Awọn Ẹmi-eṣu Fi Eke Sọ Pe Awọn Oku Walaaye
Bibeli sọ pe Satani “ntan gbogbo aye jẹ.” (Iṣipaya 12:9) Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ kò fẹ ki a gba Bibeli, Ọrọ Ọlọrun gbọ́. Wọn gbiyanju lati mu ki awọn eniyan gbagbọ pe awọn oku walaaye nibikan ninu ilẹ akoso ẹmi. Ẹ jẹ ki a wo bi wọn ti nṣe eyi.
Isin Eke
Ọpọlọpọ isin nkọni pe gbogbo eniyan ni ọkàn ti o nrekọja lọ si ilẹ akoso ẹmi lẹhin iku ara iyara. Wọn sọ pe ara nku ṣugbọn ọkan kii kú. Ju bẹẹ lọ, wọn sọ pe ọkàn kò lè kú, pe o jẹ aileeku.
Ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun kò kọni bẹẹ. Bibeli fihan pe ọkan jẹ eniyan kan, kii ṣe ohun kan ti o wà ninu eniyan. Fun apẹẹrẹ, ni ṣiṣapejuwe iṣẹda Adamu, Bibeli sọ pe: “[Jehofa, NW] Ọlọrun sì fi erupẹ ilẹ mọ eniyan; o sì mi eemi iye si iho imu rẹ̀; eniyan sì di alaaye ọkàn.” (Jẹnẹsisi 2:7) Nitori naa kii ṣe pe a fun Adamu ni ọkàn; oun jẹ ọkàn kan.
A tun npe awọn ẹranko pẹlu ni ọkan.—Jẹnẹsisi 1:20, 21, 24, 30.
Niwọn bi ọrọ Bibeli naa “ọkàn” ti tumọsi eniyan naa funraarẹ, kò yẹ ki o ya wa lẹnu lati kẹkọọ pe ọkàn lè kú o sì nku. Iwe Mimọ sọ pe:
-
“Ọkàn ti o ba ṣẹ, oun yoo ku.”—Esekiẹli 18:4.
-
“Samsoni si nbaa lọ lati wi pe: ‘Jẹ ki ọkàn mi ku pẹlu awọn Filistini.’”—Onidaajọ 16:30, NW.
-
“O ha bofinmu ni ọjọ isinmi lati ṣe iṣẹ daradara tabi lati ṣe iṣẹ buburu, lati gbala tabi lati pa ọkàn kan?”—Maaku 3:4, NW.
Awọn ẹsẹ iwe mimọ miiran fihan pe a le pa ọkàn run (Jẹnẹsisi 17:14), fi idà kọlù ú (Jọṣua 10:37), fi èémí dù ú (Joobu 7:15), o sì lè rì (Jona 2:5). Nipa bẹẹ, ọkàn nku.
Bi iwọ ba ka Bibeli lati páálí dé páálí, iwọ ko le ri ọrọ naa “aileeku ọkàn.” Ọkàn eniyan kii ṣe ẹmi. Ẹkọ aileeku ọkàn kii ṣe ẹkọ Bibeli. O jẹ ẹkọ Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀. Jehofa koriira gbogbo irọ́ isin.—Owe 6:16-19; 1 Timoti 4:1, 2.
Awọn Abẹmiilo
Ọna miiran ti Satani ngba ṣi awọn eniyan lọna ni nipasẹ awọn abẹmiilo. Abẹmiilo ni ẹnikan ti o lè gba isọfunni ni taarata lati ilẹ ọba ẹmi. Ọpọlọpọ awọn eniyan, titikan awọn abẹmiilo funraawọn paapaa, gbagbọ pe awọn isọfunni wọnyi wá lati ọdọ ẹmi awọn òkú. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti ríi ninu Bibeli, eyi kò ṣeeṣe.—Oniwaasu 9:5, 6, 10.
Lati ọdọ ta ni, nigba naa, ni awọn isọfunni wọnyi ti nwa? Awọn ẹmi-eṣu funraawọn! Awọn ẹmi-eṣu lè ṣakiyesi ẹnikan nigba ti o ṣì walaaye; wọn mọ bi ẹnikan ṣe nsọrọ, wọn mọ bi o ṣe ri, ohun ti o ṣe, ati ohun ti o mọ̀. Nitori naa o rọrun fun wọn lati ṣafarawe awọn ẹni ti o ti kú.—1 Samuẹli 28:3-19.
Awọn Itan Èké
Ọna miiran ti Satani gba ngbe irọ́ nipa awọn oku ga ni nipasẹ awọn ìtàn èké. Iru awọn itan bẹẹ saba maa nyi awọn eniyan pada kuro ninu otitọ Bibeli.—2 Timoti 4:4.
Ni Africa ọpọlọpọ àròsọ ni o wà nipa awọn eniyan ti wọn rí laaye lẹhin iku wọn. Bi o ti saba maa njẹ, iru awọn ìfojúgán-ánní bẹẹ ni a maa nṣe nibi ti o jinna si ibi ti ẹni naa ti gbé rí. Ṣugbọn beere lọwọ araàrẹ: ‘O ha bọgbọnmu pe bi ẹnikan ba ni agbara lati pada lati inu iku, oun yoo pada si ibi ti o jinna sọdọ awọn idile ati awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀?’
