà, àwọn ohun kan wà tó pọn dandan kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa.
6. Kí ni ohun àkọ́kọ́ tí a gbọ́dọ̀ ní kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa, báwo la sì ṣe lè ní in?
6 Ohun àkọ́kọ́ tó pọn dandan ni pé ká ní ìgbàgbọ́. (Ka Máàkù 11:24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti [wu Ọlọ́run] dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ṣùgbọ́n, tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tá a mọ̀ kò ju pé Ọlọ́run wà, tí a kò mọ̀ ju pé ó máa ń gbọ́ àdúrà àti pé ó ń dáhùn àdúrà, a ò tíì ní ojúlówó ìgbàgbọ́ o. Ìṣe wa ló máa fi hàn bóyá a ní ojúlówó ìgbàgbọ́ tàbí a kò ní. A gbọ́dọ̀ fi hàn kedere nínú àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́ pé a ní ìgbàgbọ́.—Jákọ́bù 2:26.
7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún Jèhófà nígbà tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà? (b) Báwo la ṣe lè fi ìrẹ̀lẹ̀ àti òtítọ́ inú gbàdúrà sí Ọlọ́run?
7 Jèhófà tún fẹ́ kéèyàn fi ìrẹ̀lẹ̀ àti òtítọ́ inú gbàdúrà. Àbí kò yẹ ká rẹ ara wa sílẹ̀ tá a bá ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀? Táwọn èèyàn bá láǹfààní láti bá ọba ìlú tàbí ààrẹ orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni wọ́n máa ń sọ ọ́, nítorí wọ́n mọ̀ pé ipò gíga ló wà. O ò rí i pé ó yẹ ká bu ọ̀wọ̀ tó pọ̀ jùyẹn lọ ní Sáàmù 138:6) Ó ṣe tán, òun ni “Ọlọ́run Olódùmarè.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Ó yẹ kí ọ̀nà tá à ń gbà gbàdúrà sí Ọlọ́run fi hàn pé a gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé, ó jù wá lọ fíìfíì. Irú ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò mú ká máa fi òtítọ́ inú gbàdúrà látọkàn wá, a ò sì ní máa sọ ohun kan náà lásọtúnsọ ní gbogbo ìgbà.—Mátíù 6:7, 8.
ìlọ́po ìlọ́po fún Jèhófà nígbà tá a bá ń gbàdúrà! (8. Báwo la ṣe lè ṣe ohun tó bá àdúrà tá à ń gbà mu?
8 Ohun mìíràn tó pọn dandan kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa ni pé ká máa ṣe ohun tó bá àdúrà tá à ń gbà mu. Jèhófà retí pé ká sa gbogbo ipá wa láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tá a fàdúrà béèrè. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá gbàdúrà pé, “Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní,” a ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ hẹ iṣẹ́ yòówù tá a bá ń ṣe; àṣekára la gbọ́dọ̀ ṣe é. (Mátíù 6:11; 2 Tẹsalóníkà 3:10) Tá a bá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí kùdìẹ̀-kudiẹ kan, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tàbí ipòkípò tó lè dán wa wò láti hùwàkiwà. (Kólósè 3:5) Ní báyìí, a ti mọ àwọn ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa. Síbẹ̀, ó ṣì kù àwọn ìbéèrè kan lórí ọ̀rọ̀ àdúrà tó yẹ ká rí ìdáhùn sí.
ÌDÁHÙN SÁWỌN ÌBÉÈRÈ KAN NÍPA ÀDÚRÀ
9. Ta la gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí, nípasẹ̀ ta sì ni?
9 Ta ló yẹ ká gbàdúrà sí? “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run” ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí. (Mátíù 6:9) Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run nìkan la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí. Ṣùgbọ́n Jèhófà fẹ́ ká mọ ipò tí Jésù Kristi, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wà. A kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Karùn-ún pé Ọlọ́run rán Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé láti rà wá pa dà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:12) Òun ni Àlùfáà Àgbà àti Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn. (Jòhánù 5:22; Hébérù 6:20) Abájọ tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé nípasẹ̀ Jésù ni ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ sì sọ ni pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa, òun nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ gbà á sí nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀.
10. Kí nìdí tí kò fi pọn dandan ká wà ní ipò kan pàtó nígbà tá a bá ń gbàdúrà?
10 Ǹjẹ́ dandan ni kéèyàn kúnlẹ̀ tàbí kó dúró tàbí kó wà ní ipò mìíràn kan pàtó nígbà tó bá ń gbàdúrà? Rárá o. Jèhófà ò fi dandan lé e pé a gbọ́dọ̀ wà ní ipò kan pàtó tá a bá ń gbàdúrà. Bíbélì fi kọ́ni pé oríṣiríṣi ipò lèèyàn lè wà nígbà tó bá ń gbàdúrà. Èèyàn lè jókòó, ó lè tẹrí ba, ó lè kúnlẹ̀, ó sì lè dúró. (1 Kíróníkà 17:16; Nehemáyà 8:6; Dáníẹ́lì 6:10; Máàkù 11:25) Pé a jókòó, a tẹrí ba, a kúnlẹ̀ tàbí a dúró kọ́ ló ṣe pàtàkì, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kéèyàn fi ọkàn tó dára gbàdúrà. Kódà, lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ pàápàá tàbí nígbà tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, a lè gbàdúrà àgbàsínú níbikíbi tá a bá wà. Jèhófà yóò gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó wà nítòsí lè má mọ̀ pé à ń gbàdúrà.—Nehemáyà 2:1-6.
11. Àwọn ọ̀ràn ara wa wo la lè gbàdúrà nípa rẹ̀?
11 Kí la lè gbàdúrà nípa rẹ̀? Bíbélì ní: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó [ìyẹn Jèhófà] ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Nítorí náà, a lè gbàdúrà nípa ohunkóhun tó bá bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu. Ǹjẹ́ Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà nípa àwọn nǹkan tó jẹ́ tara wa? Bẹ́ẹ̀ ni, ó fẹ́ bẹ́ẹ̀! Téèyàn bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ńṣe ló dà bí kó máa bá ọ̀rẹ́ kòríkòsùn sọ̀rọ̀. Kò yẹ ká fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ńṣe ló yẹ ‘ká tú ọkàn wa jáde’ sí Ọlọ́run. (Sáàmù 62:8) Kò burú tá a bá ní kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, nítorí pé ẹ̀mí mímọ́ ni yóò ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tó tọ́. (Lúùkù 11:13) A lè ní kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. A tún lè ní kó fún wa lágbára ká lè fara da àwọn ìṣòro wa. (Jákọ́bù 1:5) Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a ní láti tọrọ ìdáríjì ní ọlá ẹbọ Kristi. (Éfésù 1: 3, 7) Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ara wa nìkan kọ́ ló yẹ ká máa gbàdúrà nípa rẹ̀ o. Ó yẹ ká máa mẹ́nu kan àwọn ẹlòmíràn tá a bá ń gbàdúrà, ìyẹn àwọn ẹbí wa àtàwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa.—Ìṣe 12:5; Kólósè 4:12.
12. Báwo la ṣe lè fi àwọn ohun tó kan Bàbá wa ọ̀run ṣáájú nínú àdúrà wa?
12 Àwọn ohun tó kan Jèhófà ló yẹ ká fi ṣáájú nígbà tá a bá ń gbàdúrà. Dájúdájú, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí gbogbo ohun rere tó ń ṣe fún wa. (1 Kíróníkà 29:10-13) Nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó wà nínú Mátíù 6:9-13, Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tá a sọ di mímọ́, ìyẹn ni pé kó di ohun táwọn èèyàn mọ̀ sí ohun mímọ́. (Ka.) Ohun tí Jésù mẹ́nu kàn tẹ̀ lé e ni pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di èyí tá à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run. Ìgbà tó sọ àwọn ohun pàtàkì wọ̀nyí tó kan Jèhófà tán ló tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kan àwọn ohun tó jẹ́ tara ẹni. Táwa náà bá fi Ọlọ́run sí ipò tó ṣe pàtàkì jù nínú àdúrà wa, a óò fi hàn pé ọ̀ràn ara wa nìkan kọ́ ló jẹ́ wa lógún.
13. Kí ni Bíbélì ò sọ nípa àdúrà wa?
13 Báwo ló ṣe yẹ kí àdúrà wa gùn tó? Bíbélì ò sọ bí àdúrà tá a dá nìkan gbà tàbí èyí tẹ́nì kan gbà láwùjọ ṣe gbọ́dọ̀ gùn tó. Àdúrà tá a bá gbà nígbà tá a fẹ́ jẹun lè ṣe ṣókí, ó sì lè gùn nígbà tá a bá ń dá nìkan gbàdúrà, tá à ń sọ gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Jèhófà. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 15) Àmọ́, Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn, tí wọ́n máa ń gba àdúrà gígùn níbi táwọn èèyàn ti lè rí wọn. (Lúùkù 20:46, 47) Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sírú àdúrà yẹn. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí àdúrà tá a bá gbà wá látinú ọkàn wa. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó máa pinnu bí àdúrà wa yóò ṣe gùn tó ni irú ibi tá a bá wà àti ohun tá a nílò.
14. Kí ni ìyànjú tí Bíbélì gbà wá pé ká máa “gbàdúrà nígbà gbogbo” túmọ̀ sí, kí sì nìdí tíyẹn fi múnú wa dùn?
14 Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà lemọ́lemọ́ tó? Bíbélì Mátíù 26:41; Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà ní gbogbo ìṣẹ́jú àáyá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Bíbélì ń rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà déédéé, ìyẹn ni pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà gbogbo nítorí àwọn ohun rere tó ń ṣe fún wa. Bákan náà, ká máa sọ fún un pé kó tọ́ wa sọ́nà, kó sì fún wa lágbára. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Jèhófà ò sọ pé ó ní bí àdúrà wa ṣe gbọ́dọ̀ gùn tó tàbí pé ó ní bá a ṣe gbọ́dọ̀ gbàdúrà lemọ́lemọ́ tó? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la mọyì àǹfààní tá a ní láti máa gbàdúrà, a óò máa wáyè nígbà gbogbo láti gbàdúrà sí Bàbá wa ọ̀run.
gbà wá níyànjú pé ká máa “gbàdúrà nígbà gbogbo,” ká máa “ní ìforítì nínú àdúrà,” ká sì máa “gbàdúrà láìdabọ̀.” (15. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe “Àmín” níparí àdúrà tá a bá dá nìkan gbà àtèyí tẹ́nì kan bá gbà láwùjọ?
15 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe “Àmín” ní ìparí àdúrà? “Àmín” túmọ̀ sí “bẹ́ẹ̀ ni kó rí.” Àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó yẹ ká ṣe “Àmín” ní ìparí àdúrà tá a bá dá gbà àtèyí tẹ́nì kan bá gbà láwùjọ. (1 Kíróníkà 16:36; Sáàmù 41:13) Tá a bá ṣe “Àmín” níparí àdúrà tá a gbà fúnra wa, ńṣe là ń fi hàn pé òtítọ́ inú la fi gba àdúrà náà. Tá a bá sì ṣe “Àmín” níparí àdúrà tẹ́nì kan gbà láwùjọ, yálà a ṣe é sínú tàbí a ṣe é síta, ohun tá à ń sọ ni pé a fara mọ́ ohun tí ẹni tó gbàdúrà náà sọ.—1 Kọ́ríńtì 14:16.
