Ẹ̀KỌ́ 34
Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Ṣó o ti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run látìgbà tó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ṣó wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa sún mọ́ ọn? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, fi sọ́kàn pé bí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà bá ṣe ń jinlẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ lòun náà á túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ táá sì máa bójú tó ẹ. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
1. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Tá a bá ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 5:3.) Ọlọ́run kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti gbọ́ràn sí òun lẹ́nu. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pinnu bóyá a máa gbọ́ràn sí òun lẹ́nu àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ ká máa “ṣègbọràn látọkàn wá.” (Róòmù 6:17) Ohun tá à ń sọ ni pé, ó fẹ́ ká máa gbọ́ràn sóun lẹ́nu torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun, kì í ṣe torí pé ó fipá mú wa. Apá 3 àti 4 nínú ìwé yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́, tó o sì ń sá fún àwọn nǹkan tó kórìíra.
2. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
“Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀.” (Sáàmù 34:19) Gbogbo wa la ní àwọn kùdìẹ-kudiẹ tá à ń bá yí. Bákan náà, àtijẹ àtimu lè má rọrùn, àwọn èèyàn lè fìyà jẹ wá, bẹ́ẹ̀ la tún ń kojú àwọn ìṣòro míì. Kì í rọrùn láti jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà tá a bá ń kojú ìṣòro tó le gan-an, torí pé ohun tí kò tọ́ ló sábà máa ń rọrùn láti ṣe. Àmọ́, tó o bá ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu nígbà tó rọrùn àti nígbà tí kò rọrùn, wàá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju ohunkóhun míì lọ, wàá sì fi hàn pé adúróṣinṣin ni ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa dúró tì ẹ́, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé.—Ka Sáàmù 4:3.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu àti ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí i.
3. Ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tó kàn ẹ́
Nínú ìwé Jóòbù, ẹ̀sùn kan wà tí Sátánì fi kan Jóòbù, àmọ́ àkọsílẹ̀ yẹn tún fi hàn pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà pátá ni ọ̀rọ̀ yẹn kàn. Ka Jóòbù 1:1, 6–2:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí ni Sátánì sọ pé ó mú kí Jóòbù máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu?—Wo Jóòbù 1:9-11.
-
Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan gbogbo èèyàn, títí kan ìwọ náà?—Wo Jóòbù 2:4.
Ka Jóòbù 27:5b, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé òun fẹ́ràn Jèhófà lóòótọ́?
4. Mú ọkàn Jèhófà yọ̀
Ka Òwe 27:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà tó o bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó o sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
5. O lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí á mú kó máa wù wá láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ fáwọn èèyàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kódà láwọn ìgbà tí kò bá rọrùn, ńṣe ló máa fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn?
-
Nínú fídíò yẹn, kí ló ran Grayson lọ́wọ́ tí kò fi bẹ̀rù mọ́?
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́, tá a sì kórìíra ohun tó kórìíra, ó máa rọrùn fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ka Sáàmù 97:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fẹ́ràn? Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà kórìíra?
-
Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè nífẹ̀ẹ́ ohun rere, kó o sì kórìíra ohun tó burú?
6. A máa jàǹfààní gan-an tá a bá ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu
Ohun tó dáa jù ni pé ká máa gbọ́ ti Jèhófà. Ka Àìsáyà 48:17, 18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Ṣó o gbà pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní ká ṣe ló máa ṣe wá láǹfààní? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
-
Àǹfààní wo lo ti rí látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Bó bá ṣe wù mí ni mo lè gbé ìgbé ayé mi, Ọlọ́run ò ka gbogbo ìyẹn sí.”
-
Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè tọ́ka sí tó fi hàn pé ìwà àti ìṣe wa lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí kó bà á lọ́kàn jẹ́?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tó o bá ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu nígbà tó rọrùn àti nígbà tí kò rọrùn, ńṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn.
Kí lo rí kọ́?
-
Kí ni àpẹẹrẹ Jóòbù kọ́ ẹ?
-
Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
-
Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà gbogbo?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ sí i nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan gbogbo èèyàn.
Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn ọmọdé náà ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
Táwọn kan bá fẹ́ mú kí ọ̀dọ́ kan ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́, báwo ló ṣe lè fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́?