Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 40

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Lójú Ọlọ́run

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Lójú Ọlọ́run

Àwọn ìyá tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé àwọn ọmọ wọn wà ní mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí ọmọ kan tó lọ síléèwé, ìyá rẹ̀ á wẹ̀ fún un, á rí i pé aṣọ ẹ̀ ò rí wúruwùru, ó sì mọ́ dáadáa. Èyí á jẹ́ kára ọmọ náà le, àwọn èèyàn á sì rí i pé àwọn òbí ẹ̀ ń tọ́jú ẹ̀ dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú Baba wa ọ̀run, Jèhófà. Ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ ká jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa. Tá a bá jẹ́ mímọ́, ó máa ṣe wá láǹfààní púpọ̀, a sì máa buyì kún Jèhófà.

1. Báwo la ṣe lè jẹ́ mímọ́ nípa tara?

Jèhófà sọ fún wa pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.” (1 Pétérù 1:16) Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ká jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa. Tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́ nípa tara, a gbọ́dọ̀ máa wẹ̀ déédéé, ká máa fọ aṣọ wa, ká máa tún ilé wa ṣe, ká máa fọ ọkọ̀ wa, káwọn nǹkan wa má sì rí wúruwùru. Ó tún yẹ ká máa tún àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà ṣe. Tá a bá jẹ́ mímọ́ nípa tara, ńṣe là ń buyì kún Jèhófà.​—2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.

2. Tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́, àwọn àṣà wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?

Bíbélì sọ fún wa pé ká “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa sá fún ohunkóhun tó lè ba ara àti ọpọlọ wa jẹ́. Ó yẹ kí ohun tá à ń rò máa múnú Jèhófà dùn, torí náà a gbọ́dọ̀ máa sapá gan-an láti gbé èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn wa. (Sáàmù 104:34) Bákan náà, kò yẹ ká máa sọ ọ̀rọ̀ rírùn.​—Ka Kólósè 3:8.

Báwo la ṣe lè máa jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú èrò wa, ìwà wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa? Àwọn nǹkan kan wà tó lè kó ẹ̀gbin bá ara wa. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká máa mu sìgá, igbó tàbí tábà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa lo oògùn olóró. Tá a bá ń yẹra fáwọn nǹkan yìí, a ò ní sọ ara wa di ẹlẹ́gbin, èyí á sì fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún wa. Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà jẹ́ mímọ́ ni pé ká má ṣe máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ wa, ká má sì máa wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe. (Sáàmù 119:37; Éfésù 5:5) Òótọ́ ni pé kò rọrùn rárá láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà yìí, àmọ́ Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jáwọ́.​—Ka Àìsáyà 41:13.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo bá a ṣe lè máa buyì kún Jèhófà tá a bá jẹ́ mímọ́ àti bá a ṣe lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ń sọni di ẹlẹ́gbin.

3. Tá a bá jẹ́ mímọ́ nípa tara, ńṣe là ń buyì kún Jèhófà

Tá a bá ka òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, a máa rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwa tá à ń sin Jèhófà jẹ́ mímọ́. Ka Ẹ́kísódù 19:10 àti 30:17-​19, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí la rí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí tó fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ mímọ́ nípa tara?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa ṣe ká lè jẹ́ mímọ́ nípa tara?

Kò rọrùn láti jẹ́ mímọ́ nípa tara. Àmọ́, ibi yòówù ká máa gbé, bóyá a jẹ́ olówó tàbí tálákà, a lè jẹ́ mímọ́ nípa tara. Wo FÍDÍÒ Yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Tá a bá ń wà ní mímọ́ tónítóní tá ò sì jẹ́ káwọn nǹkan wa rí wúruwùru, báwo nìyẹn ṣe ń buyì kún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?

4. Jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa

Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa

Tó o bá ń mu sìgá, igbó tàbí ò ń lo oògùn olóró, wàá gbà pé kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá láti jáwọ́ nínú àṣà yìí. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ronú nípa àkóbá tí àṣà yìí lè ṣe fún ẹ. Ka Mátíù 22:37-39, lẹ́yìn náà kó o sọ bí lílo oògùn olóró, mímu sìgá, igbó tàbí tábà ṣe lè ṣàkóbá fún . . .

  • àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà.

  • ìdílé ẹ àtàwọn míì tó sún mọ́ ẹ.

Ṣètò bó o ṣe máa jáwọ́ nínú àṣà burúkú kan. a Wo FÍDÍÒ yìí.

