Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 10

Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ṣó o ti lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí? Tó bá jẹ́ pé o ò tíì lọ rí, ó ṣeé ṣe kó rí bákan lára ẹ tó o bá fẹ́ lọ nígbà àkọ́kọ́. O lè máa béèrè pé: ‘Kí ni wọ́n máa ń ṣe láwọn ìpàdé yìí? Kí nìdí táwọn ìpàdé yìí fi ṣe pàtàkì? Kí nìdí tó fi yẹ kí n lọ síbẹ̀?’ Nínú ẹ̀kọ́ yìí, o máa rí i pé tó o bá ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wàá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn ìpàdé yẹn sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìgbé ayé rẹ.

1. Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń pàdé pọ̀?

Wo bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa pé jọ pẹ̀lú àwọn míì, ó ní: “Nínú ìjọ ńlá, èmi yóò yin Jèhófà.” (Sáàmù 26:12) Bí ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn, inú wọn máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá pàdé láti jọ́sìn Ọlọ́run. Kárí ayé, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń yin Ọlọ́run pa pọ̀, wọ́n máa ń kọrin pa pọ̀, wọ́n sì máa ń gbàdúrà pa pọ̀. Bákan náà, láwọn ìgbà mélòó kan lọ́dún, wọ́n máa ń lọ sí àwọn àpéjọ ńlá kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀.

2. Kí lo máa kọ́ láwọn ìpàdé wa?

Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé wa. A máa ń ‘ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, a sì máa ń túmọ̀ rẹ̀.’ (Ka Nehemáyà 8:8.) Tó o bá wá sáwọn ìpàdé wa, wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó fani mọ́ra gan-an. Bó o bá ṣe ń mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn. Wàá tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé ìgbé ayé tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.​—Àìsáyà 48:17, 18.

3. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń wá sí ìpàdé wa?

Jèhófà sọ pé ká máa “gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀.” (Hébérù 10:24, 25) Tó o bá wá sípàdé wa, wàá rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. Wàá tún rí i pé ó ń wù wá gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run, bó ṣe ń wu ìwọ náà. Wàá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìṣírí látinú Bíbélì. (Ka Róòmù 1:11, 12.) Bákan náà, wàá tún mọ àwọn èèyàn lọ́mọdé lágbà tí wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ láwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú. Èyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tá a máa ń rí nípàdé, ìdí sì nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé ká máa pàdé pọ̀ déédéé!

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Gbìyànjú kó o mọ ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa àti àǹfààní tó o máa rí tó o bá ń sapá láti wá sáwọn ìpàdé yìí.

4. Ìpàdé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, àwọn Kristẹni máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti jọ́sìn Jèhófà. (Róòmù 16:3-5) Ka Kólósè 3:16, kó o sì dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo làwọn Kristẹni ṣe ń jọ́sìn Jèhófà nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀?

Lóde òní, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ déédéé láwọn ilé ìjọsìn wa. Tó o bá fẹ́ mọ ohun tá a máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa àti bá a ṣe ń ṣe é, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà, wo àwòrán ìpàdé tó wà lókè yìí, kó o wá dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ọ̀nà wo ni ohun tá a máa ń ṣe láwọn ilé ìjọsìn wa àti ohun tó o kà ní Kólósè 3:16 gbà jọra?

  • Kí lo tún rí nípa ìpàdé wa nínú fídíò tàbí àwòrán yìí tó wù ẹ́?

Ka 2 Kọ́ríńtì 9:7, kó o sì dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbé igbá owó láwọn ìpàdé wa?

Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jọ jíròrò ohun tá a máa kọ́ ní ọ̀kan lára àwọn ìpàdé tá a máa ṣe lọ́sẹ̀ yìí.

  • Apá wo lára àwọn ìpàdé wa lo rò pé o máa gbádùn jù?

  1. A. Lára àwọn nǹkan tá a máa ń gbádùn láwọn ìpàdé wa ni ẹ̀kọ́ Bíbélì, ẹ̀kọ́ nípa bá a ṣe ń wàásù, a sì máa ń wo àwọn fídíò tó dá lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Orin àti àdúrà la máa ń fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé, orin àti àdúrà náà la sì máa ń fi parí ẹ̀

  2. B. Àwọn apá kan wà nínú àwọn ìpàdé náà táwọn tó wà nípàdé máa ń nawọ́, kí wọ́n lè dáhùn ìbéèrè

  3. D. Gbogbo èèyàn la pè, àtọmọdé àtàgbàlagbà

  4. E. Ọ̀fẹ́ làwọn ìpàdé wa. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó ìwọlé, bẹ́ẹ̀ ni a kì í gbé igbá owó

5. Ó gba ìsapá kó o tó lè máa lọ sípàdé

Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù àtàwọn òbí ẹ̀. Ọdọọdún ni wọ́n máa ń rin ìrìn àjò tí ó tó nǹkan bíi ọgọ́ta (60) máìlì, wọ́n sì máa rìn gba orí àwọn òkè láti Násárẹ́tì dé Jerúsálẹ́mù. Ka Lúùkù 2:39-42. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣó o rò pé ó rọrùn fún wọn láti rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù?

  • Kí nìdí tó fi lè gba pé kó o sapá gan-an kó o tó lè máa wá sípàdé?

  • Ṣó yẹ kó o sapá láti máa lọ sípàdé? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Bíbélì sọ pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa pàdé láti jọ́sìn Ọlọ́run. Ka Hébérù 10:24, 25. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lọ sípàdé déédéé?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò yẹ kéèyàn máa dara ẹ̀ láàmù pé òun ń lọ sípàdé kankan. Téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé fúnra ẹ̀, ìyẹn náà ti tó.”

  • Ẹsẹ Bíbélì tàbí àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tó o bá ń lọ sípàdé déédéé, wàá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wàá túbọ̀ sún mọ́ ọn, wàá sì máa jọ́sìn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn míì.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ká máa pàdé pọ̀?

  • Àwọn nǹkan wo lo máa kọ́ nípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

  • Àwọn àǹfààní míì wo lo rò pé wàá rí tó o bá ń lọ sípàdé?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bákan láti wá sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Wo bí ọkùnrin kan tí kò fẹ́ wá sípàdé nígbà kan ṣe wá ń gbádùn àwọn ìpàdé wa báyìí.

A Ò Lè Gbàgbé Ìkíni Yẹn Láyé (4:16)

Wo bí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe gbádùn àwọn ìpàdé wa, kó o sì wo ohun tó ṣe kó lè máa lọ sípàdé déédéé.

Mo Gbádùn Ìpàdé Yẹn Gan-an! (4:33)

Wo ohun táwọn kan sọ nígbà tí wọ́n wá sípàdé wa.

“Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Wo bí ìgbé ayé ọmọọ̀ta kan tó burú gan-an ṣe yí pa dà lẹ́yìn tó lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Ìbọn Máa Ń Wà Lára Mi Níbikíbi Tí Mo Bá Lọ” (Ilé Ìṣọ́, July 1, 2014)