Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 2

Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 2

Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe sí ẹ̀sìn èké?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 13.)

  2. Ka Ẹ́kísódù 20:4-6.

    • Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn èèyàn bá ń lo ère nínú ìjọsìn wọn?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 14.)

  3. Ta ni Jésù?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 15.)

  4. Èwo nínú àwọn ìwà àti ìṣe Jésù lo fẹ́ràn jù?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 17.)

  5. Ka Jòhánù 13:34, 35 àti Ìṣe 5:42.

    • Àwọn wo ni Kristẹni tòótọ́ lóde òní? Kí ló mú kó o gbà pé Kristẹni tòótọ́ ni wọ́n?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 18 àti 19.)

  6. Ta ni orí ìjọ Kristẹni, báwo ló sì ṣe ń darí rẹ̀?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 20.)

  7. Ka Mátíù 24:14.

    • Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ lónìí?

    • Àwọn wo lo ti wàásù ìhìn rere fún?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 21 àti 22.)

  8. Ṣé o rò pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 23.)

  9. Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 24.)

  10. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 25.)

  11. Kí nìdí táwa èèyàn fi ń jìyà tá a sì ń kú?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 26.)

  12. Ka Jòhánù 3:16.

    • Kí ni Jèhófà ṣe fún wa ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 27.)

  13. Ka Oníwàásù 9:5.

    • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?

    • Kí ni Jésù máa ṣe fún àìmọye èèyàn tó ti kú?

      (Wo Ẹ̀kọ́ 29 àti 30.)

  14. Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju gbogbo ìjọba èèyàn lọ?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 31 àti 33.)

  15. Ṣé o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìgbà wo ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

    (Wo Ẹ̀kọ́ 32.)