Apá 9
Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Sọ Pé Àwọn Fẹ́ Ọba
Sọ́ọ̀lù, ọba tó kọ́kọ́ jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ya aláìgbọràn. Dáfídì ló jọba lẹ́yìn ẹ̀, Ọlọ́run sì bá a dá májẹ̀mú ìjọba kan tó máa wà títí láé
LẸ́YÌN tí sáà ti Sámúsìnì ti kọjá, Sámúẹ́lì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì àti onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sọ fún un lemọ́lemọ́ pé àwọn ń fẹ́ èèyàn tí yóò máa jọba lé àwọn lórí bíi tàwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ohun tí wọ́n béèrè yìí ṣe àfojúdi sí Jèhófà ni, síbẹ̀ Ó sọ fún Sámúẹ́lì pé kó ṣe ohun tí wọ́n ń fẹ́ fún wọn. Ọlọ́run yan ọkùnrin kan tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ìyẹn Sọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ọba. Kò pẹ́ kò jìnnà, Sọ́ọ̀lù Ọba di agbéraga àti aláìgbọràn. Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba ó sì sọ fún Sámúẹ́lì pé kó fòróró yan ẹlòmíì, ìyẹn ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dáfídì. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọdún ṣì máa kọjá kí Dáfídì tó di ọba.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Dáfídì ò tíì pọ́mọ ogún ọdún nígbà tó lọ wo àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n wà lára àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù. Ìdí gbogbo àwọn ọmọ ogun náà ti domi nítorí ọ̀kan lára àwọn tó wá bá wọn jagun, ìyẹn òmìrán kan tó ń jẹ́ Gòláyátì, ẹni tó ń ṣáátá wọn tó sì tún ń ṣáátá Ọlọ́run wọn. Èyí bí Dáfídì nínú, ó sì gbà láti jáde lọ bá òmìrán náà jagun. Lẹ́yìn tí ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ti mú kànnàkànnà kan, tó sì ṣa òkúta wẹ́wẹ́ díẹ̀, ó jáde lọ bá Gòláyátì, ẹni tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó mítà mẹ́ta, èyí tó lé ní ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án. Nígbà tí Gòláyátì fi Dáfídì ṣẹlẹ́yà, Dáfídì sọ fún òmìrán náà pé òun dira ogun jù ú lọ torí pé òun tọ̀ ọ́ wá lórúkọ Jèhófà Ọlọ́run! Nígbà tí òkúta kan ṣoṣo látinú kànnàkànnà Dáfídì wọnú agbárí Gòláyátì lọ, ó wó lulẹ̀ kòròbìtà. Dáfídì wá fa idà òmìrán náà yọ, ó sì fi gé orí rẹ̀. Ìpayà bá àwọn Filísínì tó kù, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìgboyà Dáfídì wú Sọ́ọ̀lù lórí débi pé ó fi ọ̀dọ́mọkùnrin náà ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àmọ́, kò pẹ́ tí àṣeyọrí Dáfídì fi mú kí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀ lọ́nà kíkorò. Dáfídì ní láti sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá fún ọ̀pọ̀ ọdún. Síbẹ̀, Dáfídì ń bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ nìṣó sí ọba tó ń gbìyànjú láti pa á, níwọ̀n bó ti mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ló yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba. Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù kú sójú ogun. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Dáfídì di ọba, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí.
“Èmi yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.”
Gẹ́gẹ́ bí ọba, ó wu Dáfídì gan-an pé kó kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà sọ fún un pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ ló máa kọ́ ọ. Sólómọ́nì sì lọmọ Dáfídì náà. Àmọ́, Ọlọ́run san èrè fún Dáfídì nípa bíbá a dá májẹ̀mú kan tó fani lọ́kàn mọ́ra. Ó ní àwọn ọba tó máa jẹ láti ìlà ìdílé rẹ̀ á pọ̀ ju ti ìdílé èyíkéyìí lọ. Ìlà ìdílé yìí náà sì ni Olùdáǹdè, tàbí Irú-ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí lọ́gbà Édẹ́nì á gbà wá. Ọmọ yẹn ló máa jẹ́ Mèsáyà, tó túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró,” tí Ọlọ́run yàn sípò. Jèhófà ṣèlérí pé Mèsáyà náà máa jẹ́ Alákòóso Ìjọba tó máa wà títí láé.
Dáfídì kún fún ọpẹ́ gidigidi, ó sì kó ohun èlò ìkọ́lé rẹpẹtẹ àtàwọn òkúta iyebíye jọ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì. Ó tún kọ ọ̀pọ̀ sáàmù tí Ọlọ́run mí sí. Lápá ìparí ìgbésí ayé Dáfídì, ó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ni ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wà lórí ahọ́n mi.”—2 Sámúẹ́lì 23:2.