Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 1

Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 1

Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Àwọn nǹkan wo ló wù ẹ́ jù nínú àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 02.)

  2. Kí nìdí tó o fi gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 03 àti 05.)

  3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo orúkọ ­Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 04.)

  4. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9) Ṣó o gbà pé òótọ́ ni?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 06.)

  5. Ka Òwe 3:32.

    • Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ Ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ?

    • Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe? Ṣó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 07 àti 08.)

  6. Ka Sáàmù 62:8.

    • Àwọn nǹkan wo lo ti torí ẹ̀ gbàdúrà sí ­Jèhófà? Àwọn nǹkan míì wo lo tún lè bá Jèhófà sọ nínú àdúrà rẹ?

    • Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 09.)

  7. Ka Hébérù 10:24, 25.

    • Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

    • Ṣó o rò pé ó yẹ kó o máa lọ sípàdé kódà ­láwọn ìgbà tí kò bá rọrùn?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 10.)

  8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì déédéé? Ìgbà wo lo máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 11.)

  9. Àwọn nǹkan wo lo gbádùn jù lọ látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

  10. Látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìṣòro wo lo ti dojú kọ tó lè mú kó o dá ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ dúró? Kí lo lè ṣe kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 12.)