Ka Fílípì 4:13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tá a bá ń gbàdúrà déédéé, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tá a sì ń lọ sípàdé déédéé, báwo nìyẹn ṣe lè mú ká jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa?

5. Máa sapá kó o lè borí èrò àti àṣà tí kò dáa

Ka Kólósè 3:5, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé wíwo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe, fífi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù àti fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni jẹ́ ohun ẹlẹ́gbin lójú Jèhófà?

  • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé ká jẹ́ mímọ́ nínú èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Wo fídíò yìí kó o lè mọ bó o ṣe lè borí èrò tí kò dáa. Wo FÍDÍÒ yìí.

Jésù lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́ nínú èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, àfi ká máa sapá gidigidi. Ka Mátíù 5:29, 30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé ká ṣe ara wa léṣe o, àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé tá a bá fẹ́ máa jẹ́ mímọ́ lérò, lọ́rọ̀ àti níṣe, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára. Ìgbésẹ̀ tó lágbára wo lo rò pé ẹnì kan lè gbé kó má bàa gba èrò tí kò dáa láyè nínú ọkàn ẹ? b

Jèhófà mọyì gbogbo bó o ṣe ń sapá gidigidi láti gbé èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn. Ka Sáàmù 103:13, 14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tó o bá ń sapá láti gbé èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn, báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀?

Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ!

O lè máa ronú pé, ‘Mi ò rò pé mo lè jáwọ́ nínú àṣà yìí jàre, bóyá kí n kúkú gba kámú.’ Àmọ́, rò ó wò ná: Tí sárésáré kan bá fẹsẹ̀ kọ tó sì ṣubú, kò túmọ̀ sí pé ó ti pàdánù nìyẹn, kò sì ní torí ìyẹn wá lọ bẹ̀rẹ̀ èrè náà pa dà látìbẹ̀rẹ̀. Lọ́nà kan náà, tó bá ṣẹlẹ̀ pé o tún jìn sọ́fìn àṣà tó ò ń gbìyànjú láti jáwọ́ nínú ẹ̀, kò túmọ̀ sí pé o ti pàdánù nìyẹn. Bákan náà, ìyẹn ò fi hàn pé asán ni gbogbo ìgbìyànjú ẹ àtọjọ́ yìí. Fi sọ́kàn pé tó o bá ṣubú, ńṣe ló yẹ kó o dìde. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí ò dáa.

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ọ̀rọ̀ mi ti kọjá àtúnṣe jàre. Mi ò lè jáwọ́.”

  • Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà fún ẹnì kan láti jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà lè ràn án lọ́wọ́ kó lè jáwọ́ nínú àṣà tí kò dáa?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tá a bá jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa, inú Jèhófà á máa dùn sí wa.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ mímọ́?

  • Báwo lo ṣe lè jẹ́ mímọ́ nípa tara?

  • Báwo lo ṣe lè jẹ́ mímọ́ nínú èrò àti ìṣe rẹ?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Àwọn ọ̀nà kéékèèké wo lo lè máa gbà ṣe ìmọ́tótó tí kò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ohun amáyédẹrùn níbi tó ò ń gbé?

Ìmọ́tótó Borí Àrùn Mọ́lẹ̀​—Ọwọ́ Fífọ̀ (3:01)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kó o ṣe kó o lè jáwọ́ nínú sìgá mímu.

“Bó O Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu” (Jí!, July 2010)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ àkóbá tí wíwo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe máa ń fà.

“Àwòrán Oníhòòhò​—Ó Léwu Àbí Kò Léwu?” (Ilé Ìṣọ́, August 1, 2013)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí ọkùnrin kan ṣe jáwọ́ nínú wíwo àwòrán àti fíìmù ìṣekúṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àṣà yìí ti di bárakú fún un.

“Mo Ṣàṣìṣe Lọ́pọ̀ Ìgbà Àmọ́ Mo Ṣàṣeyọrí” (Ilé Ìṣọ́ No. 4 2016)

a Àpilẹ̀kọ náà, “Bó o Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu,” tó wà ní apá Ṣèwádìí nínú ẹ̀kọ́ yìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ káwọn tí àṣà burúkú ti mọ́ lára ṣe kí wọ́n lè jáwọ́.

b Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè jáwọ́ nínú fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ, ka àpilẹ̀kọ yìí “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Mi?” nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, orí 25.