BÍ ỌLỌ́RUN ṢE Ń DÁHÙN ÀDÚRÀ WA
16. Ìgbẹ́kẹ̀lé wo la lè ní nípa àdúrà?
16 Ǹjẹ́ Jèhófà ń dáhùn àdúrà ní ti gidi? Bẹ́ẹ̀ ni o! A ní ìdí tó yè kooro láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” máa ń dáhùn àdúrà tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ń fòtítọ́ inú gbà. (Sáàmù 65:2) Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà lè gbà dáhùn àdúrà wa.
17. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn áńgẹ́lì láti dáhùn àdúrà?
Hébérù 1:13, 14) Àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé, ìgbà tí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́ káwọn lè lóye Bíbélì ni kò pẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi lọ sọ́dọ̀ wọn. Irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ fẹ̀rí hàn pé àwọn áńgẹ́lì ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 14:6) Bákan náà, tá a bá gbàdúrà nípa ohun kan tá a nílò, ó lè jẹ́ pé Kristẹni kan ni Jèhófà yóò lò láti ràn wá lọ́wọ́.—Òwe 12:25; Jákọ́bù 2:16.
17 Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé láti dáhùn àdúrà. (18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fi dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
18 Jèhófà Ọlọ́run tún máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti dáhùn àdúrà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà. Tá a bá gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro, ó lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wa lágbára àti ìtọ́sọ́nà ká lè fara dà á. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ní ti àdúrà tá a máa ń gbà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, Bíbélì ló sábà máa ń lò láti fi dáhùn, nítorí pé Bíbélì ló fi ń tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. A lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí tá a bá ń ka àwọn ìtẹ̀jáde táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, irú bí ìwé yìí. Ó sì lè jẹ́ pé ní ìpàdé ìjọ la ti máa gbọ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó yẹ ká ronú lé lórí tàbí kí alàgbà kan sọ ohun kan tó lè ràn wá lọ́wọ́.—Gálátíà 6:1.
19. Tó bá dà bíi pé Ọlọ́run kò dáhùn àdúrà wa, kí ló yẹ ká rántí?
19 Tó bá dà bíi pé Jèhófà kò tètè dáhùn àdúrà wa, kò yẹ ká rò pé ńṣe ni kò lè dáhùn rẹ̀. Ohun tó yẹ ká rántí ni pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ àti ní àkókó tó bá tọ́ lójú rẹ̀. Ó mọ ohun tá a nílò àti bó ṣe lè pèsè rẹ̀ fún wa ju bí àwa alára ti mọ̀ lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ ká ‘máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, ká máa bá a nìṣó Lúùkù 11:5-10) Tá ò bá yé béèrè, Ọlọ́run á rí i pé a dìídì nílò ohun tá à ń béèrè ni, yóò sì tún fi hàn pé a ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Kò mọ síbẹ̀ o, Jèhófà lè dáhùn àdúrà wa lọ́nà tí kò ní hàn sí wa pé ó ti dáhùn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá gbà gbàdúrà sí i nípa ìṣòro kan tá a ní, ó lè má fòpin sí ìṣòro ọ̀hún, àmọ́ ó lè jẹ́ agbára tá a nílò ká lè fara dà á ló máa fún wa.—Ka Fílípì 4:13.
ní wíwá kiri, ká sì máa bá a nìṣó ní kíkànkùn.’ (20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo àǹfààní iyebíye tá a ní nípa gbígbàdúrà déédéé?
20 A mà dúpẹ́ o, pé Ẹlẹ́dàá gbogbo àgbáyé wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń gbàdúrà sí i lọ́nà tó tọ́! (Ka Sáàmù 145:18) Ẹ jẹ́ ká máa lo àǹfààní iyebíye tá a ní yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa gbígbàdúrà déédéé. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò sún mọ́ Jèhófà, Olùgbọ́ àdúrà.