Apá 20
Wọ́n Pa Jésù Kristi
Jésù dá ohun ìrántí tuntun kan sílẹ̀; Júdásì dà á, àwọn ọmọ ogun kàn án mọ́gi
LẸ́YÌN ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí Jésù ti ń wàásù tó sì ń kọ́ni, ó mọ̀ pé àkókò ikú òun ń sún mọ́. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ń gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á, àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn èèyàn tó gbà pé wòlíì ni lè dá rúkèrúdò sílẹ̀. Nígbà tó yá, Sátánì lo ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá, ìyẹn Júdásì Ísíkáríótù, láti hùwà ọ̀dàlẹ̀. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fún Júdásì ní ọgbọ̀n [30] owó fàdákà kó bàa lè da Jésù.
Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó kó àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ ó sì ṣayẹyẹ Ìrékọjá pẹ̀lú wọn. Lẹ́yìn tí Júdásì ti jáde, ó dá ohun ìrántí tuntun kan sílẹ̀, ìyẹn ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó gbàdúrà, ó sì gbé búrẹ́dì náà fún àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó kù. Ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Ó ṣe ohun kan náà pẹ̀lú ife tí wáìnì wà nínú rẹ̀, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi.”—Lúùkù 22:19, 20.
Jésù ní ohun púpọ̀ láti bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ó fún wọn ní àṣẹ tuntun pé kí wọ́n máa fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn síra wọn. Ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn dààmú nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbani nínú jẹ́ tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Jésù gbàdúrà kíkankíkan nítorí wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ orin ìyìn pa pọ̀, wọ́n sì jáde lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì ní alẹ́ yẹn.
Nínú ọgbà Gẹtisémánì, Jésù kúnlẹ̀ ó sì gbàdúrà kíkankíkan sí baba rẹ̀. Láìpẹ́, àwọn ọmọ ogun tó dìhámọ́ra bíi jàǹdùkú, àwọn àlùfáà àtàwọn mìíràn dé láti wá mú un. Júdásì tọ Jésù lọ, ó sì fi í hàn nípa fífẹnu kò ó lẹ́nu. Báwọn àpọ́sítélì ṣe rí i pé àwọn ọmọ ogun gbá Jésù mú báyìí, ńṣe ni wọ́n sá lọ.
Jésù fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run nígbà tó wà níwájú ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ òdì àti pé ikú tọ́ sí i. Lẹ́yìn náà ni wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà ìlú Róòmù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rí ẹ̀sùn kankan lòdì sí Jésù, ó fà á lé àwọn jàǹdùkú tí wọ́n ń fẹ́ kó kú náà lọ́wọ́.
Wọ́n mú Jésù lọ sí Gọ́gọ́tà, àwọn ọmọ ogun Róòmù sì kàn án mọ́gi níbẹ̀. Ohun ìyanu ṣẹlẹ̀, ọ̀sán dédé dòru. Lẹ́yìn náà, lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, Jésù kú, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan sì ṣẹlẹ̀. Wọ́n tẹ́ òkú rẹ̀ sínú ibojì tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta. Lọ́jọ́ kejì, àwọn àlùfáà fi èdìdì sí òkúta ibojì náà wọ́n sì fi àwọn ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Ṣé inú ibojì yẹn ni Jésù á máa wà? Rárá o. Iṣẹ́ ìyanu tó pabanbarì máa tó ṣẹlẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 15 Fún ìjíròrò lórí bí ikú Jésù ṣe níye lórí gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà, wo orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?