ORÍ KEJÌLÁ
Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn
-
Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
-
Báwo lẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà ṣe kàn ọ́?
-
Irú àwọn ìwà wo ni Jèhófà ò fẹ́?
-
Báwo lo ṣe lè gbé ìgbé ayé tí yóò múnú Jèhófà dùn?
1, 2. Sọ díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí Jèhófà kà sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.
IRÚ èèyàn wo ni wàá fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Bóyá ni ò fi ní jẹ́ pé ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sáwọn ohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí, tí ìwà yín sì bára mu, ni wàá fẹ́ láti máa bá rìn, ó ṣe tán, ìwájọ̀wà ní í jẹ́ ọ̀rẹ́jọ̀rẹ́. Ẹni tó bá sì níwà ọmọlúwàbí, tó jẹ́ olóòótọ́ àti onínúure ẹ̀dá ni yóò wù ọ́ kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.
2 Kò tíì sígbà kan tí Ọlọ́run ò ní àwọn èèyàn tó yàn lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé ọ̀rẹ́ òun ni Ábúráhámù. (Ka Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23) Ọlọ́run sọ pé Dáfídì jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn” nítorí pé ó jẹ́ irú èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí. (Ìṣe 13:22) Bákan náà, lójú Jèhófà, “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” ni wòlíì Dáníẹ́lì.—Dáníẹ́lì 9:23.
3. Kí nìdí tí Jèhófà fi yan àwọn èèyàn kan lọ́rẹ̀ẹ́?
3 Kí nìdí tí Jèhófà fi ka Ábúráhámù, Dáfídì, àti Dáníẹ́lì sí ọ̀rẹ́ rẹ̀? Kíyè sí ohun tí Jèhófà sọ fún Ábúráhámù, pé: “Ìwọ ti fetí sí ohùn mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ìyẹn fi hàn pé àwọn tó bá fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe ni Jèhófà máa ń sún mọ́. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run yín, ẹ̀yin alára yóò sì di ènìyàn mi.” (Jeremáyà 7:23) Bí ìwọ náà bá ṣègbọràn sí Jèhófà, o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀!
JÈHÓFÀ MÁA Ń FÚN ÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ̀ LÓKUN
4, 5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn èèyàn rẹ̀?
4 Ronú nípa àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé Jèhófà ń wá àǹfààní “láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Báwo ni Jèhófà ṣe lè fi okun rẹ̀ hàn nítorí rẹ? Ọ̀nà kan tó lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú Sáàmù 32:8, tó sọ pé: “Èmi [Jèhófà] yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”
5 O ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé Jèhófà ń mójú tóni! Jèhófà yóò máa tọ́ ọ sọ́nà yóò sì máa fi ààbò rẹ̀ bò ọ́ bó o ti ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Ọlọ́run fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ìṣòro àti àdánwò tó bá dé bá ọ. (Ka Sáàmù 55:22) Nítorí náà, tó o ba sin Jèhófà tọkàntọkàn, ọkàn rẹ yóò balẹ̀ bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.” (Sáàmù 16:8; 63:8) Dájúdájú, Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé ìgbé ayé tó wù ú. Ṣùgbọ́n bíwọ náà ṣe mọ̀, ẹnì kan wà tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run, ọ̀tá yìí á sì fẹ́ dí ọ lọ́wọ́ kó o má bàa gbé ìgbé ayé tó wu Ọlọ́run.
Ẹ̀SÙN SÁTÁNÌ
6. Àríyànjiyàn wo ni Sátánì ṣe nípa àwa ènìyàn?
6 Orí Kọkànlá ìwé yìí ṣàlàyé bí Sátánì ṣe fẹ̀sùn kan Jèhófà nítorí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Sátánì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé òpùrọ́ ni, ó sì tún dọ́gbọ́n sọ pé kò dára bí Jèhófà ò ṣe jẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ti ṣẹ̀ tí àwọn ìran ọmọ wọn sì ti bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ láyé, Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn nípa ohun tó mú káwọn èèyàn máa sin Ọlọ́run. Sátánì sọ pé, “Kì í ṣe torí pé àwọn èèyàn fẹ́ràn Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń sìn ín.” Ó fi kún un pé, “Tí Ọlọ́run bá fàyè gba òun, òun lè mú kí ẹnikẹ́ni kẹ̀yìn sí Ọlọ́run.” Ìtàn Jóòbù fi hàn pé ohun tí Èṣù rò gan-an nìyẹn. Ta ni Jóòbù, báwo sì ni Èṣù ṣe fẹ̀sùn kàn án?