Pẹlupẹlu, kò ha ni jẹ pe ẹni ti a ri naa wulẹ jọ ẹni naa ti o ti ku ni? Fun apẹẹrẹ, awọn ojiṣẹ Kristẹni meji kan nwaasu ni agbegbe orilẹ-ede kan wọn sì ṣakiyesi baba agbalagba kan ti o tẹle wọn fun ọpọlọpọ wakati. Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ̀, wọn mọ̀ pe ọkunrin naa ronu pe ọkan ninu awọn ojiṣẹ naa jẹ arakunrin rẹ̀ ti o ti ku ni awọn ọdun diẹ sẹhin. Niti gidi, oun kò tọna, ṣugbọn o kọ̀ lati gbagbọ pe oun kò tọna. Finuwoye ìtàn ti baba agbalagba naa sọ lẹhin naa fun awọn ọ̀rẹ́ ati awọn aladuugbo rẹ̀!
Awọn Ìran, Àlá, ati Ohùn
Laisi iyemeji iwọ mọ̀ nipa awọn ohun abàmì ti awọn eniyan ti rí, gbọ́, tabi lálàá rẹ̀. Iru awọn iriri abanilẹru bẹẹ saba maa ńdáyàjá awọn ti o nṣẹlẹ si. Marein, tí o ngbe ni Iwọ-oorun Africa, ni gbogbo igba ńgbọ́ ohùn iya rẹ̀ agba ti o ti ku ti o npe e ni òru. Pẹlu ẹ̀rù, Marein yoo kigbe soke, ni jiji awọn miiran ninu agbo ile naa kalẹ̀. Nikẹhin, o ya wèrè.
Nisinsinyi, bi awọn oku ba walaaye niti gidi, o ha bọgbọnmu pe wọn yoo maa dẹruba awọn ololufẹ wọn bi? Dajudaju kii ṣe bẹẹ. Orisun iru awọn isọfunni ti nbanilẹru bẹẹ jẹ awọn ẹmi-eṣu.
Ṣugbọn ki ni nipa awọn isọfunni ti o dabi ẹni pe wọn nṣeranwọ ti wọn sì ntuni ninu? Fun apẹẹrẹ, Gbassay, lati Sierra Leone, ṣaisan. O lá àlá kan nibi ti baba rẹ̀ ti o ti ku ti farahan an. O fun un ni itọni lati lọ si idi igi kan bayii, mú ninu ewé rẹ̀, ki o sì pò ó pọ̀ pẹlu omi, ki o sì mu ún. Oun kò gbọdọ ba ẹnikẹni sọrọ ṣaaju ṣiṣe eyi. O ṣe bẹẹ ara rẹ̀ sì yá.
Obinrin miiran sọ pe ọkọ rẹ̀ farahan an ni alẹ́ kan lẹhin ti o ti kú. O sọ pe ọkọ rẹ̀ fanimọra o sì wọ awọn aṣọ ti o lẹwa.
Saamu 31:5) Oun ki yoo gbà lae lati ṣe àgálámàṣà tabi tàn wa jẹ. Awọn ẹmi-eṣu nikan ni wọn nṣe bẹẹ.
Iru awọn isọfunni ati awọn ìran bẹẹ dabi ẹni pe wọn dara wọn sì ṣeranwọ. Wọn ha wá lati ọdọ Ọlọrun bi? Rara, bẹẹkọ. Jehofa jẹ “Ọlọrun otitọ.” (Ṣugbọn awọn ẹmi-eṣu daradara ha wà bi? Rara. Bi o tilẹ jẹ pe o lè jọ bi ẹni pe wọn nṣeranwọ nigba miiran, gbogbo wọn jẹ buburu. Nigba ti Eṣu ba Efa sọrọ, o huwa bi ọ̀rẹ́. (Jẹnẹsisi 3:1) Ṣugbọn ki ni o yọrisi fun un lẹhin ti o fetisilẹ si i ti o sì ṣe ohun ti oun sọ? O kú.
Iwọ mọ̀ pe kii ṣe ohun ti kò wọpọ fun eniyan buburu lati huwa bi ọrẹ si awọn wọnni ti oun fẹ lati tanjẹ tabi tujẹ. “Ehín funfun, ọkàn dúdú,” ni owe Africa naa sọ. Ọrọ Ọlọrun sì sọ pe: “Satani tikaraarẹ npa ara rẹ̀ da di angẹli imọlẹ.”—2 Kọrinti 11:14.
Ọlọrun kò lò awọn àlá, iran tabi ohùn lati ilẹ ọba ẹmi mọ́ lati fi ba awọn eniyan sọrọ lori ilẹ-aye. O ntọ wọn sọna o sì npese isọfunni fun wọn nipasẹ Bibeli, eyi ti o lè mu ki ẹnikan “murasilẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.”—2 Timoti 3:17.
Nipa bayii, nigba ti Jehofa kilọ fun wa lodisi awọn arekereke Eṣu, o ṣe bẹẹ nitori pe o nifẹẹ wa. O mọ̀ pe awọn ẹmi-eṣu jẹ awọn ọta elewu.