Paradise Ilẹ-aye Naa
Jehofa yoo ṣatunṣe gbogbo awọn ohun buburu ti Satani ti ṣe patapata. Jehofa ti fi Jesu ṣe Ọba lori gbogbo ilẹ-aye. Labẹ iṣakoso rẹ̀, ilẹ-aye ni a o sọ di paradise.—Daniẹli 7:13, 14; Luuku 23:43.
Jehofa ṣeleri awọn nnkan wọnyi:
-
ỌPỌ YANTURU OUNJẸ: “Nigba naa ni ilẹ yoo too maa mu asunkun rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tikaraarẹ yoo bùsí i fun wa.” “Ikunwọ ọka ni yoo maa wà lori ilẹ, lori awọn oke nla ni eso rẹ̀ yoo maa mì.”—Saamu 67:6; 72:16.
-
KO SI OGUN MỌ: “Ẹ wa wo awọn iṣẹ Oluwa [“Jehofa,” NW], iru ahoro ti o ṣe ni aye. O mu ọ̀tẹ̀ tán de opin aye; o ṣẹ ọrún, o sì ke ọ̀kọ̀ meji; o sì fi kẹkẹ ogun jona.”—Saamu 46:8, 9.
-
KO SI AWỌN ENIYAN BUBURU MỌ́: “Nitori ti a o ke awọn oluṣe buburu kuro . . . Nitori pe nigba diẹ awọn eniyan buburu ki yoo si: nitootọ iwọ yoo fi ara balẹ wo ipò rẹ̀, ki yoo si sí.”—Saamu 37:9, 10.
-
“Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn, yoo sì maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo sì nu omije gbogbo nu kuro ni oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ́: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”—Iṣipaya 21:3, 4.
Ni iyatọ si Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀, Jehofa kò purọ rí. Gbogbo ohun ti o ṣeleri gbọdọ ni imuṣẹ. (Luuku 1:36, 37) Jehofa nifẹẹ rẹ o sì fẹ ki o gbe ninu paradise ti oun yoo ṣe. Nitori naa kàn sí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati kẹkọọ pupọ sii nipa awọn otitọ agbayanu ti a ri ninu Ọrọ Ọlọrun. Bi iwọ ba fi otitọ silo ninu igbesi-aye rẹ, iwọ yoo ri itusilẹ kuro labẹ ìdè irọ́, igbagbọ ninu ohun asán, ati aimọkan. Bi akoko ti nlọ, iwọ yoo ri itusilẹ gba kuro labẹ ìdè ẹ̀ṣẹ̀ ati iku paapaa. Gẹgẹ bi Jesu ti sọ ọ: “Ẹ o sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di ominira.”—Johanu 8:32.