7, 8. (a) Kí ló mú kí Jóòbù yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó kù nígbà ayé rẹ̀? (b) Báwo ni Sátánì ṣe jiyàn nípa ohun tó mú kí Jóòbù máa sin Ọlọ́run?
7 Jóòbù gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [3,600] ọdún sẹ́yìn. Èèyàn rere ni, nítorí Jèhófà sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” (Jóòbù 1:8) Jóòbù ń ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí.
8 Sátánì jiyàn nípa ohun tó mú kí Jóòbù máa sin Ọlọ́run. Èṣù wí fún Jèhófà pé: “Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí [Jóòbù] ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? Ìwọ ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, àní ohun ọ̀sìn rẹ̀ ti tàn káàkiri ilẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”—Jóòbù 1:10, 11.
9. Kí ni Jèhófà ṣe sí ẹ̀sùn Sátánì, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
9 Ohun tí Sátánì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ ni pé ńṣe ni Jóòbù ń sin Ọlọ́run nítorí ohun tó máa rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Sátánì tún sọ pé tí Jóòbù bá rí àdánwò, kò ní sin Ọlọ́run mọ́. Kí ni Jèhófà ṣe sí ẹ̀sùn Sátánì yìí? Níwọ̀n bí ọ̀ràn náà ti jẹ mọ́ ohun tó mú kí Jóòbù máa sin Ọlọ́run, Jèhófà fàyè gba Sátánì pé kó dán Jóòbù wò. Ìyẹn ló máa fi hàn bóyá Jóòbù nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tàbí kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
SÁTÁNÌ DÁN JÓÒBÙ WÒ
10. Àwọn àdánwò wo ló dé bá Jóòbù, kí ló sì ṣe nígbà táwọn àdánwò náà dé bá a?
10 Kò pẹ́ rárá tí Sátánì fi dán Jóòbù wò lóríṣiríṣi ọ̀nà. Àwọn èèyàn jí díẹ̀ lára ẹran ọ̀sìn rẹ̀ gbé, wọ́n sì pa àwọn tó kù. Wọ́n tún pa ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ìyẹn sọ Jóòbù di ẹdun arinlẹ̀. Ohun ìbànújẹ́ mìíràn tó tún ṣẹlẹ̀ ni pé ìjì wó ilé pa gbogbo ọmọ mẹ́wàá tí Jóòbù bí. Àmọ́ báwọn Jóòbù 1:22.
ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yẹn ṣe le tó, “Jóòbù kò dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn.”—11. (a) Kí ni ẹ̀sùn kejì tí Sátánì fi kan Jóòbù, kí sì ni Jèhófà ṣe? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà Jóòbù nígbà tí àìsàn tó ń roni lára ṣe é?
11 Sátánì ò dẹ̀yìn lẹ́yìn Jóòbù o. Ohun tó rò ni pé bí Jóòbù bá tiẹ̀ lè fara da gbogbo ohun ìní tó pàdánù àti ikú àwọn ìránṣẹ́ àtàwọn ọmọ rẹ̀, kò sí bó ṣe lè fara da àìsàn. Ó ní tí àìsàn bá ṣe Jóòbù, kò ní sin Ọlọ́run mọ́. Ni Jèhófà bá fàyè gba Sátánì láti fi àìsàn tó ń ríni lára tó sì ń roni lára ṣe Jóòbù. Síbẹ̀, àìsàn yìí náà ò sọ Jóòbù dẹni tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.
12. Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn Sátánì?
12 Jóòbù ò mọ̀ pé Sátánì ló fa ìṣòro tó bá òun. Ó rò pé Ọlọ́run ló fa ìṣòro náà nítorí kò mọ̀ nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. (Jóòbù 6:4; 16:11-14) Síbẹ̀, Jóòbù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Jíjẹ́ tí Jóòbù jẹ́ olóòótọ́ fi hàn pé, irọ́ gbuu ni Èṣù ń pa nígbà tó sọ pé ohun tí Jóòbù ń rí gbà ló mú kó máa sin Ọlọ́run!
