Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àtẹ Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Bíbélì

Àtẹ Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Bíbélì
  1. ‘Ní àtètèkọ́ṣe . . .’

  2. 4026 Ṣ.S.K. Ìṣẹ̀dá Ádámù

  3. 3096 Ṣ.S.K. Ádámù Ikú

  4. 2370 Ṣ.S.K. Omi bẹ̀rẹ̀ sí í ya lulẹ̀

  5. 2018 Ṣ.S.K. A bí Ábúráhámù

  6. 1943 Ṣ.S.K. Májẹ̀mú Ábúráhámù

  7. 1750 Ṣ.S.K. Wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú

  8. ṣáájú 1613 Ṣ.S.K. Àdánwò Jóòbù

  9. 1513 Ṣ.S.K. Ìjáde kúrò ní Íjíbítì

  10. 1473 Ṣ.S.K. Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì

  11. 1467 Ṣ.S.K. Wọ́n parí ṣíṣẹ́gun àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì nílẹ̀ Kénáánì

  12. 1117 Ṣ.S.K. A fòróró yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba

  13. 1070 Ṣ.S.K. Ọlọ́run bá Dáfídì dá májẹ̀mú Ìjọba

  14. 1037 Ṣ.S.K. Sólómọ́nì di ọba

  15. 1027 Ṣ.S.K. Wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù

  16. nǹkan bí 1020 Ṣ.S.K. Wọ́n parí kíkọ ìwé Orin Sólómọ́nì

  17. 997 Ṣ.S.K. A pín ìjọba Ísírẹ́lì sí méjì

  18. nǹkan bí 717 Ṣ.S.K. Àkójọ àwọn Òwe parí

  19. 607 Ṣ.S.K. Àwọn ọmọ ogun pa Jerúsálẹ́mù run; ìkónígbèkùn lọ sí Bábílónì bẹ̀rẹ̀

  20. 539 Ṣ.S.K. Kírúsì ṣẹ́gun ìlú Bábílónì

  21. 537 Ṣ.S.K. Àwọn Júù tó wà nígbèkùn padà sí Jerúsálẹ́mù

  22. 455 Ṣ.S.K. A tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́; ọ̀sẹ̀ 69 ti ọdún bẹ̀rẹ̀

  23. Lẹ́yìn 443 Ṣ.S.K. Málákì parí ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀

  24. nǹkan bí 2 Ṣ.S.K. Ìbí Jésù

  25. 29 S.K. A batisí Jésù àti Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run

  26. 31 S.K. Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá; ó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè

  27. 32 S.K. Jésù jí Lásárù dìde

  28. Nísàn 14, 33 S.K. Wọ́n kan Jésù mọ́gi (Oṣù Nísàn bọ́ sí apá kan oṣù March àti apá kan oṣù April)

  29. Nísàn 16 33 S.K. Ọlọ́run jí Jésù dìde

  30. Sífánì 6, 33 S.K. Pẹ́ńtíkọ́sì; ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ (Oṣù Sífánì bọ́ sí apá kan oṣù May àti apá kan oṣù June)

  31. 36 S.K. Kọ̀nílíù di Kristẹni

  32. nǹkan bí 47 sí 48 S.K. Ìrìn àjò àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù

  33. nǹkan bí 49 sí 52 S.K. Ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù

  34. nǹkan bí 52 sí 56 S.K. Ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù

  35. 60  sí 61 S.K. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù

  36. ṣáájú 62 S.K. Jákọ́bù, iyèkan Jésù kọ lẹ́tà rẹ̀

  37. 66 S.K. Àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí ìlú Róòmù

  38. 70 S.K. Àwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run

  39. nǹkan bí 96 S.K. Jòhánù kọ ìwé Ìṣípayá

  40. nǹkan bí 100 S.K. Ikú Jòhánù, ẹni tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì