Ẹ̀KỌ́ 01
Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa la máa ń béèrè ìbéèrè pàtàkì tó kan ìgbésí ayé wa, lára ẹ̀ ni ìdí tá a fi ń jìyà, ìdí tá a fi ń kú àti bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. Àwọn nǹkan míì tá a tún máa ń ronú nípa ẹ̀ lójoojúmọ́ ni àtijẹ-àtimú àti bí ìdílé wa ṣe lè láyọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé yàtọ̀ sí pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó kan ìgbésí ayé wọn, ó tún fún wọn láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn lójoojúmọ́. Ṣé ìwọ náà gbà pé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
1. Àwọn ìbéèrè wo ni Bíbélì dáhùn?
Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí: Báwo ni ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? Kí nìdí tá a fi wà láyé? Kí nìdí táwọn èèyàn rere fi ń jìyà? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Tó bá jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ àlàáfíà, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fi ń bára wọn jagun? Báwo ni ayé yìí ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì rọ̀ wá pé ká wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àìmọye èèyàn ló sì ti rí i pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà tó tẹ́ wọn lọ́rùn.
2. Báwo ni Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbádùn ìgbé ayé wa ojoojúmọ́?
Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ bí àwọn ìdílé ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́. Ó sọ ohun tá a lè ṣe tí ìdààmú bá gba ọkàn wa àti bá a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ wa. Bá a ṣe ń jíròrò ohun tó wà nínú ìwé yìí, o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì. Ìwọ náà á wá gbà pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ [gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì] . . . wúlò.”—2 Tímótì 3:16.
A ò fi ìwé yìí rọ́pò Bíbélì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa jẹ́ kí ìwọ fúnra ẹ lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o sì fi wéra pẹ̀lú ohun tó ò ń kọ́.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Wo bí Bíbélì ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kó o wo bó o ṣe lè gbádùn kíka Bíbélì àti ìdí tó fi yẹ kó o gba ìrànwọ́ kí ohun tó ò ń kà lè yé ẹ.
3. Bíbélì máa ń tọ́ni sọ́nà
Bíbélì dà bí iná tó mọ́lẹ̀ gan-an. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe ìpinnu tó dára.
Ka Sáàmù 119:105, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Èrò wo ni ẹni tó kọ sáàmù yìí ní nípa Bíbélì?
-
Kí lèrò tìẹ nípa Bíbélì?
4. Bíbélì lè dáhùn àwọn ìbéèrè wa
Obìnrin kan rí i pé Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti wà lọ́kàn ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Nínú fídíò yẹn, kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan pàtàkì tí obìnrin yẹn fẹ́ mọ̀?
-
Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ ṣe ràn án lọ́wọ́?
Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa béèrè ìbéèrè. Ka Mátíù 7:7, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Àwọn ìbéèrè wo lo ní tó o rò pé Bíbélì lè dáhùn?
5. Ìwọ náà lè gbádùn kíka Bíbélì
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbádùn kíka Bíbélì, ó sì ń ṣe wọ́n láǹfààní. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Nínú fídíò yẹn, kí làwọn ọ̀dọ́ sọ nípa ìwé kíkà?
-
Kí nìdí táwọn ọ̀dọ́ yẹn fi fẹ́ràn kíka Bíbélì ju àwọn ìwé míì lọ?
Bíbélì máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa nírètí. Ka Róòmù 15:4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìrètí tó wà nínú Bíbélì ṣe rí lára rẹ?
6. Àwọn míì lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye Bíbélì
Ọ̀pọ̀ ti rí i pé yàtọ̀ sí kí wọ́n dá ka Bíbélì, ó tún máa ń ṣàǹfààní gan-an tí wọ́n bá jíròrò ẹ̀ pẹ̀lú àwọn míì. Ka Ìṣe 8:26-31, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ lóye ohun tó wà nínú Bíbélì?—Wo ẹsẹ 30 àti 31.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Èèyàn kàn ń fàkókò ẹ̀ ṣòfò ni tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
-
Kí lèrò tìẹ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nípa bá a ṣe máa gbé ìgbé ayé wa lójoojúmọ́, ó dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì, ó máa ń tù wá nínú, ó sì ń fún wa nírètí.
Kí lo rí kọ́?
-
Àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò wo ni Bíbélì fún wa?
-
Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni Bíbélì dáhùn?
-
Kí ló wù ẹ́ láti mọ̀ nínú Bíbélì?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe wúlò tó lóde òní.
Wo bí Bíbélì ṣe ṣèrànwọ́ fún ọkùnrin kan tó jẹ́ pé àtikékeré ló ti gbà pé òun ò já mọ́ nǹkan kan, tó sì máa ń bínú.
Wo àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó wúlò fún ìdílé.
Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tó ń darí ayé. Ohun tó sọ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò.