Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 30

Àwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú Ṣì Máa Jíǹde!

Àwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú Ṣì Máa Jíǹde!

Ikú ti kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an bá aráyé. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe ikú ní ọ̀tá. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ní Ẹ̀kọ́ 27, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa mú ikú kúrò. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó ti kú? Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a máa kọ́ nípa ìlérí míì tí Jèhófà ṣe pé òun máa jí àìmọye àwọn tó ti kú dìde, kí wọ́n lè gbádùn ayé títí láé. Ó sì dájú pé ó máa jí wọn dìde! Ṣáwọn òkú lè jí dìde lóòótọ́? Ṣé ọ̀run ni wọ́n máa jíǹde sí ni àbí ayé?

1. Kí ni Jèhófà fẹ́ ṣe fún àwọn èèyàn wa tó ti kú?

Ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ó dá Jóòbù ọkùnrin olódodo náà lójú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé òun nígbà tóun bá kú. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn [látinú lsà Òkú].”​—Ka Jóòbù 14:13-15.

2. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn òkú máa jíǹde?

Nígbà tí Jésù wà láyé, Ọlọ́run fún un lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Jésù jí ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìlá kan àti ọmọkùnrin opó kan dìde. (Máàkù 5:41, 42; Lúùkù 7:12-15) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú, tí wọ́n sì ti sin ín, síbẹ̀ Jésù jí i dìde. Lẹ́yìn tí Jésù ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó dojú kọ ibojì náà, ó sì gbóhùn sókè, ó ní: “Lásárù, jáde wá!” ‘Ọkùnrin tó ti kú náà sì jáde wá.’ Bí Lásárù ṣe jí dìde nìyẹn o! (Jòhánù 11:43, 44) Ẹ wo bí inú mọ̀lẹ́bí Lásárù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ṣe máa dùn tó!

3. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú sáwọn èèyàn rẹ tó ti kú?

Bíbélì sọ pé: ‘Àjíǹde yóò wà.’ (Ìṣe 24:15) Àwọn tí Jésù jí dìde nígbà tó wà láyé kò lọ sí ọ̀run. (Jòhánù 3:13) Inú wọn dùn pé ayé yìí ló jí wọn dìde sí. Bákan náà, Jésù máa tó jí àìmọye èèyàn dìde láti gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè. Ó sọ pé “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí,” ló máa jíǹde. Kódà Ọlọ́run máa rántí àwọn tó ṣeé ṣe káwa èèyàn ti gbàgbé, á sì jí wọn dìde.​—Jòhánù 5:28, 29.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé àwọn òkú máa jíǹde àti bí ìrètí àjíǹde ṣe ń tù wá nínú tó sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀.

4. Jésù fi hàn pé òun lè jí òkú dìde

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Jésù ṣe fún Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ka Jòhánù 11:14, 38-44, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé Lásárù kú lóòótọ́?​—Wo ẹsẹ 39.

  • Tó bá jẹ́ pé ọ̀run ni Lásárù lọ, ṣé o rò pé Jésù á jí i pa dà sáyé?

Wo FÍDÍÒ yìí.

5. Jésù máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn dìde!

Ka Sáàmù 37:29, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Ibo ni àìmọye èèyàn tí Jésù máa jí dìde á máa gbé?

Yàtọ̀ sí àwọn tó jọ́sìn Jèhófà, Jésù tún máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn míì dìde. Ka Ìṣe 24:15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Ta ló ń wù ẹ́ kó o rí nígbà àjíǹde?

Rò ó wò ná: Ó rọrùn fún Jésù láti jí ẹnì kan dìde bí ìgbà tí bàbá kan bá jí ọmọ ẹ̀ lójú oorun

6. Ìrètí àjíǹde ń tù wá nínú, ó sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀

Ìtàn ọmọbìnrin Jáírù tó wà nínú Bíbélì ti tu ọ̀pọ̀ èèyàn nínú nígbà téèyàn wọn kú, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ka ìtàn náà ní Lúùkù 8:40-42, 49-56.

Kí Jésù tó jí ọmọbìnrin Jáírù dìde, ó sọ fún bàbá ọmọ náà pé: “Má bẹ̀rù, ṣáà ti ní ìgbàgbọ́.” (Wo ẹsẹ 50.) Báwo ni ìrètí tó o ní pé àjíǹde ń bọ̀ ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ . . .

  • nígbà tí èèyàn rẹ bá kú?

  • nígbà tí ẹ̀mí rẹ bá wà nínú ewu?

Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe tu àwọn òbí Phelicity nínú, tó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé àwọn òkú máa jí dìde.”

  • Kí lèrò tìẹ?

  • Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà fún ẹnì kan láti fi hàn pé àwọn òkú máa jí dìde?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Bíbélì sọ pé àìmọye èèyàn tó ti kú máa jíǹde. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n pa dà wà láàyè, ó sì ti fún Jésù lágbára láti jí wọn dìde.

Kí lo rí kọ́?

  • Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà àti Jésù láti jí àwọn òkú dìde?

  • Ṣé ọ̀run ni àìmọye èèyàn tó máa jíǹde á máa gbé ni àbí ayé? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

  • Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé àwọn èèyàn ẹ tó ti kú máa jíǹde?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn ohun tó máa jẹ́ kó o lè borí ìbànújẹ́ tí èèyàn ẹ bá kú.

“Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀” (Jí! No. 3 2018)

Ṣé àwọn ìlànà Bíbélì lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tó lẹ́dùn ọkàn torí pé èèyàn ẹ̀ kú?

Tí Ẹni Tó O Fẹ́ràn Bá Kú (5:06)

Báwo làwọn ọmọdé ṣe lè fara dà á tẹ́ni tí wọ́n fẹ́ràn bá kú?

Ìràpadà (2:07)

Ṣé àwọn kan máa jíǹde sí ọ̀run? Àwọn wo ni Ọlọ́run kò ní jí dìde?

“Kí Ni Àjíǹde?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)