13. Nítorí pé Jóòbù jẹ́ olóòótọ́, kí ni Ọlọ́run ṣe fún un?
13 Bí Jóòbù ṣe jẹ́ olóòótọ́ mú kí Jèhófà lè dáhùn ẹ̀sùn àrífín tí Sátánì fi kan Jèhófà. Ọ̀rẹ́ Jèhófà ni Jóòbù lóòótọ́, Jèhófà sì san án lẹ́san nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́.—Jóòbù 42:12-17.
BÓ ṢE KÀN Ọ́
14, 15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jóòbù kan gbogbo èèyàn?
14 Jóòbù nìkan kọ́ ni Sátánì fẹ̀sùn kàn nípa ọ̀ràn jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run o. Ọ̀ràn yẹn kan ìwọ náà. A rí èyí kedere nínú Òwe 27:11, níbi tí Jèhófà ti sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn tí Jóòbù kú, fi hàn pé Sátánì ṣì ń ṣáátá Ọlọ́run ó sì ń fẹ̀sùn kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Tá a bá gbé ìgbé ayé tó múnú Jèhófà dùn, Jèhófà yóò lè dáhùn ẹ̀sùn Sátánì, ìyẹn á sì mú ọkàn Jèhófà yọ̀. Kí lo ti rí ìyẹn sí? Ǹjẹ́ inú rẹ ò ní dùn pé kí ìwọ náà jẹ́ ọ̀kan nínú awọn tó ń fi hàn pé irọ́ gbuu lẹ̀sùn tí Èṣù fi kan Ọlọ́run, àní bó bá máa gba pé kó o ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ pàápàá?
15 Sátánì sọ pé: ‘Ohun gbogbo tí ènìyàn bá ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.’ (Jóòbù 2:4) Kíyè sí i pé, “ènìyàn,” ni Sátánì mẹ́nu kàn nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn. Ìyẹn fi hàn pé gbogbo èèyàn ló fẹ̀sùn kàn, kì í ṣe Jóòbù nìkan. Kókó pàtàkì kan nìyẹn o. Sátánì jiyàn pé bóyá ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Èṣù yóò fẹ́ kó o ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run kó o sì pa ìgbé ayé òdodo tì nígbà tí ìṣòro bá dé. Ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà ṣe èyí?
16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì máa ń gbà mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run? (b) Báwo ni Sátánì ṣe lè lo àwọn ọ̀nà yìí láti mu ọ kẹ̀yìn sí Ọlọ́run?
16 Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí Kẹwàá, oríṣiríṣi nǹkan ni Sátánì ń lò láti fi mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Ó tún máa ń gbógun ti àwọn èèyàn “bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ìbátan rẹ àtàwọn mìíràn bá ta kò ọ́ pé o kò gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ tàbí pé o kò gbọ́dọ̀ fi ohun tó o kọ́ sílò, kó o mọ̀ pé Sátánì ló gbéṣe rẹ̀ dé yẹn o. * (Jòhánù 15:19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, Sátánì máa ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Sátánì lè fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tàn ọ́ jẹ kó o bàa lè jáwọ́ nínú bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé tó múnú Ọlọ́run dùn. Ó tún lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ, kó mú kó o máa rò pé ìwà rẹ ò dáa tó láti múnú Ọlọ́run dùn. (Òwe 24:10) Yálà Sátánì ń ṣe bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù” tàbí ó ń ṣe bí “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” ẹ̀sùn tó fi kàn ọ́ kò yí padà: Ó sọ pé tí àdánwò bá dé bá ọ, o kò ní sin Ọlọ́run mọ́. Gẹ́gẹ́ bí Jóòbù ṣe ṣe, báwo lo ṣe lè fi hàn pé irọ́ lẹ̀sùn yìí kó o sì fi hàn pé, dájúdájú, o jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run?
ṢÈGBỌRÀN SÁWỌN ÀṢẸ JÈHÓFÀ
17. Kí ni lájorí ìdí tó fi yẹ kó o ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà?
17 Tó o bá gbé ìgbé ayé tó múnú Ọlọ́run dùn, wàá lè fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn Sátanì. Ọ̀nà wo ni wàá gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Bíbélì dáhùn pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5) Bí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run ti ń pọ̀ sí i, ńṣe ni yóò máa wù ọ́ láti ṣe ohun tó ní kó o ṣe. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Tó o bá fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wàá rí i pé “àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.
18, 19. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣẹ Jèhófà? (Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Kórìíra Ohun Tí Jèhófà Kórìíra.”) (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní sọ pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ?
18 Kí ni àwọn àṣẹ Jèhófa? Àwọn àṣẹ rẹ̀ kan sọ irú àwọn ìwà tí kò yẹ ká máa hù. Bí àpẹẹrẹ, wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “ Kórìíra Ohun Tí Jèhófà Kórìíra.” Níbẹ̀, wàá rí àwọn ìwà tí Bíbélì sọ pé kò dára. Tó o bá kọ́kọ́ wò ó, o lè dà bí pé àwọn kan lára àwọn ìwà náà kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Àmọ́, tó o bá ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé àwọn òfin Jèhófà mọ́gbọ́n dání. Ó lè má rọrùn fún ọ láti ṣe ìyípadà nínú ìwà rẹ, ṣùgbọ́n tó o bá gbé ìgbé ayé tó múnú Ọlọ́run dùn, wàá ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀. (Aísáyà 48:17, 18) Kì í sì í ṣe ohun tí o kò le ṣe. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
19 Jèhófà kì í sọ pé ká ṣe ohun tá ò lè ṣe o. (Ka Diutarónómì 30:11-14) Ó mọ ohun tá a lè ṣe àtohun tá ò lè ṣe ju bí àwa alára ṣe mọ̀ ọ́n lọ. (Sáàmù 103:14) Láfikún, Jèhófà lè fún wa lágbára ká lè ṣègbọràn sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Kódà, Jèhófà lè fún ọ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kó o bàa lè fara da àdánwò. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò, ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.
BÓ O ṢE LÈ NÍ ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÓ Ń MÚNÚ ỌLỌ́RUN DÙN
20. Àwọn ànímọ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn wo ló yẹ kó o ní, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe pàtàkì?
20 Láìsì àní-àní, yàtọ̀ sí pé kó o yẹra fún àwọn ohun tí Róòmù 12:9) Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sáwọn ohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí tí ìwà yín sì bára mu ló máa wù ọ́ pé kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Ohun tó wu Jèhófà náà nìyẹn. Nítorí náà, kọ́ bí wàá ṣe máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wà nínú Sáàmù 15, níbi tá a ti kà nípa àwọn tí Jèhófà kà sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Ka Sáàmù 15:1-5) Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń fi ohun tí Bíbélì pè ní “èso ti ẹ̀mí” hàn. Ìyẹn ni “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
Jèhófà kórìíra, àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó yẹ kó o ṣe láti múnú Jèhófà dùn. O tún ní láti nífẹ̀ẹ́ ohun tó nífẹ̀ẹ́. (21. Kí ni wàá ṣe kó o lè ní àwọn ànímọ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn?
21 Ohun tí wàá ṣe kó o lè ní àwọn ànímọ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn ni pé kó o máa ka Bíbélì déédéé kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Tó o bá sì mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ní kó o ṣe, ìrònú rẹ yóò lè bá ti Ọlọ́run mu. (Aísáyà 30:20, 21) Bó o bá ṣe ń jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà máa lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní láti gbé ìgbé ayé tó ń múnú rẹ̀ dùn yóò máa lágbára sí i.
22. Kí ni wàá lè ṣe tó o bá ń gbé ìgbé ayé tó múnú Ọlọ́run dùn?
22 Gbígbé ìgbé ayé tó ń múnú Ọlọ́run dùn gba ìsápa o. Bíbélì fi ṣíṣe ìyípadà nínú ayé rẹ wé bíbọ́ ògbólógbòó ìwà tó o ní sílẹ̀ àti gbígbé ìwà tuntun wọ̀. (Kólósè 3:9, 10) Onísáàmù náà sọ nípa àwọn àṣẹ Jèhófà pé: “Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.” (Sáàmù 19:11) Ìwọ náà yóò rí i pé èrè jaburata ló wà nínú gbígbé ìgbé ayé tó ń múnú Ọlọ́run dùn. Tó o bá ń gbé ìgbé ayé tó múnú Jèhófà dùn, wàá lè fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn Sátánì, wàá sì jẹ́ kí inú Jèhófà dùn!
^ ìpínrọ̀ 16 Èyí ò túmọ̀ sí pé Sátánì ló ń fúnra rẹ̀ darí àwọn to bá ta kò ọ́. Àmọ́ Sátánì ni Ọlọ́run ayé yìí, gbogbo ayé ló sì wà lábẹ́ agbára rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe káwọn kan ta kò ọ́ níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ ò ti nífẹ̀ẹ́ sí gbígbé ìgbé ayé tó ń múnú Ọlọ́run dùn.